Xenophobia: Ọ̀sẹ̀ tó ń bọ̀ ni bàálù yóò lọ kó ọmọ Nàíjíríà wálé

Oríṣun àwòrán, @FriendsofKashm2
Bi wọn se n ge awọn ọmọ orilẹede South Africa lọwọ ni wọn tun n bọ oruka nitori pe wọn ko dẹkun ikọlu ti wọn n se sawọn ọmọ Naijiria.
Iroyin kan tun ti kede pe se ni awọn eeyan lorilẹede South Africa tun n ja awọn sọọbu to jẹ tawọn ajeji, ti wọn si n ko wọn ni ọpọlọpọ ẹru tabi ba dukia wọn jẹ.
Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:
- Ọmọ ọdún méjìlá ni mo ti ń ṣe bàálù, ọkọ̀, ilé àti ọkọ̀ ojú omi - Ọdọ́mọdé ‘Engineer’
- Ajé ò! Ẹ wo fídíò òfò àti àdánù tó wáyé níbi ìkọlù sáwọn àjèjì ní South Africa
- "A ti nílé, dúkìá àti ẹbí ní South Africa, àwa kò ṣetán láti padà sílé"
- Àwọn ọ̀rọ̀ apanílẹ̀rín tí Mugabe sọ tó jẹ́ mánigbàgbé
- "Ọ̀pọ̀ ń gbé nínú ìbẹ̀rù ní South Africa ́lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí"
- Ìdájọ́ ọmọ mi tó gbé àdó ìkú wọ bàálù le púpọ̀, ẹ bá mi wòó ṣe - Bàbá Mutallab
Gẹgẹ baa ti gbọ, awọn ọlọpa lorilẹede naa ti fidi rẹ mulẹ pe awọn eeyan naa ko tii dẹkun isẹ ibi ti wọn n se lati ọjọ Aiku, ti awọn ko si tii sinmi kika apa wọn ko ninu iwa ibajẹ naa.
Bakan naa lo fikun pe ọwọ ti ba awsn eeyan kan ti wọn ka mọ idi iwa ika yii lagbegbe Gauteng, ti eeyan mẹrinlelaadọrin si ti wa lahamọ ọlọpa lẹkun Katlehong.

Oríṣun àwòrán, @FriendsofKashm2
Wayi o, ọpọ ọmọ Naijiria taa gbọ pe wọn ti fi orukọ silẹ pe awọn n pada bọ nile pẹlu baalu ọfẹ tijọba gbe kalẹ lati ko wọn wale lati orilẹede South Africa.
Sugbọn a gbọ pe ijakulẹ diẹ ba eto naa nitori bi ọjọ ti lọ lori iwe irinna awọn ọmọ Naijiria kan to fẹ wa sile.
Nigba to n ba akọroyin BBC sọrọ, osisẹ alarina fun ileesẹ ọrọ ilẹ okeere lorilẹede Naijiria kede pe, wọn ti sun igbesẹ kiko awọn ọmọ Naijiria naa wale lati South Africa di ọsẹ to n bọ.

Oríṣun àwòrán, @uche_ezeonye
O salaye pe, eyi ri bẹẹ ki awọn lee fun asoju agba fun ileesẹ asoju ilẹ South Africa ni anfaani lati se akojọpọ orukọ awọn ọmọ Naijiria to nifẹ lati pada sorilẹede wa.
- Ta ló leè rò pé ọmọ mẹ̀kúnnù bí èmi leè dé ipò alága NURTW? - MC Oluomo
- Láìpẹ́, ará ìlú rẹ ni ọlọ́pàá tí yóò máa ṣọ́ ìlú rẹ
- Ìdajì owó iṣẹ́ àgbàṣe ló ń padà sápò gómìnà àná àti aya rẹ̀ l‘Ọyọ - Seyi Makinde
- Ẹ̀tanu ni àwọn ìmáàmù Yoruba fi yan Waziri míì, ojúṣe ọba ni - Oluwo
- Sanwo-Olu fi ẹ̀gbin dá àrà tuntun l'Eko
- Àwọn ọ̀rọ̀ apanílẹ̀rín tí Mugabe sọ tó jẹ́ mánigbàgbé
O fikun pe ọkọ baalu nla ni awọn gbe kalẹ, o si yẹ ki awọn se gbogbo eto to yẹ ki baalu naa to morile orilẹede South Africa lati ko awọn eeyan naa wale.












