Enìyàn mẹ́ta kú nínú ìjàmbá ọkọ̀ ní'lù Abuja

Oko ayokele

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Àkọlé àwòrán, Kíló fa tí ọkunrin yìí fi gbẹ̀mi ènìyàn mẹ́ta tó si sálọ

O kéré tán ènìyàn mẹ́ta ló ti jẹ́ Ọlọrun nípe tí àwọn mẹ́ta míràn sí ní oníruuru ìpalára nígbà ti àwa kọ Mercedes Benz funfun kan lọ sorí mọ́ 4matic àti kẹ̀kẹ́ Maruwa méjì míràn ní agbègbè Gwarimpa nílùú Abuja.

Gẹ́gẹ́ bí àwọn tí ọ̀rọ̀ náà ṣojú wọ́n ṣe sọ, àwakọ Benz tí nọmba ọkọ̀ rẹ̀ jẹ́ SRP 553 QG tí mu otí yọ tí ó sì ń sáre asápajúde ní ǹkan bi ààgo mẹ́fa ààbọ̀ ìdájí òní nígbà tó lọ kọlu àwọn awakọ̀ Maruwa náà.

O kéré tán ènìyàn mẹ́ta kú lójú ẹsẹ̀ nígbà tí ó tún kọlu ènìyàn mẹ́ta míràn nígbà tó n gbé òkìtì.

Lẹ́yìn ìṣẹ̀lẹ̀ náà ni wọ́n ní awakọ Benz náà bẹ́ sínú ọkọ̀ míràn pẹ̀lú alábarin rẹ̀ tí wọ́n si sálọ.

Ilé iṣẹ́ ọlọpàá ìlú Abuja ní awọn tí ń gbìyànjú láti ṣe awári ọkúnrin náà.

Nígbà ti BBC Yorùbá pé agbẹ́nusọ ilé iṣẹ́ ọlọpàá ìlú Abuja Anjuguri Manza,n láti mọ bóyá wọ́n ti ṣe awári ọkunrin náà, ìdáhun rẹ̀ ni pé, " ọ̀rọ̀ náà wà lábẹ́ ìwádìí." " Nkò le sọ jù bẹ́ẹ̀ lọ, à ń ṣe ìwádiìí ọ̀rọ̀ náà lọ́wọ́"

O ní ọkunrin tó ń wa ọkọ ayọkẹlẹ Benz náà jọ bi ẹni pé ó tí mu oti yó ti kò si si nọmba idákọmọ nígbà ti ìṣẹ̀lẹ̀ náà ṣẹlẹ̀.

Agbẹ́nusọ ẹsọ ìgbòkègbodo ọkọ náà (FRSC) Bisi Kazeem tó fidi ọ̀rọ̀ náà múlẹ̀ sàlàyé wọ́n ti gbé òkú ènìyàn mẹ́ta náà kúrò, nígbà tí wọ́n ti gbe àwọn tó farapa lọ si ilé ìwòsàn gbogbo níṣe Kubwa