Robert Mugabe: Àjọṣepọ̀ káfisẹ́nu-kádákẹ́ tó wà láàrín èmi àti olórí orílẹ̀èdè Zimbabwe tẹ́lẹ̀

Oríṣun àwòrán, Fairfax / Getty Images
Ki wọn to yẹ aga ijsba mọọ ni idi lọdun meji sẹyin, Robert Mugabe ni Aarẹ kan ṣoṣo ti awọn ọdọ ti wọn bi lẹyin igbominira Zimbabwe lọdun 1980 da mọ gẹgẹ bi aarẹ.
Mugabe ni aarẹ laye iya-iya mi, oun naa ni aarẹ laye iya mi, ero mi si ni pe oun naa ni yoo jẹ aarẹ fun awọn ọmọ mi obinrin pẹlu. Loju ti wa, itums aarẹ ni Robert Mugabe.
Ni ileewe a maa n gboriyin fun bi o ṣe ja fafa to ninu ọrọ sisọ. Agbọ gbọnrinu ni awọn ọrs apilẹkọ rẹ, orin iyin rẹ ko si tan lẹnu wa ni ileewe. Irufẹ iyi ti Robert Mugabe ni niyi gẹgẹ bii olorii wa.
- Ẹ máṣe gba ààwẹ̀ dójú ikú, ẹ gba iye tí agbára yín gbé - Dókítà
- Robert Mugabe, akọni òṣèlú tó lo ọdún mẹ́wàá lẹ́wọ̀n fún ìjìjàgbara Zimbabwe
- Ikú Mugabe jẹ́ àdánù fún gbogbo ilẹ̀ Afiríka lápapọ̀ - Ọbasanjọ
- Ìdajì owó iṣẹ́ àgbàṣe ló ń padà sápò gómìnà àná àti aya rẹ̀ l‘Ọyọ - Seyi Makinde
- Ṣé Zimbabwe dùn gbé bí lásìkò yìí ju àkókò ìṣèjọ̀ba Mugabe lọ?
- Àwọn ọ̀rọ̀ apanílẹ̀rín tí Mugabe sọ tó jẹ́ mánigbàgbé
N o ranti rẹ fun jijẹ olootọ si ohun ti o gbagbọ. Ko muti, bẹẹ ni ko mu siga. Ounjẹ abalaye orilẹede Zimbabwe lo n jẹ bẹẹ ni o si kundun ere idaraya lawn tennis.
Akin ọkunrin ni Mugabe, ko si yee gbe ara rẹ si inu aṣọ oyinbo. Ni ile, baba rere ni, ti o fẹran awọn ọmọ rẹ paapaajulọ ọmọ rẹ agba obinrin, Bona.
Iroyin iku rẹ ni ileewosan aladanla kan lorilẹede Singapore jẹ manigbagbe fun mi bi a ba wo bi eto ilera ti ṣe dẹnu kọlẹ lorilẹede Zimbabwe to fi silẹ. Eleyi ti a lee pe ni ọkan lara awọn iwa imọtaraẹninikan rẹ.

Oríṣun àwòrán, AFP
Afojusun rẹ ni lati pe ọmọ ọgọrun ọdun ki o to jade laye ati lati wonkoko mọ ipo aarẹ orilẹ€de naa titi di ọjọ iku rẹ. Amọṣa gbogbo afojusun meji yii ni ko lee bọsi.
Fun ọdun mẹtadinlogoji ni a fi farada ijọba familete-n-tutọ rẹ. Mo bẹru rẹ gidigidi.
Nitori Mugabe ni a ṣe lanfani eto ẹkọ to ye kooro. Bakan naa ni a lanfani si ẹts kan naa pẹlawọn ọmọ alawọfunfun. O jẹ adari ti o mọ anfani ati agbara to wa ninu ẹkọ. eto rẹ lori ẹkọ mu ki orilẹ€de Zimbabwe di awokọṣe ni ilẹ Afirika.

Oríṣun àwòrán, AFP
Nigba to ya, iwọnba perete awọn ọmọ ilẹ Zimbabwe lo janfani eto ironilagbara rẹ. Paapaa julọ ilana aato lori ilẹ to sọ ọpọ agbẹ ti alagbara.
Amọṣa lọdun 1997 ni akara bẹrẹ si nii tu sepo nigbati Mugabe pinnu lati san owo ajẹmọnu fawọn ọmọogun ajijagbara ti wọn n beere fun ilakaka wọn.
Eyi lo gba gbara lọwọ owo orilẹede naa ki o to tun ran awọn ọmọogun lọ ja ogun lorilẹede DR Congo. Lọdun kan naa ni rogbodiyan lori ọrs ounjẹ bẹ silẹ lawọn ilu nla kan lorilẹ€de naa. Bẹrẹ lati igba yii wa, nnkan o ṣe ẹnuure fun orilẹede Zimbabwe mọ.

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Ko si aniani pe ajijagbara fun orilẹede Zimbabwe ni Mugabe jẹ, bakan naa ni o tun sọ ara rẹ di oludunkukulaja fun orilẹede naa pẹlu.
Ni orilẹede Zimbabwe, ko is ninu aṣa wọn lati maa kokiki iku ẹnikẹni, koda ko jẹ aarẹ ana. Bi iku rẹ ṣe ba mi ninu jẹ naa ni ipo to fi orilẹede mi Zimbabwe si pẹlu bami ninu jẹ gidigidi.

Oríṣun àwòrán, Reuters












