Zimbabwe: Ǹ jẹ́ ọrọ̀ ajé Zimbabwe bayìí dára ju ti ìṣèjọba Mugabe lọ?

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Oun ti a gbọ: Nkan ti le koko ni orilẹ-ede Zimbabwe ju igba ti aarẹ ana, Robert Mugabe wa lori alefa lọ. Fadzayi Mahere, ti ẹgbẹ alatako Movement for Democratic Change (MDC) lo sọ bẹẹ.
Oun ti iwadi gbe jade: Ootọ ni pe, ni awọn oṣu diẹ sẹyin, eto ọrọ aje orilẹ-ede Zimbabwe ti fidi rẹ́mi Sugbọn, awọn igba kan wa ni akoko ijọba Mugabe ti ọrọ aje orilẹ-ede naa buru ju bayi lọ.

Ẹgbẹ alatako ni orilẹede Zimbabwe ti pe fun ifẹhonu han, ti wón si na ọwọ abuku si ijọba ilẹ naa lori iṣowo baṣubaṣu.
Lati ọdun 2017, ni aarẹ Emmerson Mnangagwa ti n dari iṣejọba orilẹede naa lẹyin ti o gba ijọba lọwọ aarẹ ana, Robert Mugabe.
BBC si ti se iwadi lati mọ boya aye dẹrun fun ọmo orilẹede Zimbabwe ni akoko iṣejọba aarẹ Mnangagwa, ju igba iṣejọba aarẹ Mugabe lọ.
Ayẹwo ọrọ aje orilẹede Zimbabwe fi han pe, ọrọ aje ilẹ naa ti dẹnukọlẹ ju ti tẹlẹ lọ.
Awọn ọmọ orilẹede naa lee ni imọlara eyi nipa ọrọ aje ti o ti dẹnukọlẹ.
Bi o tilẹ jẹ pe awọn ọmọ orilẹede Zimbabwe n ni imọlara bi ọrọ aje wọn ṣe dẹnukọlẹ, sibẹ o sọro lati ṣọ kedere lẹyin iwadi yi pe, ọrọ aje ilẹ Zimbabwe ti dori kodo ju ti igba iṣejọba to kọja lọ.

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Ọna miran ti a tun fi le wo bi ọrọ aje orilẹede kan ṣe n dagba si, ni bi awọn ileeṣẹ nla ṣe n ṣe idokowo nibẹ.
Eyi ti fa sẹyin diẹ lorilẹede Zimbabwe lati ọdun 2017, sugbọn ijọba ni, eyi ṣẹlẹ nitori awọn ijẹniniya lati ọwọ awọn orilẹede miran lagbaye ni.
Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:
Awọn ijẹniniya wọnyi ṣe ipalara fun awọn eeyan jankan ninu iṣejọba ati awọn ileeṣe ti ijọba dasilẹ, eyi ti ijọba ilẹ Amẹrika si sọ pe, yoo maa tẹ siwaju afi bi eto oselu orilẹede naa ba ni atunṣe to jọju.
Nipa bi ọrọ aje orilẹede Zimbabbwe ṣe n pa awón ara ilu lara, ọwọn gogo ọja ati ọrọ aje ni o jẹ awọn ara ilu logun, ju iwaadi kankan ti ijọba lee fi lede lọ.
Lẹyin ti ọgbẹni Mugabe kuro lori aga iṣejọba ni ọdun 2017, ọwọn gogo ọja goke sii ni iwọn bi idamarun.

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Ọwọn gogo ọja lọ silẹ diẹ nipari ọdun 2018, sugbọn o tun gbera sọ ni ibẹrẹ ọdun 2019.
Onimọ nipa eto ọrọ aje, Steve Hanke sọ pe, ọwọn gogo ọja lorilẹede naa ju oye ti ijọba fi lede lọ ni osu kẹjọ ọdun 2019.
Fun idi eyi, ounjẹ ti wọn lọja, ko si epo bẹtiro, bẹẹ si ni owo awọn to ti fẹyinti lẹnu iṣẹ ko niyi mọ.
Ajọ agbaye to n ri si eto ounjẹ, United Nations World Food Programme (WFP), ti pe fun atilẹyin owo lati fi ra ounjẹ fun orilẹede naa, lẹyin ti wọn ti ni orilẹede Zimbabwe n dojukọ iyan ti ko ti ko ri iru rẹ ri.
Ajọ naa sọ pe, awọn eniyan ilẹ Zimbabwe n la ọgbẹlẹ kọja, ati pe, eto ọrọ aje wọn ti duro sojukan bi adagun odo.

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Ijọba orilẹede naa si ti n na owo tiwọn nigba keji, leyin ọdun mẹwa ti wọn ti n na owo ilẹ Amẹrika.
Eyi ti o ti fa ọpọlọpọ awuyewuye lati ọdọ awọn oṣiṣẹ ti o ti n gba owo oṣu wọn ni owo ilẹ Amẹrika tẹlẹri.
Njẹ orilẹede Zimbabwe ti la asiko to buruju kọja bi?
Bi o tilẹ jẹ pe nkan ko ṣẹnu ire lorilẹede naa lọwọ yii, awọn igba kan wa to jẹ pe, ọrọ aje ilẹ naa buru ju ti akoko yii lọ nigba iṣejọba Mugabe.

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Ni ọdun 2007 si 2009, orilẹede naa la asiko ọwọn gogo ti o buru jai kọja, ti o fi jẹ pe, owo orilẹede ọhun ko niye lori.
Ni saa kan ni ọdun 2008, ọrọ aje orileẹde Zimbabwe buru to bẹẹ gẹ ti ọpọlọpọ si di alainiṣe lọwọ.
Kini ipa ti ijọba ko?
Lẹyin ti ijọba tuntun ti gori aleefa lo ti n gbe awọn igbeṣẹ tuntun lọna lati mu ọrọ̀ aje orilẹede naa bọ sipo.

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Sugbọn onimọ nipa ọrọ aje kan lorilẹede naa, Godfrey Kanyenze, ti sọ pe, awọn eto ti ijọba Zimbabwe n ṣe ti yọri si ọwọn gogo ọja, ati pe, o ti sọ ọpọ ọmọ ilẹ Zimbabwe di alaini.














