Xenophobia: Kò sí wàhálà fún àwọn okòwò South Africa ni Eko

Sanwoolu

Oríṣun àwòrán, @sanwo olu

Àkọlé àwòrán, Awọn ara South Africa ko ni bẹru

Gomina Sanwo Olu fi ọkan awọn eeyan South Africa balẹ lori awọn okowo wọn.

Gomina to n tukọ ipinlẹ Eko, ti paṣẹ pe to ba ṣe di ọjọ Aje ki awọn oṣiṣẹ eleto aabo ipinlẹ Eko ṣe afikun si eto aabo awọn okowo South Africa.

O ni iṣẹlẹ ikọlu awọn ọmọ Naijiria ni orilẹ-ede South Africa ko dara to ṣugbọn ko yẹ ki awọn maa ba nkan jẹ pada.

Àkọlé fídíò, Amb.Oluwateru:Oju bọrọ kò ṣé gbọmọ lọ́wọ́ ekurọ South Afrika lori Xenophobia

Ninu atẹjade ti Ogbẹni Gboyega Akosile to jẹ akowe eto iroyin fun gomina Sanwo Olu fi ọwọ si lo ti paṣẹ aabo yii.

Gomina Sanwo Olu bẹnu ẹ̀tẹ́ lú iwa awọn ara South Africa si alejo ṣugbọn o tẹpẹlẹ mọọ pe ko dara lati fi oro ya oro.

O sọ fun awọn eniyan South Africa pé ijọba oun a pese aabo to peye fun ileeṣẹ wọn ati awọn okowo wọn.

attack

Oríṣun àwòrán, @others

Àkọlé àwòrán, O sọ fun awọn eniyan South Africa pé ijọba oun a pese aabo to peye fun ileeṣẹ wọn ati awọn okowo wọn.

Sanwo Olu sọrọ yii lẹyin to ṣabẹwo si Shoprite ni Sangotedo ati Surulere lati wo bi nkan ṣe bajẹ to si iroyin ti oun n gbọ lori iṣẹlẹ naa.

O ni o le ni ẹgbẹrun marun un eniyan to le padanu iṣẹ wọn lori iṣẹlẹ yii to jẹ ọmọ Naijiria.

O ni : a ti paṣẹ fawọn oṣiṣẹ eleto aabo wa lati daabo bo gbogbo ohun ini awọn ara South Africa nipinlẹ Eko.

O fi da awọn olokow South Africa loju pe ni gbogbo ileeṣẹ wọn ni awọn agbofinro a mojuto ti ilẹ ba ṣe mọ ni ọla ọjọ Aje.

Ni ipari Gomina Sanwo Olu rọ awọn ajeji to nileeṣẹ lati gbiyanju igbe aye alaafia pẹlu awọn eniyan adugbo wọn.

O ni irọrun eku lo difa fun irọrun ẹyẹ ni ati pe ti gbogbo nkan ba daru tan, ara ko ni rọ okun ati adiyẹ naa ni.

Bakan naa lo jiroro pẹlu awọn ọlọpaa lori igbesẹ ti ijọba maa gbe lori awọn ti ọwọ tẹ lọsẹ yii pe wọn n ba nkan awọn ara South Africa jẹ nileeṣẹ wọn.

O ni paapaa lori awọn to ji nkan gbe nile itaja gbogbo ọhun nitori pe iwa ole ko ni orukọ meji.

Àkọlé fídíò, Port harcourt Bole: Mi kò mọ́ pé bọ̀ọ̀lì títà lè gbé mi dé ipò yìí láyé mi!