Xenophobia: Àdúgbò Lugbe kan gbínrín torí ìkọlù àwọn olùfẹ̀hónú hàn

Awọn eeyan to n sewọde da ina soju popo
Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 3

Ọrọ di boo lọ, ko yago fun mi ladugbo Lugbe, nilu Abuja lọjọru nigba ti awọn eeyan kan to n fẹhonu han yari kanlẹ pe awọn yoo sun ile itaja ShopRite to wa ladugbo naa.

Ibudo itaja ọhun ni wọn gbagbọ pe o jẹ ti ọmọ orilẹede South Africa, ti wọn si setan lati gbẹsan ikọlu ti awọn ọmọ ilẹ South Africa n se sawọn ọmọ Naijiria to n gbe lọhun.

Koda, awọn eeyan to n fẹhonu han naa dana si oju popo, ti eefin si gba gbogbo agbegbe naa kan.

Ọkọ ijagun awọn ọlọpaa

Ikọ BBC to se abẹwo si agbegbe naa lọjọru jabọ pe awọn agbofinro ti kalẹ si agbegbe naa, ọpẹlọpẹ wọn ohun ti a n wi yii, kọ ni a ba maa wi.

Se ni awọn agbofinro ọhun tun lo afẹfẹ tajutaju ati omi lati fọn awọn eeyan to n fẹhonu han naa ka, amọ ti wọn n lọ korajọ pọ si ẹgbẹ keji lai lọ sile koowa wọn.

Awọn eeyan to n sewọde duro soju popo

Ọkọ ijagun nla ati kekere si lo wa nilẹ ti awọn ọlọpa gbe wa, ti wọn si n sọ agbegbe ibudo itaja naa bii ajẹ ti n sọ ile Olodumare, pe bi esinsin ba ta firi, awọn yoo wọn.

Bi a se n ko iroyin yii jọ, omi alaafia ko tii toro ni adugbo Lugbe ọhun nitori awọn eeyan to n sewọde ko tii kuro nibẹ.

Ọkọ ijagun awọn ọlọpaa

Ibudo itaja ShopRite naa ti wa sọ agadagodo sẹnu ọna rẹ, to si ti kede pe yoo wa ni titipa fun igba diẹ naa lati dẹkun ikọlu.

"Ọjà àìmọye mílíọ̀nù naira ni wọ́n kó nílé ìtajà mi torí ìgbẹ̀san ìkọlù South Africa"

Ọrọ ikọlu to n waye sawọn adulawọ ati awọn ọmọ Naijiria lorilẹede South Africa ti bẹyin yọ lọjọ Isẹgun nitori iwa igbẹsan ti awọn eeyan kan nilu Eko gunle.

Ile itaja ni Lekki ti wọn kọlu

Oríṣun àwòrán, @Love96047280

Ladugbo Lekki ni iroyin ti gbalẹ kan pe awọn araalu kan to n fẹhonu han ti ya bo ile itaja kan to wa nibẹ, ti wọn si n ko oniruuru ọja lati fi gbẹsan bi awọn ọmọ orilẹede South Africa se n kọlu awọn ọmọ Naijiria.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Ni bayii, osisẹ kan nile itaja naa ti n gbarata loju opo Twitter rẹ pe isẹlẹ naa ti kọja igbẹsan sawọn ọmọ orilẹede South Africa, amọ awa ara wa ni Naijiria la n doju kọ ara wa.

Skip X post, 1
Allow X content?

This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.

Warning: Third party content may contain adverts

End of X post, 1

Lily Loveth@Love 96047280 ke gbajare pe awọn araalu ati awọn alaisẹ ni awọn eeyan to n fẹhonu han naa n dojukọ bayii, papaa bi wọn se wa kọlu ibudo itaja ti oun ti n sisẹ.

Ile itaja ni Lekki ti wọn kọlu

Oríṣun àwòrán, @Love96047280

O ni ọpọ ọja ti owo rẹ to aimọye miliọnu naira ni wọn ko lọ nibẹ lai jẹ pe ara South Africa lo ni ibudo itaja naa.

Bakan naa lo fikun pe o seese ki oun padanu isẹ oun nitori ikọlu yii, to si n beere pe ki lo de tawọn eeyan naa se n kọlu awọn araalu ti wọn sọ pe awọn n ja fun.

Skip X post, 2
Allow X content?

This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.

Warning: Third party content may contain adverts

End of X post, 2

"Ẹ gba mi, isẹ ti fẹ bọ lọwọ mi, ọmọ Naijiria lo ni ibudo itaja ti mo ti n sisẹ, kii se ọmọ South Africa, ija yii ti wa dojukọ alaisẹ, ki lo maa n se awọn eeyan dudu gan? Se ni wsn n lo isẹlẹ ikọlu ni South Africa lati boju fi sisẹ ibi."

Lily wa parọwa pe ki awọn eeyan fọwọ wọnu lori isẹlẹ naa, tori ta ba ro didun ifọn, a họra de egungun.