Xenophobia: Alùpùpù ni wọ́n fi gbé epo pẹtiró wá dáná ṣun iléeṣẹ́ MTN

Awọn eeyan kan to n fẹhonu han dana sun ẹka ọọfisi ileeṣẹ ikansiraẹni lati orilẹede South Africa, MTN, to n bẹ ni agbegbe Bodija niluu Ibadan lalẹ Ọjọ Iṣẹgun mọju Ọjọru.
Iṣẹlẹ naa ni ko se lẹyin ikọlu ti awọn ọmọ orilẹede South Africa n ṣe si awọn ajeji to n bẹ nilẹ wọn, ninu eyi ti ọpọ ọmọ Naijiria ti fara gba.
Aṣoju ajọ to n mojuto igbokegbodo ọkọ ni ipinlẹ Ọyọ, Ọgbeni Adeoye Ayọade ṣe alaye fun awọn akọroyin pe, alẹ Ọjọ Iṣẹgun ni isẹlẹ naa waye.
- "Ọjà àìmọye mílíọ̀nù naira ni wọ́n kó nílé ìtajà mi torí ìgbẹ̀san ìkọlù South Africa"
- "Naijiria gbọdọ̀ kẹ̀yìn sí ìrẹ́pọ̀ pẹ̀lú South Africa"
- Xenophobic Attack: 'Nàìjíríà ló máa forí kó kíkọlu iléeṣẹ́ South Africa jùlọ'
- Xenophobic Attack: Àwọn ọmọ Nàìjírìá bínú kọlu Shoprite l'Eko
- Àjọ Commomwealth gbọ̀dọ pé ìpáde pàjáwìrì lori ọ̀rọ̀ Brexit- Wole Soyinka
Ayọade ni awọn kan lo gbe alupupu wa, ti wọn si lu awọn ọlọdẹ to n ṣọ ọọfisi naa ni bii aago mẹwa aabọ alẹ ana, lẹyin eyii ni wọn si dana sun ọọfisi ileesẹ MTN naa pẹlu kẹgi ẹpo bẹntiro ti wọn gbe dani.

Ọkan lara awọn eeyan to n kọja lasiko ti iṣẹlẹ naa waye, Ọgbẹni Ademọla fi idi isẹlẹ naa mulẹ pe lasiko ti ohun lọ si ẹnu iṣẹ ni alẹ ana ni ina dede sọ ni ọọfisi MTN ọhun.
Bi o tilẹ jẹ pe ọpọ dukia ileesẹ naa lo jona mọle amọ ko si ẹmi to bọ ninu isẹlẹ ile jijo naa, ti ijakulẹ si ba ọpọ awọn onibara ileesẹ MTN to de sẹnu ọna ileesẹ ọhun ni aarọ Ọjọru.
Se ni jẹbẹtẹ si gbe ọmọ le ọpọ awọn onibara MTN lọwọ nigba ti wọn ri pe ileesẹ naa jona kọja aala.









