U.I Language Centre: Yorùbá ló làṣà àti èdè

Àkọlé fídíò, U.I Language Centre: Yorùbá ló làṣà àti èdè

Ede Yoruba dùn lẹnu awa ọmọ ilẹ̀ Amẹrika.

Ede ati aṣa Yoruba ti di itẹwọgba ni oke okun ni eyi to n mu awọn akẹkọọ oyinbo ilẹ Amerika lati wa kọ nipa rẹ sii ni Naijiria.

BBC Yoruba kan si ẹka ibi iṣẹ fun ede Yoruba, Yoruba Language Centre ni ọgba ẹlẹranko Fasiti ni Ibadan lati mọ bi eto ẹkọ ede Yoruba naa ṣe n lọ si.

Ojọgbọn Oye Taiwo to n dari ibi iṣẹ naa lọwọlọwọ ṣalaye kikun fun BBC lori irufẹ awọn akẹkọọ to n wa ati pataki eto ẹkọ yii.

Diẹ lara awọn akẹkọọ Yoruba oloṣu meji ti BBC ba sọrọ ni Fasiti ti sanmọnti gbe dunlẹ ni Hannah Sawyer, Aminat Sanusi, Fredrick Clement, Damilola Abigeal atawọn mii.

Ojọgbọn Oye ṣalaye nipa eto oloṣu meji, mẹta ati mẹsan an nibi ti wọn ti le da duro ti awọn ọmọ oyinbo yii si n fi imọ ede Yoruba jẹun.

Oludari yii ni lọdọọdun ni ijọba ilẹ Amẹrika n fọmọ wọn ranṣẹ si Fasiti Ibadan lati wa kọ nipa ede ati aṣa Yoruba.

Ki ni o wa ṣe awa ọmọ Yoruba gangan ti a ko kọ ọmọ wa sii nipa ede ati aṣa Yoruba?

Ipenija ni eyi jẹ fun gbogbo ogidi ọmọ ku-ootu-oojiire-bi? lati ṣe ohun to yẹ fun idagbasoke ede ati aṣa Yoruba lasiko yii.