Xenophobia: Àwọn agbófinró dúró sẹ́nu ọ̀nà àbáwọlé Palm Mall Ibadan láti dẹ́kun ìkọlù

Ọrọ ikọlu ti awọn ọmọ Naijiria n se sawọn ileesẹ to jẹ tilẹ South Africa lati fi gbẹsan bi wọn se n kọlu awọn ọmọ Naijiria lorilẹede tiwọn naa, ti wa di ọrọ egbinrin ọtẹ, ba ti n pakan ni omiran n ru.
Idi ni pe lọjọ Isẹgun lawọn eeyan kan to n fẹhonu han morile awọn ileesẹ South Africa to wa nilu Ibadan, ti wọn si kọlu wọn, koda, wọn dana sun ileesẹ MTN to wa ni Bodija, ti wọn si ko ọpọ ẹru olowo iyebiye ni ile itaja Shoprite to wa ni Ring Road.
- Àwọn èèyàn to n fẹ̀hónú hàn dáná ṣun iléeṣẹ́ MTN n‘Ibadan
- "Ọjà àìmọye mílíọ̀nù naira ni wọ́n kó nílé ìtajà mi torí ìgbẹ̀san ìkọlù South Africa"
- "Naijiria gbọdọ̀ kẹ̀yìn sí ìrẹ́pọ̀ pẹ̀lú South Africa"
- Xenophobic Attack: 'Nàìjíríà ló máa forí kó kíkọlu iléeṣẹ́ South Africa jùlọ'
- Xenophobic Attack: Àwọn ọmọ Nàìjírìá bínú kọlu Shoprite l'Eko
- Àjọ Commomwealth gbọ̀dọ pé ìpáde pàjáwìrì lori ọ̀rọ̀ Brexit- Wole Soyinka
Niwọn igba to si jẹ pe ina eesi kii jo ni lẹẹmeji, awọn alasẹ ileesẹ Shoprite to wa ni ibudo itaja Palm Halm ni Ribgroad naa, ti wa sọ agadagodo sẹnu ọna ibudo itaja Palm Mall lapapọ lati dena ikọlu ẹẹkeji.

Nigba ti BBC Yoruba se abẹwo si ibudo itaja naa, wa wa wa ni awọn agbofinro gbarodan sẹnu ọna abawọle ibẹ, ti wọn si setan lati wọn esinsin to ba ta firi nibẹ.
Koda, awọn osisẹ ati onibara to fẹ wọle sibudo itaja naa ni jẹbẹtẹ gbe ọmọ le lọwọ nigba ti wọn foju kan awọn agbofinro naa, ti ẹnikẹni ko si lee wọle tabi jade latinu ibudo itaja naa.

Nigba to n ba BBC Yoruba sọrọ, awọn osisẹ ibudo itaja naa salaye pe ọna lati mase jẹ ki itakun kan soso da awọn lepo nu lẹẹkeji lo mu ki awọn alasẹ ileesẹ Shoprite gbe igbesẹ naa, tori owo gọbọi ni wọn padanu lọjọ Isẹgun lasiko ikọlu awọn eeyan to n fẹhonu naa, ti wọn ko ọpọ ọja wọn.
Amọ sa, igbesẹ titi ibudo itaja Palm Mall ti n se akoba nla fun awọn ọmọ Naijiria to ni sọọbu sinu ibudo itaja naa nitori kii se Shoprite nikan lo n ta ọja nibẹ.

Osisẹ agbofinro agba fun ibudo itaja naa, Tony, salaye pe ọpẹlọpẹ awọn osisẹ agbofinro, ninu eyi ta ti ri awọn ọlọpa atawọn aabo ara ẹni laabo ilu (Civil Defence) ti wọn tete pana ikọlu tawọn ọmọ Naijiria se si ibudo itaja naa lọjọ Isaẹgun eyi ti wọn fi n gbẹsan.
Naijiria gbọdọ kẹyin si irẹpọ pẹlu South Africa
Igbakeji Aarẹ orilẹede Naijiria ki kesi awọn adari lorilẹede South-Africa pẹlu ibanujẹ ọkan lati dẹkun ipaniyan nitori ẹya to n lọ lọwọ lorilẹede South Africa.
Osinbajo lasiko to n ba awọn oniroyin sọrọ ni ipinlẹ Kano, sọ wi pe o lodi si igbelarugẹ ẹto ọmọniyan ti awọn adari ilẹ South Africa ja fun ni igba aye wọn.

Oríṣun àwòrán, Getty Images
O ni oun to buru jai ni lati kọju ija si awọn ọmọ Naijiria ti wọn wa ni South Africa bayii, nitori pe Naijiria pẹlu awọn to ja fun ominiran ilẹ naa lọwọ awọn amunisẹru.
Bẹẹ lo wa kesi ijọba orilẹede naa lati dide ati lati wa wọrọkọ fi sada lori ipaniyan naa ki oun gbogbo le pada si ipo.
'Naijiria gbọdọ̀ kọ ìrẹ́pọ̀ pẹ̀lú SouthAfrica '
Bakan naa, Igbakeji Aarẹ Ile igbimọ Asofin to kọja, Ike Ikeremadu ti kesi ijọba orilẹede Naijiria lati jawọ ninu gbogbo irẹpọ pẹlu orilẹede South Africa, titi ipaniyan awọn ọmọ Naijiria lorilẹede naa yoo fi dopin.
Ikeremadu ni o seni laanu pe ijọba orilẹede South Africa fi ọwọ yẹpẹrẹ mu ipaniyan to n waye naa, lo se di ohun to n la ẹmi ọpọlọpọ eniyan lọ.

Oríṣun àwòrán, Getty Images
O wa kesi ijọba Naijiria lati ri wi pe ijọba ilẹ South Africa da gbogbo ikolọ awọn ọmọ Naijiria ti wọn bajẹ pada, bakan naa ni ki wọn fi imu awọn aseka yii fọn fere.
Ike Ekeremadu naa parọwa si Ajọ isọkan Ilẹ Afirika, Africa Union lati da si ọrọ naa, ki o to di gbọnmi si, omi o to laarin orilẹede mejeeji.













