Makinde: Ẹgbẹ́ òṣèlú PDP ní àwọn kò padà lẹ́yìn Seyi Makinde, gómìnà ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́

Makinde atawọn asiwaju ijọba ipinlẹ Ọyọ

Oríṣun àwòrán, @oyostategovt

Ọrọ Ẹgbẹ oṣelu PDP ati APC nipinlẹ Ọyọ ti di ti ologbo ati eku bayii paapaa julọ lori ọrọ gomina Ṣeyi Makinde ati iṣejọba rẹ nipinlẹ naa.

Laipẹ yii ni iroyin jade pe ẹgbẹ oṣelu APC n pariwo sita pe iṣejọba gomina naa ko ba awọn aṣaaju ẹgbẹ oṣelu rẹ, iyẹn PDP lara mu, wọn si ti n kọ ẹyin wọn sii lọkọọkan ejeeji.

Haa-hin in ni iroyin naa ṣe ọpọ onwoye nitori pe ko si ẹni lee ro pe ẹgbẹ kan to wa lori alefaa lee kẹyin si aṣoju wọn ninu iṣejọba.

Amọṣa, ẹgbẹ oṣelu PDP ti ni ko si nnkan to jọọ rara ni nitori pe ọmọ ẹnii kii ṣe idi bẹbẹrẹ ka fi ilẹẹkẹ sidi ọmọ ẹlomiran.

Atẹjade kan ti ẹgbẹ oṣelu PDP fi sita eyi ti alukoro rẹ, Akeem Ọlatunji fi ọwọ si ṣalaye pe ẹgbẹ oṣelu APC nipinlẹ Ọyọ kan Ọ̀Rọ̀ n tun irọ ta faraalu ni.

O ni gbagbagba lawọn aṣiwaju ati gbogbo ọmọ ẹgbẹ oṣelu PDP wa lẹyin Gomina Makinde atipe iṣọkan to jina denu lo wa laarin ẹgbẹ oṣelu naa.

Àkọlé fídíò, Wòlíì Kasali sọrọ nípa awuyewuye pé o lè ìyàwó rẹ̀ jáde nílé