NNPC: Kyari ṣàlàyé ohun tó fa ẹ̀dínkù iye epo rọ̀bì tí wọ́n ń kó níbùdó ìpọnpo ní Nàìjíríà

Ibudo iponpo

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Àkọlé àwòrán, Ọga agba NNPC Mele Kyari ni ijọba apapọ yoo tubọ tẹra mọ gbigbogun ti iwa fayawọ epo rọbi lorilẹede Naijiria.

A ti n gbe gbogbo igbese tó yẹ lati fopin si iwa fayawọ epo rọbi -Mele Kyari

Ọga agba ajọ elepo rọbi orilẹ-ede Naijiria, (NNPC) Mele Kyari ti kede pe iye agba epo ti wọn n gbe lawọn ibudo ikepo si lorilẹ-ede Naijiria ti dinku lati nnkan bii ọjọ kejilelogun, oṣu kẹjọ ọdun.

Ninu atẹjade kan ni Ọgbẹni Mele Kyari ti ṣalaye ọrọ yii lori oju opo Twitter rẹ.

O ni eyii nii ṣe pẹlu bi awọn ajọ alaabo ṣe ti awọn aala orilẹ-ede Naijiria pẹlu awọn orilẹ-ede gbogbo to yii ka lọna ati lee dẹkun fayawọ lorilẹ-ede Naijiria.

Ọga agba ajọ NNPC naa ni gbogbo igbesẹ to ba yẹ ni ijọba atawọn ajọ alaabo gbogbo yoo gbe lati dẹkun fayawọ epo rọbi lorilẹ-ede Naijiria.

Àkọlé fídíò, Nigeria models: Ẹ má bóra mọ́, ọmọ dúdú dùn lọ́mọbìnrin