Xenophobia: South Africa gbọ́dọ̀ dá owó ìtanràn padà kí wọ́n si fìyà jẹ àwọn ti ọ̀rọ̀ kàn -Sen Basiru

Oríṣun àwòrán, @others
Senatọ Basiru ni koda wọn gbọdọ san owo gba-ma-binu fawọn ti wọn ba nkan wọn jẹ.
Senetọ Basiru Ajibọla to n ṣoju aarin gbungbun Oṣun naa bu ẹnu ẹ̀tẹ́ lu iwa biba nkan ẹlomiran jẹ to ṣẹlẹ ni orilẹ-ede South Africa.
O ni iṣẹ ilu ati awọn ti a yan sipo ni lati daabo to peye bo ẹmi ati dukia awọn eniyan abẹ wọn.
O ni eyi ku diẹ kaa to ninu iwa awọn adari orilẹ-ede South Africa lori iṣẹlẹ yii.
Senetọ to n dari igbimọ yii nile aṣofin agba ni Abuja ni iwa buruku gbaa ni awọn eniyan ilẹ South Africa hu yii ni eyi ti ko dara fun ilẹ Adulawọ rara.
O ni ọpọ igba ni ikọlu si awọn ọmọ Naijiria ti n waye ni South Africa ṣugbọn bayii, o to gẹẹ ni.
O ni ko si abajade pe ijọba South Africa fiya jẹ awọn oniṣẹ ibi yii ri lati ẹyin wa ni eyi to gbọdọ dopin lasiko yii.
Bakan naa lo bu ẹnu ẹ̀tẹ́ lu iwa ki awọn ọmọ Naijiria naa maa fi oro ya oro nipa biba nkan awọn ara South Africa jẹ ni NaijiriaÀwọn ọmọ Naijiria kóju ija sí àwọn South Africa wọ́n ní "Ó tó gẹ́".
O ni asiko ti to ki ijọba Naijiria wagbo dẹkun fun iru ikọlu yii lori awọn eniyan rẹ kaakiri agabye paapaa ni south Africa.
O ni oun gbagbọ pe ko le si ninu ofin South Africa lati maa fiya jẹ awọn ajeji ni ilu wọn rara.
O ni ṣugbọn o jọ gate ko jọ gate ni ọrọ naa.
Basiru ni o ṣeni laanu pe ajọ iṣọkan ilẹ Adulawọ ko ri ohun kanakn to ṣe gboogi ṣe lori ọrọ yii.
O ṣe apẹrẹ pe awọn omo Naijiria to n gbe ni South Africa le ni 800,000 ni eyi ti ko le fi rọrun lati kan palẹ wọn mọ maa bọ nile.
Senatọ yii ni ijọba Naijiria ṣi ni iṣẹ lati ṣe lati gba owo itanran fawọn ti ọrọ kan.
O ni iṣẹ wa lọwọ ijọba lati ṣatunṣe si ọrọ eto ọrọ aje Naijiria ki awọn ero dinku ti wọn n wa jijẹ mimu lọ silẹ okeere.













