Oxfam: Olówó mẹ́ta ní Afirika lówó ju 650m aláìní lọ

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Abajade iwadi kan ti sọ pe, owo ti awọn eeyan marun un to lowo ju ni Naijiria ni, le dẹkun oṣi oun iṣẹ lorileede naa.
Ajọ ẹlẹyinju anu ilẹ Gẹẹsi ni Oxfam Charity lo fi abajade yii sita lọjọ Iṣẹgun.
Ninu iwadi naa, wọn ni owo to wa lọwọ awọn ọkunrin mẹta to lowo julọ ni ilẹ Afrika, kọja ti awọn ẹgbẹta le ni aadọta miliọnu alaini to wa nilẹ naa.
Abajade iwadi naa, ti wọn pe orukọ rẹ ni ''A Tale of Two Continents'' ṣafihan bi iṣẹ ṣe n lọ soke ni Naijiria ati ilẹ ni Afrika, ti aiṣedeede ọrọ aje si tun n da kun iṣoro kikoju aini nilẹ naa.
Bakannaa ni esi iwadi Oxfam tun tọka si bi ọrọ awọn to lowo julọ ni Afrika ṣe n pọ si, ti iṣẹ oun aini si n lọ si oke laarin awọn alaini.

Oríṣun àwòrán, Getty Images
''Ilẹ Afrika n lewaju laarin awọn ilẹ agbaye gẹgẹ bi ibi ti oṣi oun iṣẹ ti n peleke. Bi iye awọn eeyan to n na owo ti ko to dọla meji lojumọ ṣe n dinku ni ilẹ Asia, bẹẹ lo n pọ si ni Afrika''
Ọga agba ni Oxfam, Winnie Byanyima ni ''Afrika ṣetan lati dagbasoke ṣugbọn ko le ṣeeṣe ti awọn olori ko ba lẹmi lati gbaruku ti awọn to fẹ ṣiṣẹ mu agbega ba araalu dipo awọn olowo''
Esi iwadi naa ṣe agbekalẹ ohun ti awọn orileede Afrika n ṣe lati mu opin ba iṣẹ oun oṣi.

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Orileede South Afrika ati Namibia lewaju ninu ilakaka yii, ti Naijiria si ru póò nilẹ Afrika ati lori akasọ agbaye.
Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:
- Ọ̀dọ́mọdé Onímọ̀ ẹ̀rọ rèé tó ń ṣe bàálù, ọkọ̀, ilé àti ọkọ̀ ojú omi
- "Bàbá mi kú, kò sówó ni mo ṣe kúrò ní fásitì Ilorin láti fọ gíláàsì ọkọ̀ lójú pópó"
- Adúmáadán ni mí; ọmọ pé síbẹ̀! - arìnrìn oge
- Lẹ́yìn ìgbeyàwó ọdún mọ́kànlá àti ọ̀pọ̀ ìjà, Bọsẹ di èrò ọ̀run nílé Saidi
- Xenophobic Attack: 'Nàìjíríà ló máa forí kó kíkọlu iléeṣẹ́ South Africa jùlọ'
- Àjọ Commomwealth gbọ̀dọ pé ìpáde pàjáwìrì lori ọ̀rọ̀ Brexit- Wole Soyinka
- Ìdí ti àwọn kọmísọna ṣe to láti kí ìyáwó gómìnà tuntun káàbọ̀
Awọn nnkan miran ti iwadi naa sọ ni pe:
- Swaziland ni aiṣedede laarin awọ́n to ni ati alaini ti peleke ju nibi ti olowo kan Nathan Kirsh to ni biliọnu dọla mẹrin le diẹ.Iwadi fi han pe to ba n ṣiṣẹ ọmọ ọdọ ile ounjẹ,ọdun miliọnu marun un le diẹ ni yoo fi ṣiṣẹ ki o to le ri iru owo yi .
- Ida marundinlọgọrin ninu ọgọrun awọn olowo Afrika lo ṣeeṣe ki owo wọn wa loke okun.Eyi mu ki ilẹ Afrika ma padanu owo to to biliọnu mẹrinla dọla owo ori to yẹ ki wọn ma gba lọdọọdun.
- Owo tawọn orileede kọọkan jẹ ni gbese n ṣakoba fun iye ti wọn n na.Lọdun 2018,Angola na ida mẹtadinlgọta ninu ida ọgọrun owo ijọba lati fi san gbese ti wọn si mu adinku ba iye ti ijọba n na pẹlu ida mọkandinlogun laarin ọdun 2016 si 2018.Bakannaa lo ṣẹlẹ ni Ghana Egypt,Cameroon ati Mozambique












