South Africa killings: Sanwo-Olu ní àwọn ọmọ Nàìjíríà tó gbẹ̀san ìkọlù àjòjì ní South Africa ti yọ ọmọ Nàìjíríà 5000 níṣẹ́ l'Eko

Oríṣun àwòrán, @jidesanwoolu
Ṣe awọn agba bọ wọn ni ọrẹ mi yaso emi naa a ya temi, afaimọ konitọun ma ṣe gaa sara
Eyi gan an lo difa fawọn to kọlu awọn ileeṣẹ to lọwọ orilẹede South africa ninu nilu Eko nitori ikọlu awọn ajoji to n waye lorilẹede South Africa.
- South Africa gbọ́dọ̀ dá owó ìtanràn padà kí wọ́n si fìyà jẹ àwọn ti ọ̀rọ̀ kàn -Sen Basiru
- Ìdí rèé ti Nàìjíríà fí ń gbé inú òkùnkùn
- Akeredolu ò ṣe ǹkan àrítọ́kasi ni Ondo- Komísọnà ọ̀rọ̀ to n lọ tẹ́lẹ̀rí
- Ààbò tó péye wà fún àwọn okòwò ará South Africa ni Eko -Sanwo Olu
- Ìkọlù sáwọn àjèjì kò tíì tán ní South Africa, ètò ń lọ láti kó ọmọ Nàíjíríà wálé
- Láìpẹ́, ará ìlú rẹ ni ọlọ́pàá tí yóò máa ṣọ́ ìlú rẹ
- Ta ló leè rò pé ọmọ mẹ̀kúnnù bí èmi leè dé ipò alága NURTW? - MC Oluomo
Ni bi a ti ṣe n sọrọ yii, ẹgbẹrun marun eeyan lo ti padanu iṣẹ wọn nipinlẹ Eko nitori ikọlu ẹlẹsan tawọn ọmọ Naijiria kan ṣe sawọn ileeṣẹ ti wọn wo pe awọn ọmọ orilẹede South africa ni nilu Eko.

Oríṣun àwòrán, @jidesanwoolu
Gomina ipinlẹ Eko, Babajide Sanwo-olu lo fẹ idi ọrs yii sita lasiko abẹwo rẹ sawọn ileeṣẹ ati ohun elo tawọn olufẹhonuhan bajẹ nilu Eko lasiko ti wọn fi nkọlu awọn ohun to jẹ tawọn ọmọ ilẹ South Africa naa.
Gomina Sanwo-Olu koro oju si bi awọn eeyan kan ṣe lo anfani iṣẹlẹ naa lati lọ maa fọ awọn ile itaja nlanla l'Eko.
O ni ọrọ naa ti di ti papa to n pa ara rẹ to ni oun n pa aja; nitoripe pẹlu ikọlu ọhun awọn ọmọ orilẹede Naijiria gan lo fara ko iṣẹlẹ naa.













