Fake Ceritificate: Ìjọba Ọṣún ní yóò ṣoro láti gba òṣìṣẹ́ tó ní ẹbu ìwé ẹ̀rí síṣẹ́ mọ́

Awọn osisẹ Ọsun n fi ẹhonu han

Oríṣun àwòrán, NLC

Kọmiṣọna ana feto iroyin, to tun jẹ alakoso fun eto iroyin bayii nipinlẹ Ọṣun, Adelani Baderinwa, ti sọ pe, yoo ṣoro lati gba awọn to ni ayederu iwe ẹri sẹnu iṣẹ nipinlẹ ọhun lasiko yii.

Baderinwa lo sọrọ yii ninu ifọrọwerọ pẹlu BBC Yoruba, lori awọn eeyan bii okoolenirinwo ati meji ti ijọba ipinlẹ naa fẹ daduro, lẹyin ti wọn fi ayederu iwe ẹri wọ iṣẹ ijọba.

O ṣalaye pe, ipinlẹ naa ko gba ẹnikẹni sẹnu iṣẹ lọwọ yii, ati pe awọn ilana ti wa ti ijọba ipinlẹ naa yoo tẹle, ti ko fi ni gba awọn to ba ni ayederu iwe ẹri sẹnu iṣẹ mọ.

Kọmiṣọna ana ọhun ṣalaye fun BBC pe, awọn osisẹ ti aje ọrọ naa ṣi mọ lori ni ijọba ti ni ki wọn lọ rọku nile, sugbọn ijọba ko pe wọn lẹjọ lẹyin ti ẹgbẹ awọn oṣiṣẹ, NLC, ẹka ti ipinlẹ Ọṣun da si ọrọ naa.

Awọn osisẹ Ọsun n fi ẹhonu han

Oríṣun àwòrán, NLC

Baderinwa ni, ibaṣepọ to ye kooro wa laarin ijọba ati ẹgbẹ awọn oṣiṣẹ ipinlẹ Ọsun.

Adari ẹgbẹ oṣiṣẹ NLC ni ipinlẹ Ọṣun, Babatunde Adekomi ni, ijọba Arẹgbẹṣọla lo kọkọ pinlẹ iwadi naa, ti ọrọ si kan awọn osisẹ to le ni ẹgbẹrun marun un, sugbọn ti ajọ NLC da si ọrọ naa, ki o to di pe aje ọrọ ṣi mọ okoolenirinwo ati meji lori.

Nipa awọn ti aje ọrọ naa ṣi mọ lori yii, Adekomi sọ pe akitiyan NLC ni ko jẹ ki ijọba pe awọn eeyan ọhun lẹjọ.

O salaye siwaju pe, NLC n ṣakitiyan lati ri pe ko si ayederu oṣiṣẹ nipinlẹ ọhun, nipa ibaṣepọ pẹlu awọn ileewe giga lati ri pe wọn ni akọsilẹ to peye nipa awọn akẹkọ ti wọn n kọ.

Adekomi wa parọwa si awọn oṣiṣe ipinlẹ Ọsun lati mura siṣẹ, lẹyin naa lo rọ awọn okoolenirinwo ati meji ti ọrọ naa kan, lati wa owo miran ti wọn lee ṣe, lọna lati ri ounjẹ oojọ.