Police Attack: Ọ̀bẹ ni ọkùnrin kan fi pa Ọlọpàá mẹrin ni Paris

Oríṣun àwòrán, EPA
Ọkunrin kan ti o n mu ọbẹ rin ni o ti ṣeku pa Ọlọpaa mẹrin ni ilẹ Faranse ni olu ile iṣẹ ajọ naa.
Ọkunrin naa ti ko i ti si ẹni ti o mọ orukọ rẹ ni awọn Ọlọpaa ti yinbọn lu ti wọn si ran lọrun.
Iroyin fi yewa pe, ara awọn oṣiṣẹ ile iṣẹ ajọ Ọlọpaaa ni ọkunrin naa.
Lọwọlọwọ yii, ko i tii si atẹjade kankan lati lori ọrọ naa ṣugbọn ti ojuko ibi iṣẹlẹ naa si,- ilé de la Cité- ti wa ni titi pa.
Iṣẹlẹ yii waye lẹyin iyanṣe lodi ọlọjọ kan ti awọn Ọlọpaa naa gunle ṣaaju latari akọlu atigba -degba ti o wọn ṣe si ajọ naa.
Iṣẹlẹ yii waye ni nkan bii agogo kan ni inu ile iṣẹ naa.
Minisita agba fun ilẹ Faranse , Edouard Philippe ati ojugba rẹ ni ẹka ọrọ abẹle, Christophe Castaner ni wọn wa ni ojuko iṣlẹ naa.

Oríṣun àwòrán, Reuters
Adari agba ni ilẹ Paris, Anne Hidalgo fi idi ọrọ naa mulẹ lori itakun ayelujara rẹ pe, ọpọlọpọ awọn eniyan ni wọn ti pa.
O ni ainiye awọn tti ko mọwọ mẹse ṣugbọn ti wọn ti rọrun latari isẹlẹ naa ti awọn miran si farapa.
Gẹgẹ bi awọn oṣiṣẹ ibẹ ti wi, arakunrin naa nṣiṣẹ ni ẹka bi inkan ti n lọ ni ile iṣẹ ajọ Ọlọpaa naa.












