Headies Award: Orinkórin ni Naira Marley ń kọ

Naira Maley

Oríṣun àwòrán, @officialnairam1

Àkọlé àwòrán, Ajọ EFCC ni, naira Maley n ṣagabtẹru iwa jibiti ninu orin rẹ

Ayo Animasahun to jẹ oludasilẹ ileeṣṣẹ Hip TV ti sọ fun BBC pe, wọn pinu lati yọ orin Naira Maley kuro ni 'Headies Award' ọdun yii nitori pe orinkorin lo n kọ.

Animasahun tẹsiwaju pe, ileeṣẹ oun kii ṣagbatẹru orinkorin.

Hip TV ni ileeṣẹ to n ṣagabatẹru Headies Award lọdọdun.

Ọjọ kini oṣu yii ni wọn fi orukọ awọn ti wọn fẹ fun ni ami ẹyẹ Headies Award ọdun yii lede, sugbọn orukọ Naira Marley ko si nibẹ.

Lẹyin eyii ni awọn ololufẹ Naira Marley bẹrẹ si n fi eroungba wọn lede lori ẹrọ ayelujara, ti wọn si n bere idi ti orukọ rẹ ko ṣe si ninu orukọ awọn eeyan naa.

Naira Maley to jẹ olorin takasufe lo ti gbe oriṣiriṣi orin jade bi, 'Am I a Yahoo boy?' 'Soapy' ati 'Puta.'

Ọpọlọpọ awuyewuye lo yi olorin naa ka, lẹyin ti ajọ to n gbogun ti iwa ibajẹ, EFCC gbe lọ ile ẹjọ lori ẹsun to jọ mọ iwa jibiti ati gbajuẹ.

EFCC lo fi ṣikun ọba mu ni ibẹrẹ ọdun yii, lẹyin ti wọn ni o n gbe iwa jibiti larugẹ ninu orin rẹ.

Headies Award jẹ ọkan gboogi lara awọn ayẹyẹ ti wọn fi n yẹ awọn olorin si, ti ọpọlọpọ olorin takasufe si ma n gba ami ẹyẹ nibẹ.

Ọjọ kọkandinlogun oṣu yii ni ayẹyẹ Headies Award naa yoo waye ni ipinlẹ Eko.

Àkọlé fídíò, Blacksmith: èmí ni ìran keje tó jogún iṣẹ́ àgbẹ̀dẹ yii- Alatiṣe