Minimum wage: Fayemi kéde sísan 30,000 owó oṣù òṣìṣẹ́ tó kéré jù láti ìparí oṣù yìí

Oríṣun àwòrán, Facebook/Kayode Fayemi
Gomina ipinlẹ Ekiti, Kayode Fayemi ti sọ pe awọn oṣiṣẹ ipinlẹ naa yoo bẹrẹ si ni gba ẹgbẹrun lọna ọgbọn owo to kere ju fun awọn oṣiṣẹ lati ipari oṣu yii.
Fayemi lo fi ọrọ naa lede nibi ayẹyẹ ayajọ ọjọ awọn olukọ ti ọdun 2019 to waye ni papa iṣere Oluyeme Kayode l'Ado Ekiti
Gomina Fayemi ṣalaye pe, ereedi ti ijọba rẹ ṣe fẹ san owo naa ni lati ṣe iwuri fun awọn oṣiṣẹ ipinlẹ Ekiti, paapaa julọ awọn olukọ.
Ni kete ti Fayemi sọrọ naa ni awọn eeyan to wa nibi ayẹyẹ naa fo fayọ ti wọn si n kan sara si gomina ọhun.

Oríṣun àwòrán, Facebook/Kayode Fayemi
Fayemi wa parọwa si awọn oṣiṣẹ ọun lati gbajumọ iṣẹ wọn, ki wọn si ri pe ina eto ẹkọ ko jo ajorẹyin ni ipinlẹ Ekiti.
O ni "a o bẹrẹ si ni san ẹgbẹrun lọna ọgbọn owo to kere ju fun awọn oṣiṣẹ ni ipinlẹ Ekiti lati ipari oṣu yii."
"A ti ṣetan lati ṣe moriwu fun awọn oṣiṣẹ to jafafa lẹnu iṣẹ wọn, paapaa julọ awọn olukọ ti wọn ti bu iyi fun ipinlẹ wa."
Fayemi ni ijọba oun ṣetan lati gbe opo ipinlẹ Ekiti ro gẹgẹ bi ipinlẹ to ni awọn to kawe julọ lorilẹ-ede Naijiria.
Lẹyin naa lo wa fi ipinnu rẹ lede lati ṣe afikun awọn ileewe to wa ni Ado Ekiti lati mu ki iwe kika rọrun fun awọn ọmọ ipinlẹ naa.












