Brighton vs Tottenham: Aṣọ́lé Tottenham, Hugo Lloris dèrò ilé ìwòsàn lẹ́yìn ìyà àjẹtúnjẹ lórí pápá Brighton

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Kaka ki ewe agbọn dẹ, niṣe lo n le koko sii. Kaka ko san fun ẹgbẹ agbabọọlu Tottenham, niṣe lo buru si o.
Ẹgbẹ agbabọọlu Brighton & Hove Albion lo ṣe Tottenham bi ọṣẹ tii ṣoju ninu ifẹsẹwọnsẹ idije Premier League lọjọ Abamẹta.
This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.
End of X post
Ami ayo mẹta ọtọọtọ ni wọn Brighton fi ṣagba Tottenham eleyi to jẹ iyanlẹnu fun ọpọlọpọ awọn ololufẹ ere bọọlu.
- Ó di agbábóòlù mẹta tí a ti pàdánù láàárín ọjọ meji - NFF
- Manchester United kò lèe ta pútú ní AZ Alkmaar
- Kiki Osinbajo gbóṣùbà fún Seyi Awolowo, MC Oluomo gbárùkù ti Mike ní BBNaija
- Àbọ̀ mi rèé láti orílẹ́èdè South Africa- Ààrẹ Muhammadu Buhari
- Tacha tọrọ àforíjí, ó da gbogbo ẹ̀bi lé ara rẹ̀ lórí
- Ọ̀pọ̀ èèyàn bẹnu ẹ̀tẹ́ lu Mercy Aigbe lórí bó ṣe ki Adeniyi Johnson
Balogun ati aṣọle ikọ Tottenham, Hugo Lloris lo kọkọ tasẹ agẹrẹ bi Tacha lo ba mu bọọlu bọ sinu awọn ara rẹ.
Laipẹ ni aṣọle fọwọ ṣeeṣe debi pe wọn ni lati gbe lọ sile iwosan lati ori papa.
Ṣugbọn bi iya nla ba gbeni sanlẹ, kekere a gori ẹni ni Brighton fi ṣe fun Tottenham lẹyin ti wọn fi ọba lee pẹlu goolu meji.
Lẹyin ọ rẹyin, Brighton ṣina iya fun Tottenham pẹlu ami ayo mẹta sodo lairo tẹlẹ.








