Europa league: Ìjàmbà tún ṣe Ole àtàwọn ọmọ rẹ níwájú AZ Alkmaar, ọ̀mì ni wọ́n ta

Agbabọọlu Man United ṣubu silẹ

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Kikankikan ni olukọ atawọn agbabọọlu ẹbẹ agbabọọlu Manchester n pariwo lori papa iṣire ti wọn ti gba ifẹsẹwọnsẹ wọn pẹlu AZ Alkmaar ninu ifẹsẹwọnsẹ idije Europa.

Ọmi ni Manchester United ta pẹlu AZ eleyi to mu ki Manchester United ṣi wa ni ipo keji ninu atẹ ipin L ninu idije naa ti Partizan belgrade si di ipo kini mu.

Manchester United ni lati pari ifẹsẹwọnsẹ naa pẹlu agbabọọẹu mẹwa dipo mọkanla nitori ọkan lara awọn agbabọọlu rẹ, Jesse Lingard to fara pa to si ni lati fi ori papa silẹ ṣaaju opin ifẹsẹwọnsẹ naa.

Pẹlu ifẹsẹwọnsẹ yii bayii, ami ayo mẹrin ni Manchester United ti ni ninu ifẹsẹwọnsẹ meji ti wọn ti gba.

FC Astana ni wọn ba pade ninu ifẹsẹwọnsẹ wọn akọkọ ti wọn si bori.