Issac Promise' Death: Àdánù ń lá ni ikú agbábóòlù mẹta jẹ fún wa - NFF

Oríṣun àwòrán, facebook
Ajọ ti o ri si ere boolu ni Naijiria ko dunnu rara si bi iku ojiji ti n pa awọn ọjẹ wẹwẹ agbaboolu lorilẹede yii.
Ninu ọrọ rẹ, akọwe agba fun ere boolu lorilẹede yii, Dokita Mohammed Sanusi banujẹ lori iku Issac Promise.
Issac Promise ni adari ojugba rẹ nigba idije awọn ọjẹwẹwẹ ti ọjọ ori wọn ko ju Ogun ọdun ati mẹtalelogun lọ.
Akọwe agba lẹka ere bọọlu naa ni pe aipẹ yii ni ọkọ ayọkẹlẹ kan pa meji lara awọn agbabọọlu fun Ọlọpaa meji.
Awọn meji naa ni wọn ku lairo tẹlẹ ni ilu Uyo, Olu Ilu Akwa Ibom ni ọjọ meji sẹyin, ki ti Issac Promise to tun ṣẹlẹ.
Mohammed Samuel ni ọsẹ ibanujẹ ni ọsẹ naa jẹ fun Ajọ naa.
O ṣapejuwe Isaac Promise gẹgẹ bi ẹni ti o ni iwa tutu ti o si mura siṣẹ.
O tẹsiwaju pe titi di asiko ti iroyin yii jade, wọn ko i tii mọ orisun iku rẹ.
O wa ni manigbagbe ni Promise yoo jẹ fun gbogbo eniyan.
Promise ni o jẹ adari ikọ ọmọ Naijiria ninu idije ti ọjẹwẹwẹ ilẹ Afrika ni ọdun 2005 ni Orilẹ ede Benin.
Bakan naa ni o tun kopa ninu ere idije ifese wọn sẹ ti FIFA ti ọjọ ori wọ ko ju Ogun kọ
Promise ni o tun je adari ninu idije ti awọn ọjẹwẹwẹ ti ọjọ ori wọn ko ju mẹtalelogun lọ ni Beijing 2008.
Ninu atẹjade ti ẹgbẹ agbaboolu rẹ Bold FC fi lede wọn ni Promise jade laye lẹyin ti o ti lo Ookanlelọgbọn lori eepẹ.













