Customṣ Service: Ọkọ̀ tòkunbọ̀, àpò ìrẹsì àt'ohun ìjà olóró lọwọ́ òfin ti tẹ̀

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Ileeṣẹ aṣọbode orilẹede Naijiria ni titi ti wọn ti awọn ibode orilẹede Naijiria pa ti n so eso rere.
Alukoro ileeṣẹ aṣọbode orilẹede Naijiria, Ọgbẹni Joseph Attah ni ko din ni ẹgbẹrun kan ati mejilelaadọrin ọkọ tokunbọ ti wọn ti ri gba lọwọ awọn onifayawọ.
- Ààrẹ gboriyin fún ọ̀gá àgbà tó fẹ́gbà sọkọ fun akẹ́kọ̀ọ́
- Lẹ́yìn ọ̀ rẹyìn, ilé ẹjọ́ gba oníduro Sowore pẹ̀lú ọgọ́rùn ún mílíọ̀nù náírà
- Ẹ ṣé mo dúpẹ́ fún àdúrótì àti ìfẹ tí ẹ ní sí mi - Toyin Abraham
- Ṣé ẹ mọ̀ pé olóògbé Ìjàpá tó kú lẹ́ni ọdún 344 yìí kò gba abẹ́rẹ́ rí?
- Ìjọba máa ní láti dá òsìsẹ́ dúró kí wọ́n tó lè san gbedéke owó osù tí ẹ fẹ́ - Ngige
O ni ọwọ tẹ awọn ọkọ naa nigba tawọn to ni wọn n gbiyanju ati gbe wọn gba oju opo ti ko bofinmu wọ orilẹede Naijiria.
Nibi eto ilanilọyẹ ti ileeṣẹ aṣọbode gbe kalẹ lori akanṣe eto titi ẹnu ibode Naijiria pa to n lọ lọwọ eyi to waye ni ilu Katsina ni alukoro ileeṣẹ naa ti sọ ọrọ yii.
Bakan naa lo tun fi kun un pe, ẹgbẹrun mọkandinlogun apo irẹsi ati garawa epo bẹntiroolu to din diẹ lẹgbẹrun marun ni wọn tun gba lasiko naa.
O ni pe ko tan sibẹ, awọn ohun ija oloro titi kan ajilẹ tawọn kan fẹ fi ṣe ado oloro lọwọ awọn agbofinro naa tun tẹ.










