Ààrẹ Magugujfuli ní ẹgba ti àwọn àkẹkọ̀ọ̀ to dána sun ilé jẹ ko ti tó

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Ààrẹ orilẹ̀-èdè Tanzania, John Magufuli tí gboriyìn fún ọgà àgbà lẹ́nu iṣẹ́ ìjọba kan tó fi ẹgba lu àwọn akẹ́kọ̀ọ́ kan ti wọ́n fẹ̀sun kan pé wọn lọ dána sún ilé igbé ilé ẹkọ.
Èyí wáye lẹ́yin ti fọ́nran kan lú sita to sì sàfìhàn bí kọmisọna ẹkun kan ṣe ń àtori dábira fún àwọn akẹ́kọ̀ọ́ tí wọ́n dána sun ositẹli wọ́n, èyi ti mínísita fún ijọba ibilẹ si bẹnu àtẹ lu ǹkan ti kọmisọna náà ṣe.
Ní báyìí à[rẹ òrílẹ̀-èdè náà ti gbé sàdánkata káre fún kọmisọna náà.
Ìròyìn sọ pé, ààrẹ Magufuli pé Albert Chalamila lori ààgo láti kí kare, àti pé ǹkan to dara lo ṣe fún àwọn ọmọ náà '' kóda o yẹ ki o lù wan jùbẹ́ẹ̀ lọ"
Bákan náà ni ààrẹ tún ke fun àtúnto òfin ilẹ̀ náà láti fún àwọn olùkọ to kù ni ànfani láti máà lú àkẹkọọ ko máà ṣe olori ilé iwé nìkan ni yóò ma ṣe bẹ́ẹ̀.
Kíní ofin Tanzania sọ nipa lílu ènìyàn?
Ofin Tanzania sọ pé olori ilé ikwe nìkàn lo ni ẹtọ láti na àkẹ́kọ̀ọ́, tí ko ba wa lé lùú, yóò tọka si olùkọọ míràn to ba wùú láti bá òun náa ọmọ náà.
O pọ́ jù kò gbọ̀dọ̀ ju pàsán mẹ́rin lọ, gẹ́gẹ́ bi ofin náà ṣe sọ, ẹṣẹ̀ to ṣe gbòógi bníkan ni wọ́n le tori rẹ̀ lu ọmọ sí, bóti lẹ̀ jẹ́ pé òfin náà kò sọ ǹkan ti ẹ̀ṣẹ̀ gbòógi jẹ́
Èyí jẹ́ ǹkan míràn ti à[rẹ fẹ́ ki wọ́n yí pada nínú òfin, Magujfuli nígbàgbọ́ pé kí ọmọde to jẹgba ko nilo láti ṣe ẹ̀ṣẹ̀ ńlalá

Oríṣun àwòrán, Clouds Digital
Kìí ṣe gbogbo eniyan lo faramọ lilo ẹgba
Ọkan nínú 2017 Human Rights Watch sọ pé ǹkan ti wan ń ṣe ni Tanzania ti wọ́n ba lú ọmọ kìí ṣe ìbáwi bíkò ṣe pe titẹ ofin loju mọ́lẹ̀ èyi ti ko si yẹ ko ri bẹ́ẹ̀
Àjọ to n moju to ẹtọ ọmọniyan yìí ni àkẹkọ̀ọ́ binrin kan sọ pé ǹkàn ti oju àwọn rí lọ́wọ́ àwọn olùkọ kìí ṣe kèrémi. Ọ̀pọ̀ àwọn akẹ́kọ̀ọ́ binrin ni àwọn sọ pé igi ni àwọn olùkọ maa n jan mọ àwọn lọmu, koda nigbamiran ti awọn ba n ṣe ǹkan osu lọ́wọ́ wọ́n o ni ki àwọn bẹ̀rẹ̀ jẹgba titi ti gbogbo ìtẹdi yóò fi bẹ tí ẹjẹ yòó si maa jò.















