Treason allegations: Sowore, àti akọ̀ròyìn mẹ́fà míì tí ìjọba Nàìjíríà ti fẹ̀sùn kàn rèé

Agba jalingo, Chris Anyanwu ati Omoyele Sowore

Oríṣun àwòrán, @others

Ni oṣu kẹjọ ọdun yii ni ajọ ọtẹlẹmuyẹ fi panpẹ ọba mu Omoyele Sowore, to jẹ oludasile ile iṣẹ iroyin Sahara Reporters, lori ẹsun to rọ mọ igbimọditẹ, ati pe o sọrọ abuku si Aarẹ Muhammadu Buhari.

Sugbọn kii ṣe Sowore nikan ni ijọba ti fi iru ẹsun bayii kan, ti wọn si ti dero atimọle latari ọrọ naa.

Ẹjẹ ka wo diẹ ninu wọn.

Anthony Eromosele Enahoro

Irawọ Oloye Anthony Enahoro tan lọdun 1944, nigba to di ọga akọroyin fun ileeṣẹ Nigerian Defender ni ọmọ ọdun mọkanlelogun, eleyi to mu ko jẹ ọga akoroyin to kere julọ ninu itan orilẹede Naijiria.

O mura si iṣe akọroyin to bẹẹ gẹ, ti wọn fi ran an lẹwọn ọdun marundinlogun lori ẹsun igbimọdite lọdun 1963, lẹyin ti wọn fi ẹsun ifipa gbajọba kan igbimọ ẹgbẹ oṣelu rẹ, Action Group.

Anthony Eromosele Enahoro

Oríṣun àwòrán, @HistoryVille

Ọpọ igba ni ijọba apapọ sọ Enahoro si atimọle lati ọdun 1945 lori oriṣiiriṣii ẹsun.

Enahoro papopda lọjọ kẹwa oṣu kejila ọdun 2010.

Kunle Ajibade

Ijọba ologun labẹ ọgagun oloogbe Sani Abacha lo fi ṣikun ọba mu Ajibade, to si fi ẹsun igbimọditẹ kan an.

Iṣẹlẹ yii lo waye lẹyin ti orukọ rẹ jade ninu atyẹjade kan ti iwe iroyin 'TheNews' gbe jade, ni ibi to ti jẹ ọga akọroyin.

Wọn fi ẹsun kan an pe o gbe iroyin jade, eleyi ti wọn ni o le di eto ipẹjọ awọn to fẹ ditẹgbajọbalọwọ lọwọ.

Ijọba tun ni Ajibade n ṣi awọn ara ilu lọna, eleyi ti wọn ni o mu ko jẹ ọkan lara awọn aditẹgbajọba lọjọ naa lọhun.

Ijiya ẹsun naa ni ẹwọn gbere.

George Mbah

George Mbah jẹ oṣisẹẹ ileeṣẹ akọroyin Tell.

Ni ọjọ karun un oṣun karun un ọdun 1995, lẹyin ọdun kan to kuro ni ile iwosan latari ijamba ọkọ ni wọn fi panpẹ ọba mu nilu Eko pẹlu awọn akọroyin miran.

Bi o tilẹ jẹ pe ko si idi kan pato ti wọn fi mu, yatọ si iditẹgbajọ ti awọn kan se si ijọba akoko naa.

Ijọba ran Mbah lẹwọn ọdun marundinlogun.

Àkọlé fídíò, Toll Gate: Ó ṣe pàtàkì kí ìjọba kọ́kọ́ tún ojú popo ṣe naa- Awakọ̀

Chris Anyanwu

Chris Anyanwu jẹ akọrin, ounkọwe, oloṣelu ati oṣiṣẹ ileeṣẹ The Sunday Magazine.

Anyanwu ṣẹwọn laarin ọdun 1995 si 1998 fun igbimọditẹ lẹyin to kọroyin nipa iditẹgbajọba to kuna ti wọn gbiyanju rẹ si ijọba Sani Abacha.

Ijọba ran lẹwọn gbere, sugbọn lẹyin akitiyan awọn eeyan ati awọn kan ẹgbẹ lorilẹ-ede agbaye, wọn din ẹwọn naa ku si ọdun marundinlogun.

Lẹyin iku ọgagun Sanni Abacha ni ijọba ọgagun Abdulsalam Abibabkar tu sile, latari ailera to n ba fira.

Ben Obi to jẹ oṣiṣẹ The Weekend Classic, Chris Anyawu ati Kunloe Ajibade ni ijọba ko ṣẹkẹṣẹkẹ si lọwọ nigba kan naa.

Omoyele Sowore

Omoyele Sowore

Oríṣun àwòrán, @Wailingvoice

Sowore jẹ gbajugbaja akọroyin ati oludije sipo aarẹ orilẹ-ede Naijiria labẹ asia ẹgbẹ African Action Congress lọdun 2019.

Ni ọjọ kẹrin oṣu kẹjọ ni ajọ ọtẹlẹmuye ko ṣẹkẹṣẹkẹ si lọwọ lori ẹsun igbimọditẹ ati pe o n gbimọ ifẹhonuhan tako ijọba.

Lẹyin akitiyan awọn agbẹjọro rẹ ni ile ẹjọ kan gba beeli rẹ pẹlu ọgọrun miliọnu naira.

Agba Jalingo

Jalingo ni oludasilẹ iwe iroyin Cross River Watch.

Lọwọ yii, Jalingo n jẹjọ ẹsun iṣẹrubalu, igbimọditẹ ati ẹsun pe o fẹ doju ijọba ipinlẹ Rivers bolẹ.

Bi o tilẹ jẹ pe o ni oun ko jẹbi ẹsun naa ti wọn fi kan, ile ejọ kọ lati jẹ ki awọn agbẹjọro rẹ gba beeli rẹ.

Ọpọlọpọ iwọde ni awọn ololufẹ rẹ ti ṣe latari pe wọn ni awọn agbofinro mu lọna ti ko ba ofin mu.

Àkọlé fídíò, Imam tó ṣí Mọ́ṣálásì fáwọn Krístẹ́nì sọ ìdí tí kò fi lè ta wọ́n nù