Yomi Fabiyi vs Iyabo Ojo: Mo mọ̀ pé Yomi Fabiyi ń ṣe e tẹ́lẹ̀, mo kan dákẹ́ ni torí kò borí mi - Mo Bimpe

Oríṣun àwòrán, MO_Bimpe, realyomifabiyi
Bi ọrọ ṣe n lọ lagbo awọn oṣere fiimu Yoruba lẹnu ọjọ mẹta yii ko rọgbọ rara bi wọn ṣe n gbiyanju ati pana kan ti omii n ru soke, o tun ti lọ mọ ọrun Yomi Fabiyi bayii bi Bimpe Oyebade ṣe tuu laṣiri.
Bimpe ṣapejuwe Yomi bii ọkunrin to maa n dunkoko mọni lori ọrọ ibalopọ ti oloyinbo n pe ni "Bully".
O n sọ eyi nigba ti oun naa fesi si fiimu Oko Iyabo ti Yomi ṣẹṣẹ gbe jade bo tilẹ jẹ pe o ni o ti pẹ ti oun ti n pa ọrọ rẹ ti amọ kii ṣe pe oun ko ri gbogbo ohun to n lọ.
Asiko ọrọ wa to naa ni Mo Bimpe ṣe tu ọrọ sita pe o ba oun lojiji bi Yomi ṣe sare gbe sinima yii jade. "Oju gba mi ti gidi gan, bawo ni eeyan kan lorilẹ aaye ṣe le ṣe iru eyi".

Oríṣun àwòrán, mo_bimpe
Nigba ti ọkan lara awọn ọrẹ rẹ loju opo Instagram pe e jade pẹlu ọrọ lati ran an leti asiko ti Yomi Fabiyi maa n fi ilọkulọ ibalopọ lọ ọ, o ṣalaye bi oṣere Yomi ṣe fẹrẹẹ yọ aye lẹmi rẹ pẹlu bibeere lati baa lopọ ni gbogbo igba to si tun ya to bẹrẹ si ni dẹru baa.
"Idi pataki ni pe mi o gbe ara mi silẹ fun ibalopọ to n gun un gara gara pẹlu bo ṣe gbiyanju to amọ ṣiṣe eyi si ọmọde ti pọ ju".
Mo Bimpe ni wọn ni lati da Yomi Fabiyi duro pẹlu iwa yii to dupẹ lọwọ Ọlrun fun oreọfẹ to fun oun pe "bi bẹẹ kọ mo ti maa pa ala didi ẹni nla ninu iṣẹ fiimu yii ti lati ọjọ pipẹ nitori bi Yomi ṣe n naa si mi ti ko jẹ ki n gbadun to si n fi ohun gbogbo dẹru ba mi".
Kii ṣe Bimpe nikan, Fabiyi ti n gba ọpọlọpọ oko ọrọ latọdọ awọn oṣere akẹgbẹ rẹ mii atawọn ọmọ Naijiria to kẹyin si ohun to ṣe si sinima Oko Iyabo to n da rugudu silẹ lọwọlọwọ.
Esi Yomi Fabiyi
Yomi Fabiyi ti fesi lori awuyewuye to n waye lati igba to ti gbe fiimu rẹ tuntun, Ọkọ Iyabọ jade.
Ninu fiimu naa, Fabiyi ṣe apẹẹrẹ Baba Ijesha pe Princess dẹ panpẹ fun nipa ọmọdebinrin ti wọn sọ pe o ni ibalopọ ti ko tọ pẹlu rẹ loju aye.
Bakan naa, orukọ awọn eeyan to ni nkan ṣe pẹlu iṣẹlẹ ẹsun ti wọn fi kan Baba Ijesha loju aye, naa ni Yomi Fabiyi fun gbogbo awọn to kopa ninu fiinmu rẹ ọhun, to fi mọ Iyabo Ojo, to jọ pe fiimu naa da le lori.
Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:
- Ìkọlù DSS sílé Sunday Igboho tàpá sófin, ìwà ìjọba ológun ni - Falana
- Wo ohun tó le gbégi dínà àbádòfin tó wógilé ṣíṣàfihàn afurasí ọ̀daràn l'Eko
- Ìdí tí mo fi pé àkọ́lé fíìmù mi ní "Oko Iyabo" ni pé orúkọ yẹn ṣeé kówó lé lórí lásìkò yìí - Yomi Fabiyi
- Ìgbeyàwó òṣèrébìnrin mìràn tún forí ṣánpọ́n
- Wo àwọn gbajúmọ̀, òṣèré tó lọ sí ibi ètò ìsìnkú Temitope Joshua
- Odíndi mọ̀lẹ́bí kan jẹ́ oníbalòpọ̀ abo sí abo, wo irú ìpólówó ọjà wọn tó dá wàhálà sílẹ̀
- Kò jọọ́, adájọ wọ́gilé gbígba onídùró Dibu Ojerinde lórí ẹ̀sùn àjẹbánu ₦5.2 bílíọ̀nù ní JAMB
Eyi si lo mu ki awọn ọmọ Naijiria kan fi ẹjọ fiimu naa sun lori ayelujara Youtube, ti awọn alaṣẹ ibẹ si fi yọ ọ kuro loju opo wọn.
Nkan to sẹlẹ yii lo mu ki Fabiyi lọ soju opo Instagram rẹ lati sọ pe oun ti sọ pe ki wọn o yọ fiimu naa kuro tabi ki wọn o fi pamọ.
O ni afojusun fiimu naa kii sẹ lati tabuku ẹnikẹni, bi ko ṣe lati polongo tako ilokulo ọmọde, titẹ ẹtọ ọmọniyan mọlẹ, ati awọn iwa miran ti ko tọ ọ lawujọ.
"Mo ti ni ki wọn o yọ ọ kuro tabi fi pamọ, ki alaafia le jọba.
Amọ ṣa, fiimu naa wà lati koro oju si ilokulo ọmọde, ifiyajẹni, titẹ ẹtọ ọmọniyan mọlẹ, ati awọn iwa buruku miran ni awujọ."
O ni oun tun fi fiimu naa ṣalaye pe oun kii ṣe iru eeyan ti wọn n pe oun.
"Ẹ ma tete ma a gba iroyin buruku gbọ. Eniyan ni emi naa, ṣugbọn, mi o ni fi ọwọ abuku mu ọrọ to ba kan awọn ọmọde."
Amọ, o tun ti kede fun awọn ololufẹ rẹ pe fiimu naa yoo pada sori ayelujara laipẹ.

Ìdí tí mo fi pé àkọ́lé fíìmù mi ní "Oko Iyabo" ni pé orúkọ yẹn ṣeé kówó lé lórí lásìkò yìí - Yomi Fabiyi
Oṣere fiimu Yoruba ti ṣalaye ohun to ri lọbẹ to fi waro ọwọ to gbe fiimu jade nipa igbe aye Iyabo Ojo to jẹ akẹgbẹ rẹ.
Ninu fidi kan to jade lori ayelujara ni Yomi Fabiyi ti sọ pe gbogbo awọn oṣere lawọn maa n mu iṣipaya lati ibikibi "ko si si ni to lee sọ pe ko si iṣipaya latara ọrọ to n ṣẹlẹ yii".
Tori naa Yomi ni oun ṣe adalu dapọ oriṣiriṣi iṣẹlẹ to jẹ ootọ ati eyi ti kii ṣe ootọ ni toun si sọọ di odidi.
"Pataki ibẹ ni pe iru agbejade yii yoo, kọ ni lẹkọ, yoo da ni lara ya yoo si tun ṣe imulkanle fun ẹni to n wo o. Awọn eeyan ni lati loye pe awa ni olugbelarugẹ iṣe awọn eniyan".
Yomi Fabiyi ni awn oṣere lawọn n gbe ohun to n ṣẹlẹ lawujọ sita. "Tálẹntì mi ló jáde tẹẹ fi ń pariwo o! Torí àwọn kan ti fojú wò mí bí ẹni ilẹ tẹlẹ ti ko lee pag to wa kọle alarinrin nipa ṣiṣe iru fiimu yii jade laarin asiko melo kan".
Bawo ni yomi ṣe ronuu lilo akọle "Oko Iyabo"
Yomi ni bo ṣe ṣẹlẹ ni wipe nigba ti ija ṣẹlẹ laarin awọn mejeji, awn eeyan bẹrẹ si ni pe oun ni ọkọ Iyabo iyẹn Iyabo Ojo to jẹ akẹgbẹ rẹ, oun wa wo o pe bi eeyan ba fẹ kọ sinima, o gbọdọ jẹ eyi to ṣee kowo le lori.
"Ṣe o ṣee kowo le lori, ṣe o ṣee pe lẹnu, ṣe o lóòrìn nínú. Eyi ni mo ro pe ẹ jẹ ka da awọn eeyan lara ya ka si kọ wọn lẹkọ, kii ṣe lati ba ti ẹnikẹni jẹ". o ni orukọ yn ti di eyi to ṣee fi ta ọja.
Yomi ṣalaye pe nkan ti awọn eeyan n ri lori ayelujara ko tilẹ ki n ṣe gbogbo sinima naa tori naa ki wọn duro ko jade na.
"Akẹgbẹ ni gbogbo wa. Bi ko ba tilẹ ni nkankan ṣe pẹlu rẹ, amọ tori asiko ti a wa yii, bi gbogbo Iyabo ba wo o, ara rẹ naa ni".

Oríṣun àwòrán, Yomi Fabiyi
Awọn òṣere to wa ninu Oko Iyabo
Yomi fabiyi ka awọn oṣere to wa ninu sinima Oko Iyabo latori awọn agba oṣere titi dori awọn to ṣẹṣẹ n wọ agbo oṣere.
"Adewale Elesho
Toyin Afolayan (Lola Idije)
Alapini
Dauda sulaimon
Yetunde Wumi
Olofa Ina
Hakeem Alimi
Yomi Fabiyi
Aishat Ajiloba to ko ipa Iyabo".
Yomi ni awọn n ṣiṣẹ takun takun lọsan loru lati mu ki sinima yii jade gẹgẹ bi eyi to ta lẹnu gidi.

Oríṣun àwòrán, Instagram
Ta ló yọ fíímù Yomi Fabiyi ''Oko Iyabo'' kúrò lójú Youtube, Instagram?
Oju opo ikansiraẹni Youtube ti yọ fiimu ti Yomi Fabiyi ṣẹṣẹ gbe jade to pe akọle rẹ ni ''Ọkọ Iyabo''.
Eyi ko ṣẹyin bi Ọpọlọpọ awọn ọmọ Naijiria ṣe faraya lori ayelujara pe fiimu naa farapẹ ọrọ oṣere tiata, Baba Ijesha ti wọn fẹsun kan pe o ṣe aṣemaṣe pẹlu ọmọde.
Wẹrẹ ti fiimu naa jade ni Yomi Fabiyi bẹrẹ si ni lọgun rẹ loju opo Instagram rẹ pẹlu ọpọlọpọ aworan ati fidio kekeke, amọ ti ko gba loju opo rẹ, amọ ti ko faye gba ''comment'' loju opo rẹ.
- Yomi Fabiyi, ìtíjú ńlá gbá à lo jẹ́ lórí fíímú ''Ọkọ ìyábọ̀'' tó gbé jáde - Mercy Aigbe
- Yomi Fabiyi wọ wàhálà ẹgbẹ́ TAMPAN torí fíìmù Ọkọ Iyabọ
- Yomi Fabiyi ṣe fíìmù lórí ọ̀rọ̀ Baba Ijesha, Iyabo ló dá lé lórí
- Ó di èèwọ̀ látí rán ọlọ́pàá, sójà, DSS wá sí ilẹ̀ Yoruba láì sọ̀ fún wa - Àpapọ̀ gómínà ní ilẹ̀ Yoruba
Eleyii lo mu ki awọn oluworan gbẹra lo si oju opo Youtube nibi ti fiimu naa wa ti wọn si bẹrẹ si ni sọ oku ọrọ nipa rẹ.
Ọpọlọpọ lo fi si oju opo naa pe ki wọn fi ẹsun kan fiimu naa ''report'' lori Youtube titi ti awọn alṣẹ yoo fi gbegile fiimu naa.
Ni aṣalẹ Ọjọ Aje ni a ri pe Youtube ti gbegile fiimu naa, ti ko si si loju opo wọn mọ.
Bakan naa ni Yomi Fabiyi yọ gbogbo aworan ati fidio to fi kede fiimu naa ni oju opo rẹ.

Oríṣun àwòrán, Realyomifabiyi/Instagram
Ninu ọrọ to kọ si oju opo rẹ, Yomi ni oun gbe igbeṣẹ lati fi fiimu naa pamọ nitori pe awọn eniyan ko naani idi ti oun fi gbe fiimu naa jade.
- Ibadan Gas tanker accident: Ọdọọdún la máa ń gbé igbá àgbo lọ́jà Bode àmọ́ àwọn kan kọ̀ lọ
- Àwọn daran-daran ní Nàìjíríà ní ẹgbẹ́ wọ́n sì ní olórí ṣùgbọ́n ẹ kọ̀ láti mú olórí wọn - Wole Soyinka
- "Ìpè iṣẹ́ ìránṣẹ́ TB Joshua ló mú mi bí ọmọ mi wẹ́rẹ́ lẹ́yìn ikú rẹ̀"
- Sunday Igboho ń dáró èèyàn kejì tí DSS pa nílé rẹ̀
- Ẹkùn Gúúsù Nàìjíríà ni ààrẹ gbọdọ̀ ti wá lọ́dún 2023 - Àwọn Gómìnà Gúúsù yarí
- 'Mo ti yọ'wọ́ lọ́rọ̀ òṣèlú Nàìjíríà, tẹ́ẹ bá ń gbọ́ pé Obasanjo dá ẹgbẹ́ òṣèlú sílẹ̀, "ẹyẹẹ̀ mi kọ́'
- Ẹ̀yin àgbà Yorùbá, ẹ lọ gba Sunday Igboho lọ́wọ́ ẹ̀sùn tíjọba fi kàn-án - YWG
- Sunday Igboho kò ṣẹ̀ s‘ófin, ẹ dẹ́kun ọ̀nà láti mu - Agbekoya
O ni idi rẹ ni lati la awọn eniyan lọyẹ lori ẹtọ ti wọn ni labẹ ofin, ati awn iwa aitọ ti awọn eniyan n hu lawujọ.
Amọ, ileẹjọ to n gbẹjọ ẹsun aṣemaṣe ti wọn fi kan Baba Ijesha ni ki ẹnikẹni ma sọrọ lori iṣẹlẹ naa lori ayelujara, ki wọn fi idajọ silẹ fun ileẹjọ.

















