Iyabo Ojo and Yomi Fabiyi: Yomi Fabiyi ṣe fíìmù lórí ọ̀rọ̀ Baba Ijesha, Iyabo ló dá lé lórí

Yomi Fabiyi, Lola Idije ati Elesho

Oríṣun àwòrán, Instagram/yomi fabiyi

Gbajugbaja osẹrekunrin, Yomi Fabiyi gbe sinima kan jade nipa ọrọ Baba Ijesha, 'Ọkọ Iyabo' lo pe e.

Lara nkan ti a ṣe akiyesi ni pe lati asiko ti ede aiyede to waye laarin oun ati Iyabo Ojo, lo ti n polongo sinma naa lori ayelujara Instagram rẹ.

Ṣugbọn, ere ni, awada ni, a fi bo ṣe sọ di ootọ.

Ninu awọn fidio kekeeke to fi sita ninu sinma naa, eyi ti BBC Yoruba wo, lati ṣe akiyesi awọn nkankan to fi jọ pe o ṣe e ṣe ko jẹ Iyabo Ojo lo fi sinma naa ba wi.

Nkan akọkọ ni pe Iyabo ni orukọ ọmọbinrin to jẹ oṣere ti sinima naa da le lori.

Botilẹ jẹ pe ọmọbinrin naa sọ nigba to wa ni kekere pe iṣẹ aṣẹwo ni oun yoo sẹ ti oun ba dagba, iṣẹ oṣere Yoruba lo pada ṣe.

A tun ṣakiyesi pe Yomi Fabiyi lo awọn fidio kan to ni i ṣe pẹlu awọn nkan to sẹlẹ lasiko ti Baba Ijesha fi wa ni atimọle ọlọpaa nitori ẹsun ifipabanilopọ.

Lara awọn fidio naa ni fidio to ṣe lọjọ to sẹ iwọde lọ si ileeṣẹ ọlọpaa to n wadii ẹsun ọdaran ni Panti, Yaba ni Eko.

O tun lo fidio ibi ti agba osẹre, Ọlọfa Ina ti sọ pe oun pe Iyabo nitori ọrọ Baba Ijesha, amọ o ni ki oun 'gbẹnu sọun'.

Àkọlé fídíò, Tunbosun Odunsin: Ẹlẹ́dàá ló fún mi ní tálẹǹtì ẹ̀kún sísun ní ìrọ̀rùn nínú eré tíátà

Bakan naa, ninu ikan lara awọn fidio naa, o ṣe afihan awọn ọmọbinrin kan to n ṣe iwọde pe wọn ko gbọdọ tu afurasi ọdaran kan to fi ipa ba eeyan ni ibalopọ silẹ.

Lanre ni orukọ afurasi ọdaran naa, Lanre naa si ni orukọ abisọ Baba Ijesha.

Ninu sinima ọhun ẹwẹ, Iyabo jẹ ọmọ ti ko gba ẹkọ ile

Awọn osẹre to kopa nibẹ ni Adekola Tijani (Kamilu Kompo), Ọgbẹni Aderemi (Olofa Ina), Yomi Fabiyi, Toyin Afolayan (Lola Idije), Akeem Alime (Ajala Jalingo), Taiwo Hassan (Ogogo), Adewale Elesho, Yetunde Wumi (Wumi), Rammy Shitta Bay, ati awọn mii.