Chrisland School Video: Bí o ṣe lè mọ àwọn ǹkan tí ọmọ rẹ ń wò ní orí fóònù rẹ̀ rèé

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Lati ọsẹ to kọja ti iroyin ti jade si ori ẹrọ ayelujara bi fidio ṣe ṣafihan awọn ọmọ ileẹkọ Chrisland ti wọn n ba ara wọn ni ajọṣepọ, ni awọn eniyan ti n fi ero wọn han lori nkan ti eniyan le ṣe lati da abo bo ọmọ rẹ lori ẹrọ ayelujara.
Ileeṣẹ iroyin BBC Pidgin ba awọn onimọ sọrọ lori bi awọn obi ṣe le mọ awọn nkan ti ọmọ wọn n ṣe lori foonu rẹ ati bi wọn ṣe le wa ni ailewu lori ayelujara.
Onimọ Taiwo Ogunlade to jẹ agbẹnusọ fun ileeṣẹ ẹrọ ayelujara ''Google'' ni awọn ti ṣe agbekalẹ oju ẹrọ ''app'' ti yoo sọ ẹrọ awọn mọlẹbi pọ, ki awọn obi le mọ nkan ti awọn ọmọ wọn n ṣe lori ẹrọ ayelujara.
- Mo tọrọ àforíjì lórí fídíò tí mo gbé jáde, tó ń mú àwọn èèyàn pè mí - Bukunmi Oluwashina
- Ṣé lóòtọ́ ni pé mo leè jẹ́ ''virgin" kí ẹ̀jẹ̀ má sì yọ lálẹ́ ọjọ́ ìgbéyàwó? - Ìwádìí fìhàn
- Ọ̀gá Àgbà Ọlọ́pàá sọ ìgbà tí wọ́n ó gbé ọkọ akọrin Osinachi tó dolóògbé lọ sí iléẹjọ́
- Ọ̀nà àti yọ ọwọ́ àwọn ọ̀dọ́ àti obìnrin kúrò láwo òṣèlú ni owó fọ́ọ̀mù #100m tí APC kéde - CISLAC
- Ṣé lóòtọ́ ni àwọn òṣìṣẹ́ LASTMA ń lọ́ àwọn awakọ̀ lọ́wọ́ gbà l'Eko? Àwọn èèyàn jáde fi ẹ̀hónú hàn
- 'Ó dá mi lójú pé kò ní sí ìdìbò sípò gómìnà ní Osun, Ekiti láíláí ní ọdun 2022!'
Ti awọn obi ba ti so foonu naa papọ, wọn le gbegile awọn oju opo ti wọn ko ba fẹ ki ọmọ wọn wo. Eleyii yoo jẹ ki wọn mọ nkan ti ọmọ wọn n wo lori ẹrọ ayelujara.
Ileeṣẹ Google naa ni o le lo oju opo yii lati fi gbegile awọn oju opo to n safihan ibalọpọ laarin awọn eniyan .

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Bakan naa ni awọn obi le ẹrọ ''app'' yii lati fi pa foonu ọmọ wọn ti asiko ba ti to lati fi foonu silẹ.
Bi o ṣe le so foonu ọmọ rẹ pọ mọ ti ara rẹ niyii...
- Ṣi oju opo ''Gmail'' fun ọmọ rẹ pelu ọjọ ori re gangan
- Gba ẹrọ ''Google Family Link'' fun foonu awọn obi
- Fi orukọ ọmọ rẹ si ''Google Family link'' naa
- Ṣi oju opo naa lori foonu ọmọ rẹ, ki o si jẹ ki o maa ṣiṣẹ.
Lẹyin eyi ọmọ rẹ yoo le lo foonu rẹ amọ ko ni le e wọ awọn ibi ti wọn ti n ṣe iṣekuṣe.
Fun ẹrọ ayelujara bii kọmputa, oun ti awọn obi le e ṣe ni yii
- Ki wọn fi ẹrọ kọmputa naa si ibi ti oju gbogbo ti le to
- Tẹju mọ wọn ti wọn ba n wa nkan lori ẹrọ ayelujara, ẹ ma jẹ ki wọn danikan lo foonu naa tabi ẹrọ kọmputa wọn.
- Gbegile awọn oju opo ti o ko ba fẹ ki wọn wọ, nitori gbogbo oju opo loni aye lati gbegidi eyi ti ko ba fẹ.
- Fi password si kọmputa ki o si silẹ fuin wọn.
- Jẹ ko jẹ ọkunkundun ni ookan aya rẹ lati ma a ba awọn ọmọ rẹ sọrọ laipẹ, ki o si mọ ẹni ti wọn n ba sọrọ lori ẹrọ ayelujara.
Bi o ṣe le ṣe amojuto foonu awọn ọmọ rẹ ni yii...
Onimọ nipa awọn ọmọde, Dr Maymunah Kadiri ti sọ bi awọn obi ṣe le ṣamojuto ọmọ wọn ati ẹrọ ilewọ wọn lori ẹrọ ayelujara.
Maymunah to tun jẹ onimọ nipa ihuwasi eniyan ati ọrọ ọpọlọ ni ti awọn obi ba ti fi ''family link'' si tan ni ki wọn ma a gba ''notification'' nkan to ba n ṣẹlẹ lori foonu wọn.
- Ẹ fi ''child protection'' si ẹrọ tẹlifiṣọn yin, eyi ko ni jẹ ki wọn lo oju opo ti ko dara, to fi mọ lori Netflix ati Youtube
- Wo bi wọn se n lo data ati WIFI si
- Awọn ileẹkọ gbọdọ ma a wo ẹrọ ilewọ ti awọn ọmọ ba mu wa si ileẹkọ paapaa awọn to n gbe ninu ileẹkọ wọn.
- Lo ẹrọ ''whatsapp web'' lati wo awọn ti wọn n ba sọrọ ati iru ọrẹ ti wọn ni.
Ọmọ gbọdọ pe ọdun mẹtala ki wọn to fun un ni foonu
Dr Maymunah ti ni asiko to tọ lati fun ọmọ ni ẹrọ ilewọ ni ki ọmọ pe ẹni ọdun mẹtala

Oríṣun àwòrán, Getty Images
O ni awọn oju opo lori ayelujara kii gba ki awọn ọmọ wọ awọn ibi kan lori ẹrọ ayelujara, ti wọn ko ba tii pe ẹni ọdun mẹtala.
''Coronavirus lo fa a ti awọn ọmọ tun bẹrẹ si ni lo foonu lati fi kawe, amọ awọn obi gbọdọ ma a ṣe akiyesi nkan ti wọn n ṣe ni orekoore.
Bakan naa lo rọ awọn ileeṣẹ onimọ ẹrọ lati ṣiṣẹ pọ pẹlu awọn ileẹkọ lati le ma a wo kọrọ ikọkọ awọn foonu awọn ọmọ wọn.
















