LASTMA in Lagos: Awakọ̀ ṣekúpa òṣìṣẹ́ LASTMA

Oríṣun àwòrán, @followlastma
Awakọ̀ kan tí wọn kò tíì mọ orúkọ rẹ̀ báyìí ti rán òṣìṣẹ́ àjọ tó ń mójútó lílọ àti bíbọ̀ ọkọ̀ ní ìpínlẹ̀ Eko, LASTMA lọ sọ́run àrèmabọ̀.
Òṣìṣẹ́ LASTMA náà tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Jamiu Issa ni awakọ̀ fi ọkọ̀ gbá tí ẹ̀mí sì bọ́ lára rẹ̀ ni agbègbè Lekki sí Ajah ni ọjọ́rú, ogúnjọ́, oṣù kẹrin, ọdún 2022.
Àtẹ̀jáde kan látọwọ́ Agbẹnusọ LASTMA, Olumide Filade ní awakọ̀ náà ló gba ọ̀nà tí kìí se tirẹ̀ nígbà tó kó sọ́wọ́ Issa tó fẹ́ mu fún títẹ òfin lójú mọ́lẹ̀.
- Ẹ̀yà Igbo ni ipò Ààrẹ kàn, tá a ba fẹ́ àlàáfíà àti àìṣègbè - Adebanjo
- "100m tí APC ń bèrè fún owó fọ́ọ̀mù kò ní jẹ́ kí àwọn tó nífẹ́ aráàlù dé ipò ìjọba"
- Rádaràda lẹ̀yin olórin ẹ̀mí tẹ́ẹ̀ ń ṣí ara sílẹ̀, tún kó elégbè mẹ́rin kó máa túmọ̀ ọ̀rọ̀ onílù - Senwele Jesu
- Wo iye tó san to bá fẹ́ lọ sí Hajj ọdún yìí
- Mo tọrọ àforíjì lórí fídíò tí mo gbé jáde, tó ń mú àwọn èèyàn pè mí - Bukunmi Oluwashina
- Wo bí o ṣe lè so fóònù rẹ pọ̀ mọ́ àwọn ǹkan tí ọmọ rẹ ń wò lórí fóònù rẹ̀
- Ṣé lóòtọ́ ni pé mo leè jẹ́ ''virgin" kí ẹ̀jẹ̀ má sì yọ lálẹ́ ọjọ́ ìgbéyàwó? - Ìwádìí fìhàn
- Ọ̀gá Àgbà Ọlọ́pàá sọ ìgbà tí wọ́n ó gbé ọkọ akọrin Osinachi tó dolóògbé lọ sí iléẹjọ́
- Ọ̀nà àti yọ ọwọ́ àwọn ọ̀dọ́ àti obìnrin kúrò láwo òṣèlú ni owó fọ́ọ̀mù #100m tí APC kéde - CISLAC
Filade ṣàlàyé wí pé nítorí kí Issa má mù ún awakọ̀ náà ló ṣe fi ọkọ̀ gba dànù tí onítọ̀hún sì ṣe kòńgẹ́ ọlọ́jọ́ rẹ̀.
Ó fi kun wí pé ìgbà tí wọ́n máa fi gbé Issa de ile ìwòsàn, kò bá mọ́.
Àwọn tí ọ̀rọ̀ náà ṣojú wọn sọ wí pé yàtọ̀ sí Issa, awakọ̀ náà tún kọlù ẹlòmíràn níbi tó ti ń sá lọ ṣùgbọ́n tí ọwọ́ àwọn ènìyàn padà tẹ̀ ẹ́ ní agbègbè Chevron tí wọ́n sì ti fà á lé àwọn Ọlọ́pàá lọ́wọ́
Filade tún fi kun wí pé ọ̀gá àgbà àjọ náà, Bolaji Oreagba tí bá àwọn ẹbí olóògbé náà kẹ́dùn tó sì ṣèlérí wí pé awakọ̀ náà yóò fojú winá òfin.
Ki lo ti ṣẹlẹ sẹyin?
Ṣé lóòtọ́ ni àwọn òṣìṣẹ́ LASTMA ń lọ́ àwọn awakọ̀ lọ́wọ́ gbà l'Eko? Àwọn èèyàn jáde fi ẹ̀hónú hàn

Oríṣun àwòrán, Temilola Kofoworola Sobola
Àwọn awakọ̀ tó ń lo afárá Dopemu ní agbègbè Agege, ìpínlẹ̀ Eko ti fẹ̀sùn kan àwọn òṣìṣẹ́ àjọ tó ń mójútó lílọ àti bíbọ̀ ọkọ̀ ní ìpínlẹ̀ Eko LASTMA tó wà ní agbègbè náà wí pé ní ṣe ni wọ́n máa ń lọ́ àwọn lọ́wọ́ gbà.
Afárá náà ló so Dopemu, Iyana Ipaja àti Ikeja mọ́ ara wọn.
Ní ọwọ́ àárọ̀ kùtùkùtù, ànfàní wà fún àwọn ọlọ́kọ̀ tó ń lọ sí Dopemu láti gba orí Afárá náà ṣùgbọ́n aago mẹta ọ̀sán ni ànfàní yìí mọ.
Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé àmì ńlá wà ní ojú ọ̀nà náà wí pé kò sí àyè fún àwọn tó ń lọ Dopemu ní àkókò náà, àwọn awakọ̀ tó ń lọ sí Akowonjo máa ń gba orí Afárá yìí lásìkò tí súnkẹrẹ fàkẹrẹ bá ti pọ̀ ní ọwọ́ ìrọ̀lẹ́.
Ẹ̀wẹ̀, àwọn ènìyàn ti ń kọminú lórí ojú òpó Facebook wí pé àwọn òṣìṣẹ́ LASTMA máa ń mọ̀-ọ́n-mọ̀ lọ àwọn ènìyàn lọ́wọ́ gbà ní agbègbè pàápàá àwọn tí kò bá mọ ojú ọ̀nà náà dáadáa.
Stephen Legal ní kàkà kí àwọn òṣìṣẹ́ LASTMA dúró ní ẹnu ọ̀nà Afárá náà láti máa darí àwọn ọkọ̀ gba ibi tó yẹ láti ago mẹ́ta ọ̀sán, ó ní ní ìparí Afárá ọ̀hún ni wọn yóò lọ lúgọ sí láti mú ẹni tó bá rú òfin náà.
Legal ní ìwà ìkà àti ọgbọ́n jìbìtì ni kí àwọn òṣìṣẹ́ LASTMA lọ sápamọ́ sí ibì kan kí wọ́n máa retí ẹni tí wọn yóò mú láti gba owó geege lọ́wọ́ rẹ̀.
Ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn mìíràn náà tó ń jẹ́rìí sí ọ̀rọ̀ náà ní ìwà àwọn LASTMA náà kò ṣẹ̀ṣẹ̀ bẹ̀rẹ̀, wí pé tipẹ́ ló ti ń wáyé tí ìjọba kò sì wá ojútùú sí ọ̀rọ̀ náà.
Israel Balogun ní tirẹ̀ ní láti bí ọdún méjì ni òun, LASTMA àti àwọn Ọlọ́pàá máa ń jà nítorí ìrẹ́nijẹ tó máa ń fi gbogbo ìgbà wáyé ní agbègbè náà.
Ó ní "báwo ni ènìyàn ṣe ma mọ̀ wí pé ọna tí òun gbà kọjá ní àárọ̀ ti di èèwọ̀ fún òun láìsí ẹni tí yóò sọ fún un, mo ṣetán láti kún gbogbo àwọn tó bá fẹ́ ja ìjà yìí títí ìjọba yóò fi ṣe ohun tó yẹ lórí Afárá náà."
Bákan náà ni ẹlòmíràn, Ayoade Sikiru fẹ̀sùn kan àjọ task force wí pé bẹ́ẹ̀ náà ni àwọn náà ń ṣe lójú òpópónà náà, tó ṣe wí pé tí wọ́n bá mú ènìyàn, kò ní dín ní ẹgbẹ̀rún lọ́nà ọgbọ̀n sí àádọ́ta náírà tí ẹni náà yóò fi gbára.
Iléeṣẹ́ ìwé ìròyìn Punch ní àbẹ̀wò àwọn òṣìṣẹ́ àwọn fìdí gbogbo ohun tí àwọn ènìyàn náà sọ múlẹ̀.
Agbẹnusọ Iléeṣẹ́ Ọlọ́pàá Ìpínlẹ̀ Èkó, Benjamin Hundeyin wá rọ àwọn awakọ̀ láti fi ẹjọ́ àwọn òṣìṣẹ́ tó bá ń gbowó kò tọ́ sùn ní àgọ́ Ọlọ́pàá nítorí kọmíṣọ́nà Ọlọ́pàá ìpínlẹ̀ korò ojú sì gbígba àbẹ̀tẹ́lẹ̀.
















