London Bicycle ride to Lagos: Ọmọ Naijiria kan ti bẹ̀rẹ̀ ìrìnàjò láti London wá sí Naijiria pẹ̀lú kẹ̀kẹ̀

Oríṣun àwòrán, @lionheart1759
Adeyanju ni nitori ati pa owo jọ fun itọrẹaanu awọn alaini ni oun ṣe gbe igbesẹ naa.
Irinajo lati ilu Ọba wa si ilu Eko yoo gba arakunrin naa ni ọjọ marundinlọ̣gbọn.
Bakan naa ni yoo gba orilẹede Faranse, Spain, Gibraltae, Morocco, Iwọ oorun agbegbe Sahara, Mauritana,Senegal, Gambia, Mali, Ivory Coast, Ghana, Togo ati Benin ki wọn to wa kọja si Naijiria.
- 'Ó dá mi lójú pé kò ní sí ìdìbò sípò gómìnà ní Osun, Ekiti láíláí ní ọdun 2022!'
- Òṣìṣẹ́ ìjọba gba àṣẹ lọ rọọ́kún nílé nítorí ìròyìn òfégè ìkú nípa Gómìnà Akeredolu
- Oluwo, tètè yípadà nídìí títàbùkù Yorùbá tori ewe ń bẹ̀, òògùn wà
- Wo ìjìyà tó wà fún pínpín fọ́rán ìbálòpọ̀ ọmọdé lórí ayélujára
- Ọ̀rọ̀ Ayo Adebanjo pé kí Tinubu, Osinbajo yọwọ́ ní dídu ipò ààrẹ, ṣé gbogbo ẹgbẹ́ Afenifere lọ́wọ́ síi báyìí?
- Irọ́ tó jìnà sí òótọ́ ni gbogbo ẹ̀sùn rẹ Oluwo - Ohanaeze Ndigbo fèsì
- Bíb'ojú àánú wo àwọn gómìnà tó sẹ̀wọ̀n-ọ́n lòdì sí gbígbógun tí ìwà àjẹbánu - Soyinka sí Buhari
- Àwọn ọ̀dọ́ ló leè gba Naijiria là kúrò ní oko ẹrú –Imam Akeugbagold
Adeyanju ni owo naa ti oun ba ri tujọ lasiko irinajo oun naa ni yoo lo lati ṣe iranwọ fun ẹka ilera, ipese omi ati ayika mimọ toni toni.
This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.
End of X post
''Ni oni Ọjọ kọkandinlogun ni mo bẹrẹ irinajo lọ si ilu Eko lati ilu Ọba''
''Ọjọ marundinlọgbọn ni o ṣeeṣe ki n lọ lati fi rin irinajo naa to le ni ẹgberun kilomita ẹgbẹrun lọna mejila.''
Lara awọn ololufẹ rẹ to kii fun iwa akinkanju loju opo Twitter naa ni awọn n gbero lati ṣe iru rẹ.
Wọn wa gbadura fun un lati rin irinajo naa laisi ewu abi ijamba ni gbogbo ibi ti o ba n de.Arakunrin ọmọ Naijiria, Kunle Adeyanju ti bẹrẹ igbesẹ lati rin irinajo pẹlu ọkada rẹ lati ilu Ọba wa si ilu Eko.















