Akeugbagold on 2023 Election: Akeugbagold sọ ìdí tó fi ní àwọn ọ̀dọ́ ni ọ̀nà àbáyọ sí ìṣòro Naijiria

Oríṣun àwòrán, Àyìnlá Àyàn
Alaga Ajọ awọn Musulumi ni ipinlẹ Oyo, Sheik Taofeek Akeugberu Akeugbagold ti ni awọn ọdọ lo le e yọ Naijiria kuro ninu iṣoro ti ohun la kọja.
Onimọ nipa ẹsin Islam naa, Akeugbagold sọ eyi ni ilu Ibadan lasiko ijiroro lasiko awẹ Ramadan.
Orilẹede Naijiria n koju awọn idojukọ ni ẹka eto oṣelu, iya ati iṣẹ to fi mọ airilegbe, airiṣẹ ati igbesunmọmi kaakiri orilẹede Naijiria.
- Iṣẹ́ ilé kíkọ́ bẹ̀rẹ̀ lórí ilẹ̀ Dejo Tunfulu lẹ́yìn tó jáde láyé
- kìí ṣe ẹ̀bi wa wí pé àwọn akẹ́kọ̀ọ́ ṣe àṣemáṣe - ile ẹ̀kọ́ Chrisland
- Bí mo ṣe rí iṣẹ́ ní UK rèé lẹ́yìn ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìgbìyànjú - Ọmọ Naijiria sọ ìrírí rẹ̀
- Ǹkan tí a mọ̀ rèé nípa ẹ̀sùn ìbálòpọ̀ tó wáyé láàárín àwọn akẹ́kọ̀ọ́ Chrisland
- Mo ti tọrọ aṣọ àti yẹrín etí rí, kí n tó leè ṣe àwo orin - Tope Alabi
- Ọlọ́run ló sọ fún mi kí n lọ dupò ààrẹ Naijiria ní 2023, ohun tó sọ fún mi rèé - Ìmàámù Afeez Akinola
- Nítorí orin 'Angeli mi' ti Tope Alabi kọ, iléeṣẹ́ MTN, Glo àti Airtel dèrò ilé ẹjọ́
Akeugbagold ni orilẹede ki orilẹede ti ko ba gba awọn ọdọ laaye ninu ọrọ oṣelu wọn ko le e kẹsẹjari.
Imaamu naa wa rọ awọn ọmọ Naijiria lati dibo yan ọdọ gẹgẹ bi adari wọn nitori wọn ni ọpọlọ pipe ti wọn le koju awọn iṣoro ti Naijiria n la kọja.
Kí ló wú ọ̀rọ̀ yìí jáde?
Ninu akọle ọrọ rẹ to pe ni ''2023 Election and Youth Participation for National Development'' ni awọn ọdọ gbọdọ dide kuro ninu oorun wọn ki wọn si gbe apoti idibo ni ọdun 2023.
Bakan naa lo rọ awọn ọmọ Naijiria lati yan awọn adari to dantọ lai fi ti ọrọ ẹsin tabi ẹlẹyamẹya wọ ọ.
''Mo ni igbagbọ pe awọn ọdọ nikan lo lee gba orilẹede Naijiria la, ti wọn si le e mu gun oke agba.
''Nigba ti a ba n sọrọ nipa orilẹede to nilo ati ni ilọsiwaju, a nilo a ti mu ọrọ ẹsin kuro nibẹ.
''Ni awọn orilẹede bi Ghana, China, awọn ọdọ bii Jerry Rawlings lo gba ilẹ wọn la kuro ni oko ẹru.''
''O ṣeni laanu pe awọn ile ijọsin n ko owo jọ to le ni biliọnu biliọnu lai san owo ori, nitori naa awọn ọdọ ni lati gbaradi fun iṣẹ.''
''Ti o ba wọ Ilẹ Gẹẹsi ni oni, awọn ileeṣẹ nla nla ni eniyan a ma a ri to fi mọ ni orilẹede China.''
'' Amọ ti a ba de Naijiria paapaa ni ilu Eko ati Ibadan, awọn ile ijọsin ati mọṣalasi ni o kun gbogbo ẹba ọna kaakiri.''
Akeugbagold fikun pe ọrọ Naijiria ṣe ni laanu nitori kaka ki awọn eniyan ma a da ileeṣẹ nlanla silẹ, ile ijọsin nlanla ni wọn n da silẹ kaakiri.
















