Dejo Tunfulu: Àwọn òṣèré tíátà bẹ̀rẹ̀ kíkọ́ ilé sórí ilẹ̀ gbajúgbajà adẹ́rìnínpòṣónú tó papò dà

Oríṣun àwòrán, dejo Tunfulu/laideolabanji
Yorùbá ní dídùn dídùn báyìí ni ìrántí olódodo.
Àwọn òṣèré tíátà ti bẹ̀rẹ̀ sí ní kọ ilé sí orí ilẹ̀ gbajúgbajà òṣèré adẹ́rìnínpòṣónú, Adekunle Adetokunbo tí ọ̀pọ̀lọpọ̀ mọ̀ sí Dejo Tunfulu tó di olóògbé láìpẹ́ yìí.
Ní ọjọ́ kìíní, oṣù kẹrin, ọdún 2022 ni Dejo Tunfulu dágbére fáyé lẹ́ni àádọ́ta ọdún lẹ́yìn àìsàn ráńpẹ́.
- A máa ń lọ yọjú wo Yinka Quadri tó bá ń ṣe fíìmù ládùúgbò wa - Ẹ wo bí Dejo Tunfulu ṣe bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ Tíátà
- Ikú Dejo Tunfulu ti kó ìrẹ̀wẹ̀sí ọkàn bá mi, ń kò le kópa nínú eré tà ń yà mọ́ - Ọ̀gá Bello
- Wo gbajúmọ̀ aláwàdà Yorùbá méjọ tó ti kú saájú Dejo Tunfulu
- Àlàyé rèé lórí aìsàn tó pa Dejo Tunfulu àti ilé ìwòsàn tó dákẹ́ sí
- Wèrè ọlọ́mọ ní Dejo Tunfulu, ọmọ mẹ́rin ní ìyá wa dà sílẹ̀ fún, tó sì bá ọkọ míì lọ - Ọmọ olóògbé
- kìí ṣe ẹ̀bi wa wí pé àwọn akẹ́kọ̀ọ́ ṣe àṣemáṣe - ile ẹ̀kọ́ Chrisland
- Bí mo ṣe rí iṣẹ́ ní UK rèé lẹ́yìn ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìgbìyànjú - Ọmọ Naijiria sọ ìrírí rẹ̀
- Ǹkan tí a mọ̀ rèé nípa ẹ̀sùn ìbálòpọ̀ tó wáyé láàárín àwọn akẹ́kọ̀ọ́ Chrisland
- Mo ti tọrọ aṣọ àti yẹrín etí rí, kí n tó leè ṣe àwo orin - Tope Alabi
Ní orí ilẹ̀ olóògbé náà ni wọ́n sin-ín sí ní ìlànà ẹ̀sìn Islam.
Gbajúgbajà òṣèré kan, Olaide Olabanji ti wá fi fọ́nrán kan léde báyìí léyìí tó ń ṣe àfihàn orí ilẹ̀ olóògbé níbi tí wọ́n sin Dejo Tunfulu sí.
Ní orí ayélujára Instagram Olaide Olabanji ni ó fi fọ́nrán fídíò tó ṣàfihàn pé iṣẹ́ ilé kíkọ́ náà tí bẹ̀rẹ̀ sí.
Ohun tí Olabanji kọ sí abẹ́ fọ́nrán náà ni wí pé "iṣẹ́ dáadáa ṣì ń tẹ̀síwájú, lónìí ní orí ilẹ̀ Dejo Tunfulu, iṣẹ́ ti bẹ̀rẹ̀, kí Ọlọ́run tẹ sí afẹ́fẹ́ rere."
This article contains content provided by Instagram. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read Instagram cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.
End of Instagram post
Ohun tí a rí nínú fídíò náà ni wí pé iṣẹ́ ilé kíkọ́ ti bẹ̀rẹ̀ níbẹ̀ tí ìròyìn náà sì ti ń fa kí àwọn olólùfẹ́ olóògbé Dejo Tunfulu máa kan ṣáá sí àwọn tó dìde ìrànwọ́ náà.
Lẹ́yìn tí Dejo Tunfulu jáde láyé tí àwọn ènìyàn sì gbọ́ wí pé gbajúgbajà òṣèré adẹ́rìnínpòṣónú náà kò ní ilé ti ara rẹ̀ wí pé ó ń yá ilé gbé ni àwọn ènìyàn ti ń kùn wí pé pẹ̀lú gbogbo bí ó ṣe fara ṣiṣẹ́ nídìí tíátà tó, kò yẹ kó jẹ́ pé irú Dejo Tunfulu ni kò ní nílé lórí.
Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ó ní ilẹ̀ tó ti rà kalẹ̀ ní orúkọ ara rẹ̀ kí ọlọ́jọ́ tó dé.
Àwọn olólùfẹ́ Dejo Tunfulu fi ìdùnnú hàn sí bí ilé kíkọ́ ṣe bẹ̀rẹ̀ lórí ilẹ̀ rẹ̀
Àwọn olólùfẹ́ gbajúgbajà òṣèré adẹ́rìnínpòṣónú, Dejo Tunfulu ti bẹ̀rẹ̀ sí ní fi ìdùnnú wọn hàn lórí Fọ́nrán tí Olabanji fi léde.
Ọ̀pọ̀lọpọ̀ wọn ló ń sọ̀rọ̀ ìwúrí tí wọ́n sì ń fi àdúrà ránṣẹ́ sì àwọn tó wà nídìí ilé kíkọ́ náà.
Bákan náà ni wọ́n gbàdúrà pé kí Ọlọ́run fún wọn ní oore ọ̀fẹ́ láti parí iṣẹ́ rere tí wọ́n bẹ̀rẹ̀ ọ̀hún.















