Late Yoruba Nollywood Comedians: Moladun, Lukuluku, Alaran, àti àwọn gbajúmọ̀ aláwàdà mìí tó ti kú

Alaran, Omoladun, Baba Suwe ati Lukuluku

Oríṣun àwòrán, others

Lara ẹka to se koko ni agbo tiata ni ẹka awọn osere apanilẹrin wa, eyi ti awọn ololufẹ wọn maa n nifẹ lati wo wọn.

A si le se apejuwe awọn adẹrinposonu yii gẹgẹ bii akanda ẹda nitori abuda apanilẹrin kii si se nnkan ti eeyan maa n kọ, amutọrun wa lo saba maa n jẹ.

Idi ree to se maa n ka awọn eeyan lara ti ọkan ninu awọn apanilẹrin naa ba jade laye nitori pe yoo pẹ diẹ, ki wọn tun to ri iru ẹda bii tiẹ pada, ti yoo ni ẹbun awada.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Ni awọn ọdun to wa laarin 1980 si 1999, ọpọlọpọ awọn oṣere apanilẹrin lo fi ẹbun ati ọpọlọ pipe wọn da araalu laraya, paapaa ni agbo oṣere tiata Yoruba.

Sugbọn o se ni laanu pe diẹ ninu wọn ti rọrun alakeji, lara wọn si ni awọn oloogbe alawada meje ta fẹ mẹnuba yii:

Baba Suwe

Oríṣun àwòrán, Others

1. Babatunde Omidina

Babatunde Omidina ti ọpọ mọ si Baba Suwe jẹ gbajugbaja agba oṣere apanilẹrin.

Ọkan pataki ni lara awọn osẹre apanilẹrin lasiko to fi n ṣe ere tiata, ko to o di pe aisan bẹrẹ si.

Lara awọn ilumọọka sinima to ti ko pa ni Elebolo, Larinloodu ati bẹbẹ lọ.

2. Omoladun Omidina

Moladun Omidina, ti ọpọ mọ si Moladun Kenkelewu jẹ oṣerebinrin to gbajumọ gẹgẹ bi apanilẹrin. Ọkan pataki si ni lara awọn oṣerebinrin to jẹ apanilẹrin nigba aye rẹ.

Baba Suwe ati Omoladun

Oríṣun àwòrán, others

Moladun Kenkelewu jẹ iyawo Baba Suwe, wọn si jọ kopa ninu ọpọ sinima ṣaaju iku rẹ lọjọ kinni, oṣu Kẹsan-an, ọdun 2009.

Ẹrin arintakiti ni awọn ololufẹ Omoladun ma n rin ti wọn ba n wo awọn sinima rẹ, paapaa to ba tun jẹ ere ti oun ati ọkọ rẹ, Baba Suwe ba jọ wa ninu rẹ.

Iroyin sọ pe aisan ẹjẹ riru lo ṣeku pa a.

Lukuluku

Oríṣun àwòrán, others

3. Lukuluku Bantashi

A ko mọ orukọ abisọ arakunrin yii, ṣugbọn Lukuluku Bantashi tun jẹ ongbotagi oṣere apanilẹrin ni awọn ọdun 1980 si 1990. Ere Yoruba lo n naa m a n sẹ.

Ko si si ipa ti Lukuluku ko ninu ere, ti awọn ololufẹ rẹ ko ni rẹẹrin arin tọ si ṣokoto.

Lara awọn ere to ṣe ni Yemi My Lover,Ti Oluwa Nile, Ami Orun, Legal Wife, Itunu, ati bẹẹbẹẹ lọ. Oun ati Baba Suwe naa jọ ṣe ere papọ.

Ọdun 1995 ni Lukuluku di oloogbe.

Alaran

Oríṣun àwòrán, others

4. Mufutau Oladokun (Alaran):

Alaran ni ọpọ eeyan mọ Ọgbẹni Mufutau Oladokun si.

Òdú ti kii ṣe aimọ fun oloko ni oun naa ni agbo tiata Yoruba.

O si gbajumọ fun awọn ere apanilẹrin to ma n ṣe. O kopa ninu awọn sinima manigbagbe bi i Erin Lakatabu, Opolo ati Larinloodu.

Àkọlé fídíò, 'Wọ́n sọ fún ìyà mi kó jù mi nù nígbà tí mò ń fi àyà fà bí ejò àmọ́ mo di àrídunú pẹ̀lú gbígbé "weight"

5. Tajudeen Akanmu (Koledowo):

Taa ni ko mọ Koledowo laarin ọdun 1980 si 1999? Ka ma parọ, Tajudeen Akanmu ti ọpọ mọ si Koledowo jẹ oṣere apanilẹrin to mọ iṣẹ rẹ gidi gan-an.

Koledowo

Oríṣun àwòrán, others

Ṣe ipa to ko ninu sinima Alaga Kansu ni ka sọ ni, tabi ti Koto Aie, Koto Orun ati Eran Iya Osogbo? Ko si ipa ti Koledowo ko ti kii pa awọn ololufẹ rẹ lẹẹrin arin takiti.

Àkọlé fídíò, Lalude, Alapini, Odunlade Adekola pàdé lẹ́nu adẹ́rìínpòṣónú yìí

O gbajumọ fun ẹnu rẹ to mu bi abẹ fun eebu, paapaa bo sẹ ma n koju awọn ajẹ ninu ere.

Ṣugbọn ṣe ko sẹni ti ko ni i ku. Ọdun 2008 ni iku wọle mu Koledowo lọ nile rẹ to wa nilu Osogbo.

Baba Sabiko

Oríṣun àwòrán, others

6. Abiodun Aremu (Baba Sabiko):

Baba Sabiko ni ọpọ eeyan mọ Abiodun Aremu si.

Oun naa jẹ gbajugbaja ni ẹka ere sinima Yoruba.

Yatọ si pe o jẹ oṣere, sọrọsọrọ tun ni lori agbohunsafẹfẹ redio ati amohunmaworan nilu Ibadan.

O kopa ninu awọn ere bii Ija Orogun, Ija Ominira ti Oloogbe Ade Love ṣe.

Ọjọ kẹsan-an, oṣu Kẹrin, ọdun 2018 ni Baba Sabiko ku.

Baba Sala

Oríṣun àwòrán, others

7. Moses Olaiya (Baba Sala):

Agba oṣere apanilẹrin ti a ko tun le gbagbe ni Moses Olaiya, Baba Sala.

Alawada kẹrinkẹri ni Baba Sala, to tun jẹ akọrin ati osẹre ori itage.

O jẹ ọkan lara awọn to kọkọ n ṣe ere ori itage lori amohunworan akọkọ ni Naijiria, WNTV, to ti di NTA Ibadan bayii, pẹlu ere Alawada.

Ọdun 2018 ni Baba Sala di oloogbe lẹni ọdun mejilelọgọrin.

Dejo Tunfulu

Oríṣun àwòrán, Dejomania/Instagram

Kunle Makinde Adetokunbo (Dejo Tunfulu):

Kunle Makinde Adetokunbo, ti ọpọ eeyan mọ si Dejo Tunfulu lo jẹ gbajumọ adẹrinposonu nigba aye rẹ.

Ọjọ Ẹti, ọjọ Kinni osu Kẹrin ọdun 2022 ni Dejo Tunfulu mi kanlẹ sile iwosan kan ladugbo Ikorodu lasiko aisan ranpẹ.

Aadọta ọdun ni loogbe naa lo loke eepẹ, ki ọlọjọ to de.

Àkọlé fídíò, Ará ìlú ò lè dá owó fún iṣẹ́ ìjọba, ohun tí mo fẹ́ ṣé tí àwa ará Ekiti yóò ní owó tiwa rèé - Olùdíjé ADC

Ní ọjọ́ kọkànlélọ́gbọ̀n oṣù Karùn-ún, ọdún 1972 ni wọ́n bi Tunfulu ní Idumota, Lagos Island, nipínlẹ̀ Eko.

Ọmọ bíbí ìlú Ikija, Abeokuta, ìpínlẹ̀ Ogun ni.

Dejo Tunfulu lọ sí ilé ẹ̀kọ́ alákọ̀ọ́bẹ̀rẹ̀ ní Ansar-Ud-Deen, Lagos Island, lẹ́yìn èyí ló lọ sí Modern Way Nigeria School of Printing níbi tó ti gbàwé ẹ̀rí nípa ìmọ̀ ìtẹ̀wé.

Àkọlé fídíò, Ko sọna ni APC ati PDP

Ipa adẹ́rìnínpòṣónú ló máa ń kó nínú eré sinimá tó sì máa ń kálòlò nínú eré.

Sinimá Omo Oran ló fi di gbajúgbajà èyí tí òun àti Lalude jọ ṣe.

Ní ọdún 1987 ló kọ́kọ́ ṣeré lórí amóhùnmáwòrán nígbà tó kópa nínú eré ọlọ́sọ̀ọ̀ṣẹ̀ Apere Ijogbon èyí tí ikọ̀ Kolawole International Theatre Group máa ń gbé jáde.

Àkọlé fídíò, 'Tí kìí bá ṣe pé mo rọ lẹ́sẹ̀, àwọn èèyàn sì kọ̀ láti gbé mi lọ ilé ẹ̀kọ́, ó yẹ kí ń ti dí "Lawyer" àmọ́...'

Ní ọdún 2012 ló pàdánù ìyàwó rẹ̀ tó kọ́kọ́ fẹ́ sọ́wọ́ ikú.

A wa n gbadura pe ki Ọba Oke tẹ gbogbo wọn si afẹfẹ rere.