Mapoly student's death: Lẹ́yìn ọjọ́ kẹfà tí Happiness di omidan MAPOLY ni wọ́n ṣekú pà á ní Ogun

Oríṣun àwòrán, @Dapo Abiodun
Mo gbọdọ rii pe ọwọ tẹ awọn to pa Odeh - Gomina Dapọ Abiọdun
Ni bayii, Gomina Dapọ Abiọdun ti ipinlẹ Ogun ti ṣe ileri pe gbogbo nnkan ti yoo ba gba loun yoo ṣe lati rii pe ọwọ tẹ gbogbo awọn to lọwọ ninu iku Omidan Mapoly, Happiness Odeh.
Gomina Abiọdun lo sọrọ naa ninu atẹjade to fi sita l'ọsan oni, ọjọ Aiku, Sannde lakoko to n kẹdun ikun ọmọbinrin naa.Mo gbọ́dọ̀ ríi pé ọwọ́ tẹ̀ àwọn tọ pá Happiness MAPOLY, o tó gẹ́ ní Ogun- Gomina Dapo Abiodun
O ni iwa ọdaju ni awọn to ṣeku pa Odeh hu, ti wọn si gbọdọ jiṣẹ ẹṣẹ wọn laipẹ nitori toun ni igbagbọ wi pe ọwọ palaba wọn maa segi.
- Kò sí ẹlẹ́gbẹ́ Atiku láàrín Tinubu àti Obi - Dino Melaye
- Òjò arooroda mú èèyàn 50 lọ, àìmọye di aláinílélórí báyìí ní Jigawa
- Mo gbọ́dọ̀ ríi pé ọwọ́ tẹ̀ àwọn tọ pá Happiness MAPOLY, o tó gẹ́ ní Ogun- Gomina Dapo Abiodun
- Ìjàmbá iná pa olùjọ́sìn 41 lásìkò iṣẹ́ ìsìn lọ́jọ́ Àìkú
- Adeleke tẹ́wọ́ gba kọ́míṣọ́nà Aregbesola sẹ́gbẹ́ òṣèlú PDP, Ó ní àìríkanṣèkan lẹjọ́ tí Oyetola gbé lọlé ẹjọ́
- Wọ́n tí sìn Páṣítọ́ Shuaib Busari tí àwọn adigunjale ṣekúpa niluu ibadan
Bẹẹ lo sọ pe oun ti paṣẹ f'awọn ọlọpaa lati rii daju pe ọwọ tẹ gbogbo awọn to lọwọ ninu iku oloogbe naa, to si tun ba awọn mọlẹbi rẹ kẹdun.
Gbogbo akitiyan lati ba agbenuso fawon olopaa ipinle Ogun, Abimbola Oyeyemi soro lori isele naa lo ja si pabo titi asiko ti a pari akojopo iroyin yii.

Oríṣun àwòrán, @Happiness
Lẹyin ọjọ kẹfa ti Happiness di Omidan Mapoly ni wọn ṣeku pa a l'Ogun.
Titi di asiko ti a pari akojọpọ iroyin yii l'awọn obi, ọrẹ ati ololufẹ ọmọdebinrin akẹkọọ ile ẹkọ Gbogboniṣe ti Mọshood Abiọla to wa niluu Abẹokuta kan, Happiness Odeh ṣi fi wa ninu ibanujẹ.
Eyi ko ṣeyin lori bi wọn ṣe jii gbe, ti wọn si tun d'ẹmi rẹ legbodo.
- Kò sí ẹlẹ́gbẹ́ Atiku láàrín Tinubu àti Obi - Dino Melaye
- Adeleke tẹ́wọ́ gba kọ́míṣọ́nà Aregbesola sẹ́gbẹ́ òṣèlú PDP, Ó ní àìríkanṣèkan lẹjọ́ tí Oyetola gbé lọlé ẹjọ́
- Wọ́n tí sìn Páṣítọ́ Shuaib Busari tí àwọn adigunjale ṣekúpa niluu ibadan
- Ìjàmbá iná pa olùjọ́sìn 41 lásìkò iṣẹ́ ìsìn lọ́jọ́ Àìkú
- Àjọ àgùnbánirọ̀ NYSC sọ̀rọ̀ lórí àgùnbánirọ̀ tílé ẹjọ́ rán lọ sẹ́wọ́n nítorí 'yahoo-yahoo'
- Wò ó bí èsì ìbò ààrẹ ní Kenya ṣe lọ....
Iroyin to tẹ BBC YORUBA lọwọ sọ pe oko ere itage kan ti wọn n ya lọwọ niluu Ipara, Ode Rẹmọ, ipinlẹ Ogun ni Happiness n lọ nirọlẹ ọjọ Iṣẹgun to kọja yii.
Nibe ni ọrọ ti bẹyin yọ ko to di pe wọn da a lọna, ti wọn si jii gbe lagbegbe Ipẹru Rẹmọ.
Lẹyin ti wọn ji Happiness gbe, la gbọ pe wọn fipa ba a laṣepọ, ko to di pe wọn ṣeku pa a danu, ki aṣiri ma ba a tu sita.
Wọn ni ọjọ kẹta, oṣu kẹjọ, ọdun ti a wa yii ni Happiness to wa ni ipele keji (ND II), ẹka ikẹkọọ iṣẹ igbohunsafẹfẹ (Mass Communication) gbega oroke ninu idije Omidan Mapoly to waye l'ọgba ile ẹkọ naa.
Bawo lo ṣe ṣẹlẹ?
Irọlẹ ọjọ Iṣẹgun to kọja yii ni wọn sọ pe Happiness dagbere f'awọn ọrẹ rẹ, koda, ti wọn tun lo sọ f'awọn obi rẹ lori foonu wi pe oun n lọ s'oko ere kan niluu Ipara to wa ni Ode Rẹmọ.
Wọn ni Happiness ko tii de ibi to n lọ ko to di pe awọn oniṣẹ ibi t'ẹnikẹni ko tii mọ titi digba ti a pari akojọpọ iroyin yii pade rẹ lọna, ti wọn si jii gbe.
- Wo àwọn nọ́mbà ìpè agbófinró tó yẹ kò mọ̀, èyí tó pè tí ìkọlù agbébọn bá dé
- Ọkọ àfẹ́sọ́nà kọ̀ mí sílẹ̀ pé mo ní iṣan lápá, ọ̀yan mi sì ǹ rá torí iṣẹ́ ọ̀gbìn – Àgbẹ̀ Obìnrin
- Egungun Oloolu ti ilẹ̀ Ibadan fojú han aráyé! Gbọ́ àwọn ǹkan tó ń dẹ́rù ba obìnrin, ọmọde nípa rẹ̀ àti èèwọ̀ rẹ̀
- 'Ó yẹ kí ẹnu mi wọ́ sẹ́gbẹ̀ẹ́, kí ọ̀rọ̀ ẹnu rẹ̀ má dá, mi ò lè rìn dáadáa'! Ṣé o lè mọ̀ lára Anifa pé ó ní Hemiplegia Cerebra
- Òṣèré tíátà, ẹ má jẹ́ kí àbùkù wọ ìlàkàkà yín láti kó ọrọ̀ jọ - Ajirebi
A gbọ pe Happiness de ibudoko Ogere t'awọn ọkọ akero maa n duro si, nibẹ si lo ti wọ mọto miran to n lọ siluu Ipara to ti fẹ lọ darapọ mọ oko ere to n lọ lọwọ.
Latigba naa la gbọ pe wọn ko ti gburo rẹ mọ.
Gbogbo bi wọn ṣe n pe ẹrọ ibanisọrọ rẹ la gbọ pe ko lọ mọ, ti wọn si ni bo ṣe poora lojiji n kọ awọn eeyan, paapaa awọn ọrẹ rẹ lominu.
Oku rẹ ni iroyin fi to wa leti pe awọn ẹlẹyinju aanu kan ba pade l'Ọjọbọ, ti wọn fi ranṣẹ s'awọn ọlọpaa to pada gbe oku naa lọ si mọṣuari ọsibitu t'awọon olukọni, iyẹn Olabisi Onabanjo University Teaching Hospital, to wa niluu Ṣagamu.
- Kò rọrùn rárá láti dàgbà ní agbègbè bíi Mushin, àànú Ọlọ́hun ló sọ mi di agbábọ́ọ̀lù Super Falcons - Rasheedat Ajibade
- Ẹ má bú ọkọ́ mi mọ́, Bàbá Tobi kò jẹ́bí bó ṣé dáná sún aṣọ èrè ṣíṣá ọmọ rẹ - Ìyá Amusan
- Wo àwọn ọkùnrin tó ń múra bí obìnrin àti ohun tí àwùjọ ń fi ojú wọn rí
- Iléeṣẹ́ apoògùn wọ́gilé ìpara ọmọdé ‘baby powder’ lẹ́yìn tí àwọn èèyàn ní ó ń fa àrùn jẹjẹrẹ
- Á san ọ̀pọ̀ mílíọ́nù náírà fáwọn olùpẹ̀jọ́ EndSARS - Ìjọba àpapọ̀
- Àwọn Olùkọ́ Akure pegedé lórí ètò Akomolede àti Aṣa lórí BBC Yorùbá
Iku Happiness ko ni nnkan ṣe pẹlu ipo Omidan Mapoly - Aarẹ ẹgbẹ akẹkọọ
Aarẹ ẹgbẹ awọn akẹkọọ Mapoly, Kọmureedi Sodiq Damilọla Ajani n'igba to n f'idi iṣẹlẹ naa mulẹ, sọ pe bo tilẹ jẹ pe iku Happiness dun awọn gidi, sibẹ o sọ pe iku rẹ ko ni nnkan ṣe pẹlu Omidan Mapoly to ṣẹṣẹ gba laipẹ yii.
Ajani, ninu atẹjade toun pẹlu alukoro ẹgbẹ awọn akẹkọọ naa, Joy Okolie bu ọwọ lu lọjọ Satide lo ti jẹ ko di mimọ pe ko si awuyewuye kan to dide lẹyin idije Omidan Mapoly to waye kọja lọ.
Ajani ni pe: ni ọjọ mẹta sẹyin ni wọn ji oloogbe ọhun gbe loju ọna oko ere to fẹ lọ ṣabẹwo si.
"Awa ẹgbẹ akẹkọọ ile ẹkọ gbogboniṣe Moshood Abiola kede ipapoda Omidan Happiness Odeh, akẹkọọ ẹka iṣẹ igbohunsafẹfẹ ti Mapoly.
"Gẹgẹ bi iroyin to tẹ wa lọwọ, oju ọna Ipẹru ni wọn ti jii gbe ko to de ibi to n lọ.
Oloogbe naa kuro niluu Abẹokuta lọjọ mẹta sẹyin, to si n lọ si oko ere itage niluu Ipara, Ode Rẹmọ, pẹlu ajọmọ awọn obi rẹ.
"Lati tako awuyewuye to n lọ kaakiri nipa iku rẹ, iku rẹ ko ni nnkan ṣe pẹlu ipo Omidan Mapoly to ṣẹṣe gba. Ọjọ kẹta, oṣu kẹjọ lo gba awọọdu ọhun, oko ere to si n lọ ko ni ohunkohun ṣe pẹlu idije Omidan to waye lọgba ile ẹkọ.
"A ba awọn mọlẹbi, ọrẹ ati akẹgbẹ rẹ kẹdun. Ki Ọlọrun fun wa ni ọkan lati gba iku rẹ. Sun re laya Olugbala."
Bakan naa ni Ajani tun jẹ ko di mimọ pe ṣe l'awọn oniṣẹ ibi naa mu foonu rẹ lọ, to si l'awọn ọlọpaa ti bẹrẹ iṣẹ iwadii wọn.

















