Kenya Presidential Election Results: Àkójọpọ̀ bí èsì ìbò ààrẹ ṣe rí rèé

Orílẹ̀-èdè Kenya ti yan ẹni tó wú wọn bí aàrẹ, Ruto William ló jáwé olúborí ní Kenya
Wọ́n ti kéde Wiliam Ruto ni aarẹ Kenya, wo bí èsì ìdìbò náà ṣe lọ níbí....
Wò ó bí èsì ìbò ààrẹ ní Kenya ṣe lọ....
- Iléeṣẹ́ ológun kéde orúkọ àwọn afurasí agbébọn tó ṣé ìkọlù sì Owo
- Kí ló dé tí orúkọ̀ ọ̀daràn tó sá kúrò lọ́gbà ẹ̀wọ̀n Kuje ṣe wà lára àwọn agbébọn tó kọlu ṣọ́ọ̀ṣì Owo-
- Awakọ̀ àti èrò lé àwọn adigunjalè pẹ̀lú òkò wọnú igbó lópòpónà Ibadan sí Eko
- Àwọn tó ń fi àìsàn bú Tinubu ti lulẹ̀, ó dàgbà lóọ̀tọ́ọ́, àmọ́ kò ṣàìsàn - APC -
- Owó pínpín dá rògbodìyàn òṣèlú sílẹ̀ ní Ede, ẹ̀mí olóyún àti ọkùnrin kan ba rìn

Ẹ fi ọwọ kan isalẹ yii lati mọ bi ẹkun kọọkan tabi ipinlẹ kọọkan se n dibo aarẹ ati awọn esi idibo to jade ni ẹkun kọkan.
Esi ibo aarẹ lati ipinlẹ kọọkan ree:
Bakan naa ni awọn lọgalọga ileeṣẹ to n ri si eto idibo naa ti wa ni ikalẹ.
Ileeṣẹ to n ri si eto idibo gbogbogbo ni Kenya ti n mura lati kede awọn to jawe olubori bayii ninu eto dibo naa.
Akọroyin BBC to wa nibi ti wọn ti n ṣe akojọpọ ibo naa, Dickens Owele sọ pe wamu-wamu ni awọn ẹṣọ alaabo duro nibẹ lati ri daju pe ohun gbogbo lọ bo ṣe yẹ.
Nibi ti wọn yoo ti kede esi ibo naa niluu Nairobi, Owele sọ pe oniruru awọn aṣoju ẹgbẹ oṣelu lo korajọ sibẹ ni imurasilẹ ikede esi ibo ọhun.
Awọn eeyan orilẹ-ede ọhun lo ti woye ẹni ti ipo Aarẹ yoo ja mọ lọwọ bayii.
Ẹwẹ, ọpọ awọn eeyan orilẹ-ede naa lo ti n binu lẹyin ti awọn ileesẹ iroyin kan n kede esi ibọ ọhun, eyii ti awọn araalu n pe ni iroyin ẹlẹjẹ.
Wayi o, ileeṣẹ to n ri si eto idibo naa ti w kilọ fun awọn ileesẹ iroyin lati dẹkun ati maa kede esi ibo ti Awọn ko tiI fi lede.
Awọn iroyin ti ileeṣẹ iroyin BBC n gbe jade nipa ibo Aarẹ lo jẹ eyii ti a ri oju opo ileeṣẹ to n ri si eto idibo orilẹ-ede Kenya, iyẹn, Independent Electoral and Boundaries Commission (IEBC). Alafo diẹ le wa laarin igba ti ileeṣẹ naa gbe esi wọn jade ati akoko ti awa naa fi lede. Ileeṣe iroyin BBC yoo kede esi idibo Aarẹ orilẹ-ede Kenya gẹgẹ bii alakalẹ ofin orilẹ-ede naa.

Ki lo ti ṣẹlẹ ṣaaju?
Bí èsì ìdìbò ààrẹ Kenya ṣe lọ rèé
Eto idibo aarẹ ni orilẹede Kenya ti waye ni ọjọ Isegun, to si ti pari.
O si ti foju han pe iye awọn eeyan to dibo lọdun yii kere si iye awọn to ti n dibo latẹyinwa.

Idi ni pe eeyan miliọnu mejila ati ọgọrun kan pere lo jade lati wa dibo dipo eeyan miliọnu mọkanlelogun to fi orukọ silẹ, ti wọn si n reti pe ko wa dibo.
Awọn eto idibo to waye lasiko ibo gbogbo gboo ọjọ Isẹgun ni ibo aarẹ, tawọn asofin agba, ibo tawọn ọm ile asofin apapọ ati tawọn gomina ipinlẹ.
- Òmìnira Yorùbá ló lé fòpin sí ipàníyàn, ìjínigbé nílẹ̀ wa - Sunday Igboho
- Pásítọ̀ àti èkejì rẹ̀ tó bẹ́ orí ọmọdé ṣètùtù sí ṣọ́ọ́ṣì gba ìdájọ́ ikú
- Folarin ní òun kẹ́ pàkúté méjì sílẹ̀ fún Makinde, ọ̀gá ọlọ́pàá, ẹ gbà wá - PDP Oyo
- Àṣìyàn olórí lọ́dún 2023 léwu fún ọjọ́ ọ̀la Nàìjíríà - Obasanjo
- “Gbogbo àwọn tó bá kọ ‘proposal’olólùfẹ̀ wọn yóò bẹ̀rẹ̀ sí ń san owó ìtanràn”
Saa ọdun marun gbako si ni awọn oludije to ba wọle yoo lo lori aleefa ti wọn dibo yan wọn si.
Ireti si wa pe loni ni wọn yoo kede awọn oludije to jawe olubori lasiko eto idibo naa.
BBC Yoruba yoo si maa mu akojọpọ bi esi idibo aarẹ naa se n waye wa si etigbọ yin.
















