Òmìnira Yorùbá ló lé fòpin sí ipàníyàn, ìjínigbé nílẹ̀ wa - Sunday Igboho

Oríṣun àwòrán, Olayomi Koiki/Facebook
Gbajumọ aṣiwaju ipe fun idasilẹ orilẹede Yoruba, Oloye Sunday Adeyẹmọ ti ọpọ mọ si Sunday Igboho tun ti sọrọ sita.
Igboho ti fọwọ gbaya pe ipinya ẹya Yoruba kuro ni Naijiria nikan lo le mu opin si ipaniyan ati ijinigbe to wọpọ laarin wa.
Igboho tun wa kede ọjọ Kẹtala oṣu kẹjọ gẹgẹ bi ọjọ iwọde alaafia fun ipe fun orilẹede Yoruba ni ipinlẹ Califonia lorilẹede Amrika.
Bakan naa lo ni irufẹ iwọde naa yoo tun maa waye ni Trafalgar Square niluu London.
Gẹgẹ bi atẹsita ti agbenusọ rẹ, Olayomi Koiki fisita loju opo rẹ lọjọ isẹgun, wa rọ awọn ọmọ Yoruba niluu lati darapọ mọ wọn fun iwọde alaafia naa.
“Bi itajẹsilẹ ṣe n waye yika Naijiria lo jẹ oun ibẹru, ti igbe aye si ti su ọpọlọpọ ọmọ Yoruba.
Eyi si da lori bi ijọba Buhari ṣe kuna lati ṣe fẹ tọwọ bọ abadofin nipa ipese ibudo idaranjẹ fawọn darandaran, RUGA.”

Oríṣun àwòrán, Olayomi Kioki
Ẹyin ọdọ bii temi, ẹ jẹ ka parapọ gba ilẹ wa lọwọ awọn agbebọn - Igboho
“O to gẹ, asiko ti to lati fi opin si ipaniyan ati ijinigbe to wọpọ yii.
“A wa rọ awọn ọmọ Yoruba lati darapọ mọ wa fun iwọde yii.”
“Wọn ti ni ka bọ sita lọjọ kẹtala oṣu yii lati fi ẹhonu wa han fun araye, ni asẹ Ọlọrun, a o jade ṣe iwọde naa.”
Igboho ni pupọ lara awọn nkan ti oun sọ nigba naa, lo ti wa si imusẹ, ti o si jẹ ohun to ba ni ninuje.
“Awọn kan n sọ pe Igboho lo n da ilu ru, o fẹ da ilu ru ni ni gbogbo igba. Ṣe ẹ ti wa rii nisinsiyi bayii?
“Ki ni wahala ti mo fẹ da silẹ.”
Igboho tun tẹnu mọ ọ pe idi niyi ti oun fi n pariwo pe ki wọn jẹ gbogbo awọn tawọn jọ jẹ ọdọ, ti awọn ṣi ni okun ti wọn ni akinkanju nilẹ Yoruba jọ pawọpọ gbeja iran Yoruba lọwọ awọn agbebọn.
Atẹjade naa wa fi adirẹsi kan sita nibi ti awọn ọmọ Yoruba ti ko ba si ni Califonia yoo ti lanfaani lati darapọ mọ iwọde naa lati ori ayelujara.















