Àwọn èèyàn kan dá yẹ̀yẹ́ mi sílẹ̀ lórí ikú ọmọ mi - Adeboye

aworan pasitọ Adeboye ati ọmọ rẹ

Oríṣun àwòrán, Enoch Adeboye

Alufaa agba ijọ Redeemed Christian Church of God, RCCG, Pasitọ Enoch Adeboye sọ pe ọpọlọpọ eeyan lo fi oun ṣe yẹyẹ lori iku ọmọ bibi oun, Pásítọ̀ Dare Adeboye lọdun to lọ.

Ọrọ yii lo jade lati ẹnu Pasitọ Adeboye lasiko ayẹyẹ aadọrin ọdun ijọ naa,.

Bakan naa ni wọn tun ṣe ayipada orukọ ibudo ipagọ ijọ naa lati The Redeemed Camp si Redemption City.

Adeboye ni ọjọ to ba oun ninujẹ ju nigba ti ọmọ oun ku ninu oṣu karun un ọdun 2021.

“Awọn kan laarin yin mọ pe mo wa ninu ibanujẹ ọkan nigba ti mo ni ọpọlọpọ ibeere lati beere.

Sugbọn wọn fi mi ṣe yẹyẹ, amọ mo gba ipe lati ọdọ ọmọbinrin kan to ni ki n jẹ ki Ọlọrun gbe mi, ko si fi opin si ibanujẹ ọkan mi.

Ọrọ yii mu itusilẹ ba mi, o si da igbagbọ mi pada”

Ibudo ipagọ RCCG (The Redeemed Camp) yi orukọ pada di Redemption City

Nibi ipade ọlọdọọdun naa si ni ijọ naa ti kede orukọ titun ti ibudo ipagọ ijọ naa yoo ma jẹ.

Adeboye ni ayipada orukọ ipagọ ile jọsin rẹ lati ijọ ‘ The Redeemed Camp’ yoo maa jẹ ilu irapada ‘Redemption City’

Adeboye ni ilu Irapada ni o ma dabi ilu Vatican ti ilu Rome.

Bakana ni wọn ṣe ayipada orukọ si kampu wọn to wa ni Ring Road si orukọ oludasile ile jọsin naa, Pasitọ Josiah Akindayomi.

Àwọn Gómìnà tó ń ṣ’ẹ̀wọ̀n lọ́wọ́, Nyame àti Dariye ti gba ìtúsílẹ̀

Dariye ati Nyame

Oríṣun àwòrán, OTHER

Gomina ana ti ipinlẹ Plateau, Sẹnetọ Joshua Dariye ati gomina tẹlẹ ti ipinlẹ Taraba, Jolly Nyame ti gba itusilẹ kuro ni ọgba ẹwọn ti wọn wa.

Ile iṣẹ ọgba ẹwọn Naijiria lo kede itusilẹ wọn.

Awọn mejeji n jiya ẹṣẹ wọn tẹlẹ lori ẹsun iwa jẹgudujẹra titi di igba ti wọn ri dariji aarẹ orilẹede gba lọwọ aarẹ Muhammadu Buhari ni oṣu diẹ sẹyin.

Awọn ẹlẹwọn mẹtadinlọgọjọ (157) mii naa fara ko ninu oriire naa ti wọn si tun wọn silẹ pẹlu awọn gomina tẹlẹri meji yii.

Ọdun 2018 ni adajọ agb Adebukola Banjoko ni wọn jẹbi ẹsun ti wọn fi kan wọn ni ile ẹjọ giga ilu Abuja.

Ki gan ni ẹsun Dariye ati Nyame?

Dariye ni tirẹ jẹ bi ẹsun kiko iye owo N1.16 biliọnu jẹ lasiko to jẹ gomina ipinlẹ Plateau laarin ọdun 1999 si ọdun 2007 ti wọn si ran an lọ si ẹwọn ọdun mẹrinla

Amọ nigba to ya wọn din iye ọdun ti yoo lo ku si mẹwaa ni ile ẹjọ kotẹmilọrun ti Abuja amọ ti wọn ṣi ni o jẹbi ẹsun ti wọn ka mọ ọ lọwọ.

Nyame to jẹ́ gomina ipinlẹ Taraba laarin ọdun 1999 si 2007 ni wọn fi ẹsun pe o ji iye owo N1.6 biliọnu lapo isuna ipinlẹ ti wọn si ran an lọ si ẹwọn ọdun mejila.

Wọn tun ẹjọ tirẹ naa gbe jade ni ile ẹjọ kotẹmilọrun ti ile ẹjọ naa si ni o jẹbi gbogbo ẹsun ti wọn fi kan an.