Wo àwọn orílẹ̀-ede tí obìnrin ti ń fẹ́ ju ọkọ kan lọ

Oríṣun àwòrán, THE WHISTLER
Kii ṣe ohun tuntun nilẹ Afrika tabi lawọn ilẹ mi pe ọkunrin n fẹ ju obinrin kan lọ, awọn ẹsin ati aṣa kan tilẹ kin irufẹ iwa bẹẹ lẹyin.
Amọ ohun kayeefi ni lọpọ orilẹ-ede pe obinrin n fẹ ju ọkọ kan lọ.
O ṣeeṣe ki obinrin fẹ ọkọ tẹlẹ, amọ ko tun lọ fẹ ẹlomiran, yala nitori iku ọkunrin naa tabi ikọsilẹ.
“Polyandry” ni wọn n pe ni ede Gẹẹsi ti obinrin ba fẹ ju okunrin kan lọ lasiko kan naa.
A ṣe akojọpọ awọn orilẹ-ede mẹrin ti obinrin ti n fẹ ju ọkọ kan lọ lasiko kan naa.
Naijiria
Ohun kayeefi ni yoo jẹ fun ọpọ awọn ọmọ Naijiria pe obinrin ni ju ọkọ kan, paapaa larin ẹya Yoruba.
Ṣugbọn laarin awọn ẹya Irigwe, ni Ariwa Naijiria, awọn obinrin wọn ti fẹ ju ọkọ kan lọ lasiko kan naa ri.
Awọn ẹya Irigwe yii, obinrin wọn maa n fẹ ju ọkunrin kan titi di ọdun 1968, ti wọn dibo tako irufẹ iwa bẹẹ.
Itan sọ pe ṣaaju ọdun 1968 yii, awọn obinrin maa n lọ lati ile sile lati fẹ ọkọ, ti wọn a si maa bimọ sibẹ.
India

Oríṣun àwòrán, Google
Kii ṣe ẹya kan ṣoso lo maa n fẹ ju ọkọ kan lọ ni India, amọ iwa naa wọpọ laarin awọn Pahari ni Ariwa India.
Awọn iran Pachi Pandavas, nibi ti ọmọ iya marun un to jẹ ọkunri ti fẹ obinrin kan ṣoṣo gbagbọ pe ko yẹ ki aṣa naa parẹ.
Yatọ si awọn wọnyii, awọn ẹya Toda, ni Nilgris ati Najanad Vellala ni Guusu India naa maa n fẹ ọkọ meji.
Nepal

Oríṣun àwòrán, Quora
Nepal jẹ ọkan lara awọn orilẹ-ede to toṣi julọ ni Asia.
Lootọ ọdun 1963 ni wọn fofin de igbeyawo laarin obinrin kan ṣoṣo ati ọkọ to ju ẹyọ kan lọ, ṣugbọn ẹya kan bii Humla, Dolpa ati Kosi si n ṣe bẹẹ.
Wọn ni o jẹ ọkan lara awọn aṣa ẹya wọn, awọn ko si le jọwọ rẹ laelae, nitori naa, awọn bọwọ fun aṣa naa ju ofin lọ.
Yatọ si awọn ẹya wọnyii, awọn ẹya mii bii Bhote, Sherpa ati Newbie naa maa n ṣe bẹẹ.
China
Awọn eeyan agbegbe Tsang ati Kham ni iha Tibet lo ṣaba maa n fẹ ọkọ to ju ẹyọ kan lọ ni China.
Amọ awọn eeyan ẹya mii bii Monpa, Tamang, Qiang, Sherpa ati Lhoba naa maa n ṣe bẹẹ, to fi mọ awọn ẹya Han ati Hui.
Iwadii kan ti wọn ṣe labule Xigaze ati Qamdo lọdun 2008 fi han pe, nnkan bii ida ogun si aadọta awọn eeyan naa ni obinrin wọn n fẹ ju ọkọ kan lọ.
Iwadii ọhun sọ siwaju si pe lawọn abule miran, nnkan bii ida aadọrun awọn obinrin wọn lo n ṣe bẹẹ.
















