Kí ló dé tí orúkọ̀ ọ̀daràn tó sá kúrò lọ́gbà ẹ̀wọ̀n Kuje ṣe wà lára àwọn agbébọn tó kọlu ṣọ́ọ̀ṣì Owo?

Owo Church Attack: Akeredolu tan ìmọ́lẹ̀ sí bí orúkọ̀ Idri Ojo ṣe jẹyọ lára àwọn agbébọn tó kọlu ṣọ́ọ̀ṣì

awọn ẹlẹwọn

Oríṣun àwòrán, Federal Ministry of Internal Affairs

Ni ọsan Ọjọru, ni aworan ati orukọ awọn eeyan kan gba ori ayelujara kan pe awọn lo sa kuro ni ẹwọn Kuje nilu Abuja laipẹ yii.

Amọ lara awọn ọdaran naa ni orukọ ọkunrin wa, to n jẹ Idris Ojo.

Bakan naa ni iroyin kan sọ pe orukọ Idris Ojo yii wa lara awọn orukọ ti olori eto aabo ilẹ yii, Ọgagun Lucky Irabor da pe o wa lara awọn agbebọn to lọ kọlu sọọsi Aguda nilu Owo.

Eyi si mu ki awn eeyan maa se ariyanjiyan lori ayelujara pe ejo ti lọwọ ninu ọrọ yii, ti orukọ awọn agbebọn to lọ sisẹ ibi ni Owo si jẹ ayederu.

Awọn eeyan naa ni bawo ni wọn se fẹ se alaye pe ọdaran to wa lọgba ẹwọn Kuje se ri aaye jade lati lọ sisẹ ibi nilu Owo, to si tun pada si ọgba ẹwọn naa.

Wọn ni o yẹ ka ranti pe lẹyin ti ikọlu ilu Owo waye ni isẹlẹ fifọ ọgba ẹwọn Kuje to sẹlẹ, ti awọn ẹlẹwọn kan fi raye salọ.

Idris Ojo ko si lara awọn agbebọn to paniyan ni Owo, o wa sa pamọ sibẹ ni:

Akeredolu wipe o ṣeeṣe ko jẹ pe eyi lo fa idarudapọ ninu ifilede ọgagun Irabor to fi darukọ Idris Ojo pe o wa lara awọn ti wọn ṣe akọlu si ijọ St. Francis nilu Owo, amọ eyi ko ri bẹẹ.

Gomina naa wa rọ awọn ara ilu lati wa nipo oju lalakan fi n ṣọri, ki wọn si maa fi gbogbo ohun ti wọn ba ri to ijọba ati awọn ẹṣọ alaabo leti.

Ṣaaju ni ọgagun Lucky Irabọ ti fi kede pe ọwọ ti tẹ awọn to ṣe akọlu sile ijọsin St. Francis nilu Owo loṣu kẹfa ọdun yi.

Asiko ikọlu naa si ni eeyan mẹtalelogoji ti padanu ẹmi wọn, ti awọn to le ni aadọta si farapa.

Ninu ọrọ ọgagun Irabor, o wipe ọdaran kan, Idris Ojo, to sa kuro lọgba ẹwọn Kuje loṣu to kọja, wa lara awọn afunrasi naa.

Eyi lo mu ki ọpọ ọmọ Naijiria bẹrẹ si ni beere lori ẹrọ ayeluja boya o ṣeeṣe ki ọdaran kan kuro lọgba ẹwọn lati lọ daran kan, ko si tun pada sibẹ lai si ẹni to nimọ nipa rẹ.

Wọn mu Idris Ojo nilu Owo lasiko to sa kuro ni Kuje, ti wọn si ko pọ mọ agbebọn to kọlu sọọsi - Akeredolu:

Amọ nigba to n tan imọlẹ sidi isẹlẹ naa, Gomina ipinlẹ Ondo, Oluwarotimi Akeredolu ni ariyanjiyan to n lọ lori ẹrọ ayelujara naa, ko yẹ ko waye rara.

Atẹjade kan ti akọwe iroyin fun gomina Akeredolu, Richard Olatunde, fisita ni ede-aiyede yi lo waye nitori bi ọga agba feto abo ṣe ka orukọ ọkan ninu awọn to sa lọgba ẹwọn Kuje mọ awọn ti wọn mu lori ẹsun iṣekupani nilu Owo.

Akeredolu ṣe e lalaye pe Idris Ojo to wa lara awọn ti wọn sa kuro ni Kuje lo waa fara pamọ s'ọdọ ẹgbọn rẹ, Jimoh Rasheed Ibrahim, nilu Akure.

Asiko yii si ni awọn agbofinro mu pọ mọ awọn afunrasi ti wọn ṣekupani nilu Owo, to si jẹ pe niṣe ni wọn ko gbogbo wọn pọ si ahamọ kan naa.

Kò ní dára láti mọ̀ pé àwọn Ebira tó wà láàrin wa ń lọ́wọ́ nínú ìjínigbé - Akeredolu

Gomina Rotimi Akeredolu

Oríṣun àwòrán, @RotimiAkeredolu

Gomina ipinlẹ Ondo, Rotimi Akeredolu ti kesi awọn ẹya Ebira to wa nipinlẹ naa lati fi ewe ọmọ mọ awọn ọmọ wọn leti, ki wọn mase fi iwa ijinigbe se awokọse.

Gomina gbe imọran naa kalẹ ninu atẹjade kan ti akọwe feto iroyin rẹ, Richard Olatunde fisita fawọn akọroyin.

Gomina ni awọn iroyin lati ẹnu awọn eeyan to jajabọ lọwọ awọn ajinigbe nipinlẹ naa, ti fidi rẹ mulẹ pe awọn ẹya Ebira lo n sisẹ ibi naa.

O ni awọn Ebira ti n gbe ni alaafia pẹlu awọn eeyan ipinlẹ Ondo lati ọpọlọpọ ọdun sẹyin, ti wọn si maa n se atilẹyin pẹlu wn pẹlu isẹ asekara.

Ẹ̀yin ẹ̀yà Ebira, ẹ máṣe fi àṣà ìjínigbé ṣe àwòkọ́ṣe, ẹ gbájúmọ́ ìṣẹ́ ọ̀gbìn yín – Akeredolu

Gomina Akeredolu tun tẹsiwaju ninu ọrọ rẹ nipa rirọ awọn Ebira naa lati gbajumọ isẹ ọgbin ti aye mọ wọn mọ.

“Mo wa n lo akoko yii lati rọ awọn arakunrin mi pe ki wọn doju kọ isẹ ọgbin ti wn n se.

Kò ní dára láti mọ̀ pé àwọn Ebira tó wà láàrin wa ni Ondo lọ́wọ́ nínú ìjínigbé.

A si n rọ wọn lati mase fi ohun buburu se awokọse, awọn ontaja to wa lẹba titi naa ko si gbọdọ di afinmufinlẹ, a ko ba wọn ja.

A ti ri iye wọn, wọn se atilẹyin fun wa, ti wọn si dibo fun wa lasiko idibo, a si n kesi awọn asaaju wọn lati ba wọn sọrọ.

Wọn n ji awọn eeyan wa lọ ni Ikare, ẹ ba wọn sọrọ, ti wọn si n gbe wọn lọ si oko awọn Ebira.”

Ọwọ́ Amotekun Ondo tẹ àwọn afurasí 151 láti Ariwa pẹ̀lú oògùn abẹnu gọ̀ngọ̀

Amotekun

Oríṣun àwòrán, @upshotreports

Ọwọ ikọ abo Amotekun ipinlẹ Ondo ti tẹ awọn eeyan ti iye wọn jẹ mọkanlelaadọjọ, 151, ti wọn wọ ipinlẹ naa lati Ariwa Naijiria.

Igba keji ree ti ọwọ Amotekun yoo tẹ awọn eeyan to n wọ ipinlẹ Ondo lati Ariwa lẹnu ọjọ mẹta yii.

Igba akọkọ ni ọjọ kẹrin, oṣu Kẹjọ yii, ti wọn ṣawari eeyan 152 loju ọna Akure si Ado Ekiti ni nnkan bii aago mẹfa idaji.

Awọn tuntun ti wọn ṣẹṣẹ ri yii ni wọn ṣawari lọjọ Aiku, ti iye wọn jẹ 168, pẹlu awọn eeyan kan ti wọn ti ji gbe.

Awakọ to ko awọn eeyan naa sọ pe ilu Abuja, Kano, Katsina ati Jigawa loun ti n ko wọn bọ wa si ipinlẹ Ondo.

Nigba to n ba awọn akọroyin sọrọ niluu Akure lọjọbọ to kọja, adari ikọ Amotekun nipinlẹ Ondo, Adetunji Adeleye ni abẹ apo irẹsi lawọn eeyan ti ọwọ awọn kọkọ tẹ sa pamọ si, wọn ko si le ṣalaye ni pato ohun ti wọn fẹ ṣe wa nipilẹ naa.

O ni awọn ba awọn alupupu kan ni ikawọ wọn pẹlu awọn aworan kan.

A oo da wọn pada sibi ti wọn ti wa - Amotẹkun

Adeleye ni awọn yoo ṣe ifọrọwanilẹnuwo fun awọn eeyan ọhun, ki awọn to da wọn pada si ibi ti wọn ti wa.

O ni “Nigba ti a yẹ ọkọ ti wọn gbe wa wo, a ba alupupu mẹwaa ati oniruru oogun abẹnugọngọ lọwọ wọn.”

“Ti a ba yẹ ara wọn wo ti a ko si ri ohun to le ṣe ijamba kankan, ti ko si ṣeni ti wọn wa ba nipinlẹ Ondo, a oo da wọn pada si ibi ti wọn ti wa.”

Ti ẹ ko ba gbabe, inu oṣu Kẹwaa ọdun to kọja ni ọwọ Amotekun kọkọ tẹ awọn ọdọ kan to tẹkọ leti lati Ariwa wa lọ si ipinlẹ Ondo ninu ọkọ akero marun un ọtọtọ ti wọn ko si le sọ ohun ti wọn lọ ṣe nibẹ tabi ẹni ti wọn fẹ lọ ba.

Lara awọn ohun ti Amotekun ka mọ wọn lọwọ ni awọn apo ti oniruru ọbẹ ati ida wa ninu rẹ.