Awakọ̀ àti èrò lé àwọn adigunjalè pẹ̀lú òkò wọnú igbó lópòpónà Ibadan sí Eko

Oríṣun àwòrán, LASMA
Se ni ìsẹlẹ yii dabi ere ori itage nigba tawọn awakọ ati ero dojukọ awọn afurasi adigunjaje, ti wọn si le wọn pẹlu ọkọ wọ ninu igbo.
Awọn Adigunjale naa si lo gbinyanju lati ja awọn eeyan ọhun lole dukia wọn.
Ori afara Kara, lopopona marosẹ Eko si ibadan si ni isẹlẹ naa ti waye ni dede ago mẹfa ku iṣeju marun un.
Nigba ti wọn salaye ohun ti oju wọn ri, awọn ero ninu ọkọ ayokẹlẹ Mazda kan sọ pe ni kete ti awọn gbera lati Mowe, ni awọn ri awọn afurasi adigunjale naa.
Ọkan lara awọn ero ọkọ naa ni awọn meje ni awọn wa ninu ọkọ naa nigba ti awọn fi oju gan ni awọn adigunjale naa.
O ni wọn wọ asọ dudu, wọn si tun gbe ibọn dani lati ja awọn eeyan ni ole.
O ni "Irinajo wa lọ ni irọnu lati Mowe, sugbọn nigbati a de afara gungun to wa ni Kara lopopona naa, awakọ wa ni ki olukokaluku tọju awọn dukia wa nitori awọn adigunjale wa ni itosi.
“Ko pẹ ni a ri awọn adigunjale naa, ti ẹru si n ti ba ọpọlọpọ wa ati awọn yoku, ti ọpọ awakọ si fi ọkọ wọn silẹ lati saa asala fun ẹmi wọn.
“Sugbọn ọkan lara wa ni ki a ma bẹru, ki a dojukọ awọn afurasi adigunjale naa, ti ọpọ si bẹrẹ si ni mu awọn ohun ija bi ada ati igi lati koju awọn adigundale naa.
“Kete ti wọn ri pe awọn ero ti bẹrẹ si ni pe ara wọn jọ, awọn adigunjale naa ba ẹsẹ wọn sọrọ, ti wọn si salọ.
Amọ àwọn eeyan naa gba bo wọn bi o tilẹ jẹ pe wọn ko ri ẹnikankan mu ninu wọn”
Agbenusọ, Ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Ogun, Abimbola Oyeyemi, ti fi idi iṣẹlẹ naa mulẹ.
Oyeyemi ni awọn adigunjale naa lanfani lati sisẹ ibi naa nitori atunṣe to n waye ni opopona marosẹ Eko si Ibadan, eyi si lo fa sunkẹrẹ fakẹrẹ awọn ọkọ.
“Awọn adigunjale naa ni anfani lati ṣe isẹ ibi naa nitori atunṣe to n waye lọwọ ni afara to wa ni opopona Ibadan si Eko.”
Oyeyemi wa ti fi da awọn awakọ ati ero opopona naa loju pe ọwọ ọlọpaa yoo tẹ awọn adigunjale naa laipẹ, ti wọn yoo si fi oju ba ile ẹjọ.
1 bilionu ni ìjọba Ìpínlẹ̀ Eko ń ná fi kó ìdọ̀tí l'óṣooṣù? Ẹ gbọ́ àlàyé Gómìnà Sanwo-Olu

Oríṣun àwòrán, Babajide Sanwo-Olu
Bi ẹ ba jẹ "ṣẹ̀ṣẹ̀ dé" Eko ti ẹ wá gba aarin awọn àdúgbò kan kọja niluu Eko yala ninu ọkọ tabi ẹ ń rìn, òórùn ti yoo bù jáde ni yóò kí yin kaabọ si Eko.
Eyi ko si jẹ ajoji si ọpọlọpọ ọmọ Naijiria torí Ìpínlẹ̀ Eko ni ibùdó katakara to tobi ju ni Naijiria, lo jẹ ki wọn bọ sórí ayélujára maa beere ibeere lọwọ gomina Eko nitori ọrọ to sọ lori iforowanilenuwo ori ẹ̀rọ amohunmaworan to ṣe lánàá.
Ohun ti Gómìnà Ìpínlẹ̀ Eko mẹ́nu ba jẹ lara awọn ìṣòro gboogi tí àwọn eeyan Ìpínlẹ̀ Eko n koju ìyẹn ìdọ̀tí to wa káàkiri adugbo to si ni ijọba oun ti ná bilionu kan naira lati ko ati lati da ìdọ̀tí nu laarin oṣù kan.
Àmọ́ ṣe ni ọrọ naa tu si ori ayelujara ti awọn ọmọ Naijiria si n ju ibeere síta pe ki nidi ati pe lọ́nà wo ni o gba na odindi bilionu kan naira.
Koko ọrọ gaan ni pe ilu le lọwọlọwọ ni ti ọrọ aje ni Naijiria kódà ijọba gan n rahun pe ko sowo lode.
Eyi lo mu ki BBC tan ina wa ìdí ọrọ yii ti Gomina Sanwo-Olu sọ lori eto. Ohun to si sẹlẹ ni pe Gomina ko sọ pato asiko wo si asiko wo ni wọn ná iru owo ọhun.

Oríṣun àwòrán, Babajide Sanwo-Olu
Nigba ti wọn bere lọwọ rẹ pe ki lo fi aduru owo to wọle si Ìpínlẹ̀ ṣe lo mẹ́nu ba ọrọ bilionu kan náà.
Ẹwẹ, agbenuso fun ijọba Ìpínlẹ̀ Eko, Gboyega Akosile sọ fun BBC Pidgin pe akojopo gbogbo owo nìyẹn, "nigba ti ẹ ba ṣe atupalẹ rẹ lẹ ó mọ ohun ti ìjọba ń ná owó lé lórí.
Ọpọlọpọ oṣiṣẹ akodọti ni ijọba n san owo wọn, ìjọba n ra ọpọlọpọ ọkọ akodọti, wọn ń ra epo disu sínú àwọn ọkọ yii àti àwọn iṣẹ́ míì tí ìjọba n ṣe láti sọ ilu di mimọ", eyi ni ọrọ ti agbenuso ìjọba sọ.
Àwọn nǹkan míì tí Gómìnà Sanwo-Olu sọ̀rọ̀ nípa rẹ̀
Lasiko to farahàn lori amohunmaworan Channels TV, gomina tun mẹ́nu ba awọn igbesẹ míì ti ìjọba rẹ n gbe àti àwọn ààtò ti wọn ṣe.
Fifopin si Okada gigun- Gomina Sanwo-Olu ni opin ti awọn fi si gigun Okada ni Eko ti mu adinku ba ijamba ojú pópó, iku àti idigunjale lójú ọna.
"Nigba ti a fi kọ́kọ́ ṣe òfin Okada yii, a máa ń rí ijamba to to ẹẹdẹgbẹta loju popo to wa lati ọwọ Okada ṣùgbọ́n lati igba taa ti fi opin sii, ijamba ti dinku si bii ọgọrun ".
Abo - Gomina Sanwo-Olu ni awọn n ṣiṣẹ́ pọ pẹlu gbogbo awọn ikọ̀ alaabo lati da abo bo Ìpínlẹ̀ naa. Ó ní àwọn ti fun awọn Ọlọpaa ni ọkọ to le ni igba àti ọgọ́ta láti rán iṣẹ́ wọn lọwọ.
Iṣẹlẹ Pajawiri - Ó ní àwọn n bojuto iṣẹlẹ pajawiri ni Ìpínlẹ̀ naa. "A ti ra ọkọ to le ni mẹrinlelọgọ́ta fún iṣẹlẹ pajawiri. A si ti ṣe idanilẹ̀kọ́ fun awọn oṣiṣẹ pana-pana to le ni ẹgbẹ̀ta a o si maa to pín wọn si ẹnu iṣẹ wọn.















