"Jẹ́jẹ́ ni ọmọ mi ń bá ìyá rẹ̀ tajà, káwọn ẹgbẹ́ òkùnkùn tó yìnbọn bà á"

Oríṣun àwòrán, SCREENSHOT
Ibànújẹ́ ńlá ni kí ọmọ ti ojú òbí rẹ̀ lọ sọ́run, gbogbo abiyamọ ayé, a kò ní fi ọwọ́ gbé ọmọ sin.
Ibanujẹ nla ni bi Firdaos, ọmọ ọdún mẹ́sàn-án, ṣe pàdánù ẹ̀mí rẹ̀ ní Ìlọrin nígbà tí àwọn ọmọ ẹlẹ́gbẹ́ òkùnkùn ṣe ìkọlù sí ara wọn.
Ìbọn tí àwọn ọmọ ẹlẹ́gbẹ́ òkùnkùn náà ń yìn ló ṣèèṣì bá ọmọdé náà, to sì jáde láyé.
Ismail Elesin, tii se bàbá Firdaos ní ohun ìbànújẹ́ ńlá ni ikú ọmọ náà jẹ́ fún àwọn.
Elesin, tó ń gbé ní agbègbè Olunlade, Ilorin, níbi tí ìṣẹ̀lẹ̀ náà ti wáyé, ṣàlàyé fún BBC Yorùbá bí ìṣẹ̀lẹ̀ náà ṣe wáyé.
Elesin ní ọ̀sán Ọjọ́rú, ọjọ́ Kẹwàá, oṣù Kẹjọ, ọdún 2022 ní isẹlẹ ọhun waye, to si jẹ ẹ̀dùn ọkàn gbáà bi ọmọ náà se ku.
Elesin ní ṣàdédé ni wọ́n pe òun wí pé àwọn ẹlẹ́gbẹ́ òkùnkùn ń bá ara wọn fa wàhálà, tí wọ́n sì ti ń pa ara wọn sí ṣọ́ọ̀bù ìyàwó òun.
Ó ní nígbà tí òun ma fi dé ibẹ̀ láti lọ wo òun to n ṣẹlẹ̀, ní òun ri wí pé ìbọn ti bá Firdaos náà, níbi tó ti ń ran ìyá rẹ̀ lọ́wọ́.
Ó fi kun pé kìí òun gan ni òun da ẹ̀jẹ̀ sí Firdaos lórí nítorí bàbá rẹ̀ ti kú láti nǹkan bíi ọdún márùn-ún sẹ́yìn, kí òun tó fẹ́ ìyá ọmọ náà.
Amọ o ni àwọn ènìyàn kò le mọ̀ wí pé òun kọ́ ni òun bi ọmọdebinrin naa.
‘Ọmọ tó já fáfá ni Firdaos, a mọ ikú rẹ̀ lára gidi’
Elesin ṣàlàyé pé Firdaos jẹ́ ọmọ tó já fáfá lẹ́nu ẹ̀kọ́ rẹ̀, tí kìí si ṣe ìmẹ́lẹ́ àti wí pé ìdí nìyí tó fi máa ń tẹ̀lé ìyá rẹ̀ lọ sí ṣọ́ọ̀bù, pàápàá lásìkò isinmi báyìí.
Ó ní ó ṣe ni láàánú wí pé ìbọn àwọn ọmọ ẹlẹ́gbẹ́ òkùnkùn náà bà á, níbi tó ti ń ran ìyá rẹ̀ lọ́wọ́.
Ó tẹ̀síwájú pé ní kété tí ìbọn ti ba ọmọ náà ní nǹkan bí ago márùn-ún àbọ̀ ìrọ̀lẹ́. ni àwọn ti gbe lọ sí ilé ìwòsàn nibi tó padà dákẹ́ sí lọ́jọ́ Ìṣẹ́gun.
Ó ní gbogbo ìgbìyànjú àwọn láti jẹ́ kí ọmọ náà yè ló já sí pàbó.
Ìjọba nílò láti máa fi ìyà jẹ́ àwọn ọmọ ẹlẹ́gbẹ́ òkùnkùn tí ọwọ́ bá ti tẹ̀
Ismail Elesin ní ó yẹ kí ìjọba gbé ìgbésẹ̀ akin lórí àwọn ọmọ ẹlẹ́gbẹ́ òkùnkùn tó ń fi ojoojúmọ́ ṣọṣẹ́ káàkiri orílẹ̀ èdè yìí, pàápàá ìpínlẹ̀ Kwara.
Ó ní tó bá jẹ́ wí pé ìjọba máa ń fi ìyà tó tọ́ jẹ́ àwọn tí ọwọ́ bá tẹ̀ nínú wọn, wọn kò ní máa fi ojoojúmọ́ pọ̀ si débi tí wọ́n yoo ma fi gbogbo ìgbà pa ara wọn káàkiri ìlú.
Awọn ẹlẹgbẹ okunkun pa ọmọ iya alagbo, ọkunrun kan to n lọ ati Abbey gan, ti wọn wa wa - óṣojúmikòró
Bakan naa, ọkùnrin kan tí kò fẹ́ kí a dá orúkọ rẹ̀ ṣàlàyé bí àwọn ọmọ ẹlẹ́gbẹ́ òkùnkùn náà ṣe dá rúgúdù sílẹ̀.
Ọkùnrin náà tí ó ń ta ọjà lagbègbè náà ní àwọn ń bá káràkátà àwọn lọ gẹ́gẹ́ bí ìṣe àwọn ní ìrọ̀lẹ́ ọjọ́ Ajé tí ìṣẹ̀lẹ̀ náà wáyé, kí àwọn tó máa gbọ́ ìró ìbọn.
Ó ṣàlàyé pé ní ṣọ́ọ̀bù obìnrin kan tó ń ta agbo, tí ọ̀pọ̀lọpọ̀ máa ń pè ní Toke Alágbo, ni àwọn ẹlẹ́gbẹ́ òkùnkùn ọ̀hún tọpa ẹni tí wọ́n fẹ́ pa, wá.
"Bí wọ́n ṣe dé, ṣọ́ọ̀bù Toke Alágbo ni wọ́n lọ tààràtà, tí wọ́n sì da ìbọn bolẹ̀."
"A gbọ́ pé ọmọkùnrin kan tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Abbey ni wọ́n wá, bí òun náà ṣe rí wọn ló sá láti sá àsálà fún ẹ̀mí ara rẹ̀."
"Níbi tó ti ń sá lọ ní àwọn ọmọ ẹgbẹ́ òkùnkùn tó wa wá ti bẹ̀rẹ̀ sí ní yin ìbọn."
Ó ní yàtọ̀ sí Abbey tí ìbọn àwọn ọmọ ẹlẹ́gbẹ́ òkùnkùn náà pa, ìbọn naa tun ṣèèṣì ba ọkùnrin kan tó n lọ jẹ́jẹ́ tirẹ̀ àti ọmọ ìyá alágbo tó jẹ́ ọmọ kékeré.
"Ní òwúrọ̀ yìí la gbọ́ pé ọmọ ìyá Alágbo náà ti kú nítorí kò kú ní ẹsẹ̀kẹsẹ̀ tí ìbọn bà á."

Oríṣun àwòrán, SCREENSHOT
A ti ń ṣe iṣẹ́ láti nawọ́ gán àwọn tó bá lọ́wọ́ nínú ìkọlù àwọn ọmọ ẹgbẹ́ òkùnkùn - Ọlọpaa
Agbẹnusọ ọlọ́pàá ìpínlẹ̀ Kwara, Ajayi Okasanmi ní lóòótọ́ ni àwọn ti gbọ́ fìnfìn pé àwọn ọmọ ẹgbẹ́ òkùnkùn fẹ́ ṣọṣẹ́ nítorí àyájọ́ tí wọ́n máa fi ń hu ìwà láabi ni ọjọ́ Kẹjọ, oṣù Kẹjọ jẹ́.
Okasanmi ní gbogbo ibi tí àwọn lérò pé àwọn ọmọ gànfé náà ti lè hu ìwà yìí, ni àwọn da ọlọ́pàá sí nítorí à ti dènà ìṣẹ̀lẹ̀ bẹ́ẹ̀.
Ó ní ó ṣeni láàánú pé pẹ̀lú gbogbo ìgbìyànjú àwọn, àwọn ọmọ náà tún rí ààyè ṣe iṣẹ́ ibi wọn ní ìrọ̀lẹ́ ọjọ́ náà.
Ó ṣàlàyé pé ní nǹkan bí ago méje ọjọ́ Ajé ni àwọn gba ìpè wí pé àwọn ọmọ ẹgbẹ́ òkùnkùn pa ènìyàn kan sí agbègbè Olunlade, tí àwọn sì ti lọ gbé òkú náà sí mọ́ṣúárì.
Okasanmi ní ìwádìí ti ń lọ lọ́wọ́ láti ṣàwárí àwọn tó lọ́wọ́ nínú ìkọlù náà láti fi ojú wọn winá òfin.
Bákan náà ló gba òbí àti àwọn alágbàtọ́ ní ìmọ̀ràn láti mójútó àwọn ọmọ wọn pàápàá lórí àwọn ènìyàn tàbí ọ̀rẹ́ tí wọ́n bá ń bá rìn.












