“Gbogbo àwọn tó bá kọ ‘proposal’ olólùfẹ̀ wọn yóò bẹ̀rẹ̀ sí ń san owó ìtanràn”

fines for those who reject marriage proposals

Oríṣun àwòrán, Ozone Jeydin

Obinrin tabi ọkunrin to ba kọ lati ṣe igbeyawo pẹlu ẹni to ba kọ ẹnu ifẹ sii yoo bẹrẹ si n san owo itanran bayii lorilẹ-ede Chad.

Orukọ ti wọn n pe owo itanran yii ni ni “amchilini.”

Igbimọ awọn Musulumi to ga julọ nilẹ naa le kede ofin tuntu yii,.

 Igbimọ naa sọ pe obinrin ti aje ọrọ ọhun ba ṣi mọ lori yoo san $39 owo itanran, nigba ti ọkunrin yoo san $15.

Ẹgbẹ kan to n ja fun ẹto awọn obinrin nilẹ naa, Chadian Women's Rights League, ti tako ofin tuntun yii pẹlu ami #StopAmchilini.

Ẹgbẹ ọhun sọ pe ofin naa ko ba ofin mu, ati pe o tapa si ofin orilẹ-ede naa, eyii to fun eeyan lanfani lati gba tabi kọ igbeyawo pẹlu ẹnikẹni.

Amọ igbimọ awọn Musulumi to gbe òfin náà kalẹ ni igbesẹ awọn ko ṣẹyin nnkan to wa ninu mimọ Quran.

 Ẹwẹ, ọpọ igba ni wọn maa n fi ipa mu eeyan ṣe igbeyawo ti ọkan rẹ ko nifẹ si ni Chad, awọn ọmọde si ni wọn maa n fi ipa fun ni ọkọ.

Bo tilẹ jẹ pe wọn ti ṣe ofin kan lọdun 2015, eyii to fajuro si irufẹ iwa bẹẹ, ida ọgọta awọn obinrin lati ẹni ogun ọdun si ọdun mẹrinlelogun ni wọn ti fi ipa mu lọ sile ọkọ ni Chad.