Pásítọ̀ àti èkejì rẹ̀ tó bẹ́ orí ọmọdé ṣètùtù sí ṣọ́ọ́ṣì gba ìdájọ́ ikú

aworan awọn apaniyan

Oríṣun àwòrán, Screenshot

Adajọ Oluwatoyin Taiwo, ti ile ẹjọ giga ipinlẹ Eko, lọjọ isẹgun, da ẹjọ iku fun pasitọ kan ati amugbalẹgbẹ rẹ.

Orukọ awọn ọdaran mejeeji ni pasitọ Erinmole Adetokunbo ati Adedoyin Oyekanmi.

Adajọ ni wọn jẹbi fun bi wọn ṣe pa ọmọde kan, Kazeem Rafiu, ẹni ọdun meje ni agbegbe Ikorodu ni ipinlẹ Eko.

Adajọ Taiwo lo gbe idajọ naa kalẹ, lẹyin ti awọn olujẹjo ni awọn jẹbi ẹsun naa.

Oyekanmi ati Adetokunbo ni iwadi awọn ọlọpaa safihan pe, wọn lẹdi apo pọ lọjọ keje oṣu kẹfa lọdun 2017, ni agbegebe Odekekere, lati gba ẹmi ọmọdekunrin naa.

Iwadi fi han awọn mejeeji bẹ ori ọmọdekunrin naa, ti wọn si sin ori naa si abẹ ile ijọsin pasitọ naa fun etutu.

Awọn eeyan adugbo naa lo kẹfin wọn , ti wọn si ransẹ si ọlọpaa lati wa mu pasitọ ati amugbalẹgbẹ rẹ.

Lẹyin ọdun mẹrin ni ahamọ, wọn bẹrẹ igbẹjọ lori wọn lọdun 2021.

Ninu idajọ rẹ, Adajọ Taiwo ni iṣẹlẹ naa lo bani ninujẹ bi awọn olujẹjọ ṣe pa ọmọ kereke lati fi ṣe etutu.

“Ẹsẹ ti awọn olujẹjọ da lo jẹ ẹsẹ nla pẹlu iwa ọdaju, ti wọn fi mọọmọ pa ọmọdekunrin naa lai wo ti awọn obi ọmọ naa, ti o le wulo fun wọn ni ọjọ waju.”

“Idajọ mi ree, mo pasẹ ki wọn yẹ igi fun iwọ Adedoyin Oyekanmi ati iwọ Erinwole Adetokunbo fun bi ẹ dijọ ṣeku pa Kazeem Rafiu, ki Ọlọrun wa pẹlu yin.”

NDLEA mú afurasí pásìtọ̀ pẹ̀lú egbòogi olóró àti bàbá ẹni ọdún 90 tó ń ta egbòogi fún àwọn jàndùkú

NDLEA

Oríṣun àwòrán, Femi Babafemi

Ajọ to n gbogun ti egboogi oloro ni Najijiria, NDLEA, ti fi ṣikun ofin mu pasitọ kan, Okon Effiong, ti wọn ka agba mẹta egboogi crystal methamphetamine mọ lọwọ.

Egboogi oloro yii naa tun ni wọn tun n pe ni ti ọpọ mọ si “Mkpuru Mmiri” mọ lọwọ.”

Ajọ naa ni awọn gbabọ pe orilẹ-ede India ni wọn ti gbe egboogi naa wọle.

Ninu atẹjade kan ti agbẹnusọ ileeṣẹ naa, Femi Babafemi fi lede lo ti ṣi aṣọ loju ọrọ naa.

O ni “Inu ẹru kan ti iwọn rẹ to aadọrun kilo ni wọn gbe egbogi oloro naa si lagbegbe Ojuelegba, niluu Eko.

Amọ akara wọn to tu sepo loju ọna marosẹ Umuahia si Ikot Ekpene nipinlẹ Akwa Ibom.

“Egboogi naa, ti wọn di ni iwọn ọgbọn sinu agba kọọkan ni wọn n gbe lọ fun ọkunrin kan to jẹ pasitọ, iyẹn Anietie Okon Effiong.”

Gẹgẹ bii ohun ti Babafemi sọ, orilẹ-ede Cameroon ni wọn n gbe egboogi naa lọ.

Eyi lo n waye lẹyin ti ajọ yii kan naa ti kọkọ gbẹsẹle egboogi oloro ‘crystal meth’ yii kan naa, ti awọn kan n gbe lọ si orilẹ-ede Australia, Indonesia ati Philipines.

NDLEA tun gbẹsẹle egboogi igbo, ti ileeṣẹ kan to maa n fi ẹru ranṣẹ n gbe lọ si Dubai, ni United Arabs Emirates.

Yatọ si awọn egboogi ti NDLEA gbẹsẹle niluu Eko yii, wọn tun fi ṣikun ofin mu awọn eeyan mii to n pin egboogi oloro kaakiri Naijiria.

Lara wọn ni baba agba kan, to jẹ ajagunfẹyinti, Usman Adamu ti wọn mu ni Sokoto lori ẹsun pe o n ta agboogi oloro fun awọn janduku.

NDLEA ni ẹni aadọrun ọdun ni baba agba naa.