Ṣé lóòtọ́ ni pé Ooni Adeyeye Ogunwusi ń gbaradì fún ìgbéyàwó míràn?

Ooni ile ife ati Mariam Anako

Oríṣun àwòrán, ile oodua/ other

Ṣe lootọ ni Kabiyesi Ọọni ile Ifẹ, Ọba Adeyẹye Ẹnitan Ogunwusi n gbaradi lati gbe olori tuntun si aafin ni ile Oodua nile Ifẹ?

Ibeere yii lo gba ori ayelujara kan bayii lẹyin ti iroyin gbode pe Ooni ile Ifẹ ti gbọn ara nu kuro ninu ijakulẹ igbeyawo rẹ pẹlu Olori Naomi Silẹkunọla.

Gẹgẹ bi awọn iroyin ori ayelujara kan ṣe n sọ, eto gbogbo ti n to laafin bayii lati gba alejo tuntun yii. 

Awọn lamẹtọ kan laafin Oodua tilẹ sọ pe eto mọmi n mọ ọ ti waye nile mọlẹbi olori tuntun naa.

Ireti si wa pe olori tuntun naa, ti wọn pe orukọ rẹ ni Mariam Anako, yoo wọ aafin Ọọni laipẹ jọjọ.

Ki ni awọn to sun mọ aafin Oodua nile Ife n sọ nipa ọrọ naa?

Ooni ile ife

Oríṣun àwòrán, ile oodua

Lootọ iroyin yii ti n kaakiri ṣugbọn BBC Yoruba gbiyanju lati fi idi rẹ mulẹ boya ootọ ni tabi irọ.

Ọkan lara awọn eekan ọmọ bibi ilu Ile Ifẹ kan, to tun jẹ oloye pataki nilu Ile Ifẹ amọ ti a ko fẹ darukọ rẹ, ṣalaye fun BBC News Yoruba pe lootọ ni ọrọ fifẹ olori tuntun n lọ lọwọ.

Oloye naa ni pọpọṣinṣin ọdun ijẹṣu to waye ni ọsẹ akọkọ ninu oṣu kẹjọ yii si lo mu ki wọn dawọ rẹ duro naa.

Oloye ilu Ile Ifẹ naa tun ṣalaye pe o ṣeeṣe ki igbeyawo naa waye ki wọn to ṣe ọdun ọlọjọ ni oṣu kẹsan an ọdun yii."

Ooni Ogunwusi ti ile ife nibi ayeye odun ijesu tuntun

Oríṣun àwòrán, ile oodua

Amọṣa, eekan ilu Ile Ifẹ naa ṣalaye pe lootọ ni Mariam Anako wa loju irinajo ifẹ pẹlu Kabiyesi Ọọniriṣa olori ade gbogbo.

Sugbọn gẹgẹ bi o ṣe sọ, “ko tii si ẹni lee sọ boya oun ni tabi obinrin miran ni baba n gbe bọ wa si aafin.”

Ọkan lara awọn akọroyin to sun mọ aafin Ọọni Ifẹ pẹkipẹki ṣalaye fun wa pe aafin ko tii sẹ iroyin naa pe irọ ni, tabi gba a wọle gẹgẹ bi ootọ.

O ni “eyi n fihan pe o ṣeeṣe ko jẹ otitọ lọrọ naa. Ṣugbọn gbogbo wa ṣi n reti ibi ti yara ọrọ naa yoo ja si.

Ki ni Aafin oodua sọ nipa iroyin igbeyawo yii?

Ohun ti a gbọ lati aafin Oodua ni pe ko Kabiyesi ati ile Oodua ko fẹ ki ariwo pupọ waye pẹlu igbeyawo naa.

Eyi si lo faa ti wọn fi n gbe awọn igbaradi ati eto gbogbo gbẹyin awọn akọroyin.

Nigba ti a kan si agbẹnusọ fun Ọọni Adeyẹye Ẹnitan Ogunwusi, Ọjaja keji, Ọtunba Ọlafare ṣalaye fun BBC Yoruba pe oun ko lee sọ ni pato boya ootọ ni tabi ahesọ ọrọ lasan ni.

O ni lootọ ori ayelujara loun pẹlu ti gbọ iroyin naa ṣugbọn ko tii si iroyin pato lati ọdọ kabiyesi funra ara rẹ pe oun fẹ ṣe iyawo laipẹ.

O fikun pe bẹẹ naa ni ko si awọn oloye laafin to tii fi iroyin nipa igbeyawo naa to oun leti pẹlu.

Ooni ile ife

Oríṣun àwòrán, ile oodua

“Idi ti mo fi ni mi o le sọ pe otitọ ni iroyin naa tabi kii ṣe otitọ ni pe, ọrọ igbeyawo jẹ ọrọ mọ sinu, mọ sikun fun ẹni tọrọ kan.

O si di igba ti ẹni ti ọrọ kan ba sọ ọrọ naa sita ki araye to mọ bo ṣe nlọ, ṣugbọn nibi ti ọrọ de duro bayii, Kabiyesi ko tii fi to mi leti pe oun n gbe iyawo bọ laafin"

Nigba ti a tun bii lere boya arabinrin Mariam Anako, ti aye n pariwo ni ẹni naa, Ọtunba Ọlafare ko sọ boya oun ni tabi oun kọ.

Ohun to sọ ni pe Kabiyesi Ọọni Ile Ifẹ nikan lo le sọ nitori pe t’ẹni n t’ẹni lọrọ igbeyawo jẹ.

Ta ni ẹni ti awọn eeyan n tọka si gẹgẹ bi olori tuntun?

Mariam Anako ni obinrin tuntun ti awọn eeyan n fi oju si lara bayii gẹgẹ bii olori tuntun ti yoo gba ipo Silẹkunọla Naomi to fi aafin silẹ loṣu kejila ọdun 2021.

Olori Silekunola lo si fi iroyin ikọsilẹ naa to araye leti nigba to kọwe si oju opo Instagram rẹ pe oun ti jẹ ẹ to nile Oodua.

O ni aala ti gba aarin oun ati Ọọni Ogunwusi kọja.

Aworan arabinrin Mariam Anako

Oríṣun àwòrán, other

Ta ni Mariam Anako, ti ẹnu n kun pe o le di Olori ni aafin Ife?

Gbajumọ oniṣowo epo ni arabinrin Mariam Anako, ọmọ ẹya Ebira ni ipinlẹ Kogi si ni. 

Ilu Ilorin ni a gbọ pe awọn obi rẹ wa.

Bakan naa la gbọ pe Mariam padanu baba rẹ lati igba ewe rẹ, ile ọga ọlọpaa patapata ri lorilẹede Naijiria, Mohammed Dikko Abubakar ni wọn si ti tọọ dagba.

Iya rẹ pẹlu jẹ ọlọpaa to ti fẹyinti.

Awọn Igbeyawo atẹyinwa ti Ọọni tise sẹyin:

Ooni ile ife ati omo re obinrin pelu olori ana, Naomi Silekunola

Oríṣun àwòrán, ile oodua

Eyi ni yoo jẹ igba kẹrin ti Ọọni Ile Ifẹ yoo maa ṣe igbeyawo arede. 

Ko si ọrọ anjayopa nibẹ bi eeyan ba sọ pe apọn ni Ọoniriṣa pada si lẹyin ti Olori tẹlẹ, Ṣilẹkunnọla Naomi fi silẹ ni oṣu kejila ọdun 2021.

Igbeyawo wọn so eso kan ṣoṣo, ọmọ okunrin ti wọn pe orukọ rẹ ni Tadenikawo; yoo pe ọdun meji ni oṣu kọkanla ọdun yii.

Ooni ile ife ati Olori tele, Wuraola

Oríṣun àwòrán, ile oodua

Ṣaaju Naomi, Kabiyesi Ọọni Ogunwusi ti kọkọ fẹ Adebukola Bombata ki o to de ori oye ṣugbọn ituka waye lẹyin iwuye rẹ. 

Lẹyin rẹ, o fẹ Olori Wuraọla ki igbeyawo naa to foriṣanpọn loṣu keje ọdun 2017.

Lẹyin rẹ lo fẹ Olori Naomi lọdun 2018 ki onitọun pẹlu to gba ori ayelujara Instagram lọ lati kede ituka igbeyawo oun ati ọbalaye naa