Ọwọ́ Amotekun Ondo tẹ arìnrìnàjò 151 láti Katsina, Kano, Jigawa pẹ̀lú ọ̀pọ̀ oògùn abẹnugọ̀ǹgọ̀

Aworan awọn afurasi naa

Oríṣun àwòrán, amotekun ondo

Ọwọ awọn oṣiṣẹ ajọ alabo ipinlẹ, Amọtẹkun nipinlẹ Ondo ti tẹ awọn arinrinajo bii mọkanlelaadọjọ ti wọn fẹ wọ ipinlẹ naa lọjọbọ.

Ninu atẹjade kan ti ajọ Amọtẹkun nipinlẹ Ondo fi sita, ọwọ tẹ awọn eeyan naa lagbegbe Sango, lopopona Iju ni agbegbe ijọba ibilẹ Ariwa Akurẹ.

Adari ajọ Amọtẹkun ni ipinlẹ Ondo, Akọgun Adelẹyẹ ṣalaye pe lasiko ti wọn fi n tu ẹru awọn eeyan naa ni wọn ba awọn oogun abẹnugọngọ.

Ati alupupu ọkada mẹwaa ti ko ni idanimọ to ba ofin mu ninu ẹru wọn.

O fii kun un pe “awọn kan lara awọn eeyan yii sọ pe ipinlẹ katsina, Kano ati Jigawa lawọn ti n bọ,

Sugbọn nigba ti a bi wọn leere bi irin wọn ṣe wa papọ, wọn ko lee ṣe alaye to kuna.

Wọn ni ọkọ naa kan wa gbe awọn ni, o si n gbe awọn bọ ni ilu Akurẹ nipinlẹ Ondo”

Aworan oogun to wa lọwọ wọn

Oríṣun àwòrán, amọtẹkun Ondo

Amọtẹkun ni ipinlẹ Ondo wa ṣalaye siwaju sii pe bi awọn eeyan naa ko ba ti lẹbọ lẹru, ti wọn ko si ni ẹnikẹni nipinlẹ Ondo to ranṣẹ pe wọn, taarata ni wọn yoo da wọn pada si ibikibi ti wọn ba ti n bọ.