Gbọ́ ohun tí Ààrẹ Buhari, Gómìnà Oyetola sọ nípa olóògbé Tafa Balogun, IGP tẹ́lẹ̀ rí

Aarẹ Muhammadu Buhari ti mọ riri iṣẹ takuntakun ti Ọga agba Ọlọpaa Tafa Balogun to di oloogbe to jade laye ṣe nigba to wa lẹnu iṣẹ.
Aarẹ ninu atẹjade ti agbẹnusọ rẹ, Femi Adesina fi sita kẹdun pẹlu ileeṣẹ Ọlọpaa nibi to ni Balogun ti lo aye to daa lara igbe aye rẹ.
Bakan naa, Gómìnà ipinlẹ Osun, Gboyega Oyetola kẹdun iku Ọga agba Ọlọpaa tẹlẹ ri naa, Tafa Balogun to jade laye l’Ọjọbọ ọsẹ ni to ku ọjọ di ko pe ẹni ọdun marundinlọgọrin loke eepẹ.
Oyetola sọ ninu ọrọ to fi sita lọjọ Ẹti to si n ki Ọba ilu oloogbe Tafa, Ọrangun ti ilu Ila, Ọba Wahab Oyedotun, gomina tẹlẹ ri ni ipinlẹ Osun Oloye Adebisi akande to fi mọ ẹbi ati ọrẹ Ọgbẹni Balogun. Bakan naa lo ki awọn oṣiṣẹ Ọlọpaa Naijiria ati awọn araalu Ila-Ọrangun ku ikẹdun.
Ninu atẹjade ti agbẹnusọ rẹ Ismail Omipidan fọwọ si, Gomina Oyetola tun sọ nipa ipa ribiribi ti oloogbe to jẹ Ọga agba Ọlọpaa tẹlẹ naa ko nipa eto abo orilẹede yii lasiko to wa ni ipo naa.
Nǹkan méje tí ọ̀pọ̀ kò mò nípa Ọ̀gá Ọlọ́pàá Nàìjíríà tó jáde láyé

Oríṣun àwòrán, Facebook/Adélówòtán Tolúwanimí Adékóláwolé
Ọga agba ọlọpaa lorileede Naijiria nigba kan ri, Mustapha Balogun ti jade laye.
Ẹni ọdun mẹrinlelaadọrin ni Tafa Balogun ṣe taa si gbọ pe o ki duniya pe o di gbere lẹyin aisan ranpẹ.
Ni Ọjọbọ nileeṣẹ iroyin Naijiria Punch jabọ pe o ku ni ile iwosan kan lagbegbe Lekki ni ilu Eko ni nkan bi ago mẹsan abọ alẹ.
Ọmọ bibi ilu Ila Oragun ni ipinlẹ Osun ni Mustapha Adebayo Balogun ti wọn si bi lọjọ Kẹjọ oṣu Kẹjọ ọdun 1947.
O n palẹmọ ọjọ ibi ọdun karunlelaadọrin rẹ ni ọlọjọ de.
Ọga ọlọpaa ikọkanlelogun ni Naijiria ni Tafa Balogun
Fasiti ilu Eko ni Tafa Balogun ti kẹkọ imọ nipa eto oṣelu.
Ọdun 1973 lo darapọ mọ iṣẹ ọlọpaa nibi to ti kawe gboye imọ ofin lati fasiti ilu Ibadan.
Lasiko to wa nidi iṣẹ ọlọpaa, a ri akọsilẹ pe o ṣiṣẹ laaye orisirisi to si jẹ pe oun ni Kọmisana ọlọpaa akọkọ ti wọn yan ni ipinlẹ Delta.
Bakan naa lo jẹ Komisana ọlọpaa ni Rivers ati Abia.
Ṣaaju igba naa wọn fi jẹ adele Kọmisana ni ipinlẹ Edo.
Lẹyin to ri agbega lẹnu isẹ si ipo igbakeji ọga agba ọlọpaa to n ṣe akoso Zone 1, niṣe ni Tafa Balogun di ilumọọka.
Ko pẹ si igba naa ni wọn fi jẹ ọga agba ọlọpaa lọjọ Kẹfa oṣu Kẹta ọdun 2002.
Ni ọjọ Kẹrin oṣu Kẹrin ọdun 2005, ajọ to n gbogun ti iwa jẹgudujẹra EFCC wọ Tafa Balogun lọsiwaju ile ẹjọ lori ẹsun pe o lu owo ọba to le ni ọgọrun miliọnu dọla ni ponpo laarin ọdun mẹta.
O ṣi wa lori ipo ọga ọlọpaa nigba ti wọn fẹsun yi kan an.
Ẹsun 70 ni EFCC fi kan Tafa Balogun

Oríṣun àwòrán, Adélówòtán Tolúwanimí Adékóláwolé
Nuhu Ribadu lo jẹ ọga agba EFCC nigba ti wọn fi ẹsun yi kan Tafa Balogun.
Nuhu Ribadu jẹ igbakeji Kọmiṣana ọlọpaa ki wọnto fi jẹ ọga ajọ EFCC.
Bi ọmọṣẹ lo jẹ si Tafa Balogun nigba taa n wi yi.
Nigba ti wọn yoo fi mu Balogun, o tọwọ bọ adehun pe oun yoo da pada ninu owo toun lu ni ponpo bi wọn ko ba jẹ koun ṣe ju ẹwọn oṣu mẹfa lọ.
Adajọ Binta Nyako to gbe idajọ kalẹ sọ pe nitori pe Tafa Balogun ti kabamọ ẹsẹ rẹ ati pe igba akọkọ rẹ ree ti wọn yoo mu, awọn yoo din ijiya rẹ ku.
Tori naa o ni ki Tafa Balogun san fun ikọọkan ẹsẹ mẹjọ to jẹwọ pe oun ṣẹ.
Lapapọ owo yi jẹ miliọnu mẹrin Naira.
Igbẹjọ Tafa Balogun nigba naa jẹ manigbagbe ninu itan orileede Naijiria nitori oun ni ọga ọlọpaa orileede.
O jẹ itọka gẹgẹ bi ijọba aarẹ Olusegun Obasanjo ṣe sọ pe awn ko ni faaye gba iwa ajẹbanu lorileede Naijiria.
Lati igba ti wọn ti yọ Balogun loye a ko fi taratara gburo rẹ mọ bi kii ṣe pe awọn eeyan tun gbọ nipa iku rẹ.́












