Ọba ìlú àtàwọn mẹ́ta kàgbákò ajínigbé, ìbọn ba awakọ̀ wọn l'Ondo

Inú fu àyà fu bí àwọn agbébọn ṣe ji ọba alayé kan gbé, yìbọn mọ́ awakọ̀ ní ìpínlẹ̀ Ondo.

Ní alẹ́ ọjọ́bọ̀, ọjọ́ Kẹrin, oṣù Kẹjọ ọdun 2022 ni àwọn agbébọn jí Onikun ti Ikun, ọba Mukaila Bello gbé ní òpópónà márosẹ̀ Owo sí Ikare.

Nígbà tí BBC News Yorùbá kàn sí agbẹnusọ iléeṣẹ́ ọlọ́pàá ìpínlẹ̀ Ondo, Funmilayo Odunlami ṣàlàyé pé nígbà tí Ọba náà àti àwọn ènìyàn rẹ̀ ń bọ̀ ni àwọn agbébọn bẹ̀rẹ̀ sí ní yìbọn lu ọkọ̀ wọn.

Àwòrán àwọn agbébọn

Oríṣun àwòrán, SCREENSHOT

Odunlami ní ìbọn náà ba awakọ̀ tó wa ọkọ̀ náà lórí àmọ́ àwọn ọlọ́pàá ti gbe lọ sí ilé ìwòsàn níbi tó ti ń gba ìtọ́jú lọ́wọ́.

Ó ní lẹ́yìn tí àwọn agbébọn yìbọn mọ́ ọkọ̀ ni wọ́n kó Ọba náà àti àwọn ènìyàn tó kù wọ inú igbó lọ.

Ọba Onikun àti àwọn mẹ́ta mìíràn ni àwọn afurasí ajínigbé náà jí gbé lọ.

Àwọn mẹ́ta mìíràn tí wọ́n jí gbé náà ló jẹ́ olóyè ní ìlú ọ̀hún.

Lára àwọn tí wọ́n jí gbé ni Yeye Gbafinro, olùdíje sípò aṣòfin ìpínlẹ̀ Ondo láti ṣojú ẹkùn ìlà oòrùn Akoko tẹ́lẹ̀ rí lábẹ́ ẹgbẹ́ òṣèlú All Progressives, APC, Adeniran Adeyemo àti olóyè ìlú mìíràn Bashiru Adekile.

Ìjínigbé yìí ló ti ń dá ìbẹ̀rù-bojo sọ́kàn àwọn ará ìlú náà báyìí.

Ọba náà àti àwọn yòókù tí wọ́n jí gbé ló ń bọ̀ gẹ́gẹ́ bí ìròyìn ṣe sọ láti Akure, olú ìlú ìpínlẹ̀ Ondo kí àwọn ajínigbé náà tó dá wọn lọ́nà.

Odunlami wá fìdí rẹ̀ múlẹ̀ pé ìwádìí ti ń lọ lọ́wọ́ láti ṣe àwárí àwọn ajínigbé náà báyìí kí wọ́n sì tún le gba Ọba àti àwọn yòókù kalẹ̀ lọ́wọ́ àwọn ajínigbé ọ̀hún.

Ó fi kun pé àwọn ọdẹ, fijilanté àti ọlọ́pàá ti kán lu ìgbẹ́ báyìí láti wá wọn rí.