Àtúntò ni Nàìjíríà nílò jùlọ lásìkò yìí fún ìdàgbàsókè - Atiku

Atiku Abubakar

Oríṣun àwòrán, SCREENSHOT

Olùdíje sípò Ààrẹ lábẹ́ ẹgbẹ́ òṣèlú peoples Democratic Party, PDP, Atiku Abubakar ti ní kò ṣeéṣe fún orílẹ̀ èdè Nàìjíríà láti bọ́ nínú gbogbo àjàgà gbogbo ìpèníjà tó ń ba fínra àyàfi tí àtúntò bá wáyé.

Atiku ní ohun tó ṣe pàtàkì tí orílẹ̀ èdè Nàìjíríà nílò jùlọ lásìkò yìí ni olórí tó ní ìmọ̀, ọgbọ́n àti òye láti yọ àwọnọmọ orílẹ̀ èdè lọ́wọ́ àjàgà tí àwọn adarí tó ti kọjá kó orílẹ̀ èdè yìí sí.

Níbi ètò àpérò ọlọ́dọọdún àwọn ọ̀dọ́ ìjọ Anglican ilẹ̀ Nàìjíríà tó wáyé ní Iyin-Ekiti, ìpínlẹ̀ Ekiti ni Atiku ti sọ̀rọ̀ náà.

Ó ni àwọn ọmọ Nàìjíríà gbọ́dọ̀ bọ́ lọ́wọ́ ìpèníjà yíyan àwọn olórí tó ti ṣèjọba kọjá tí orílẹ̀ èdè Nàìjíríà bá fẹ́ ní ìgbéga àti ìlọsíwájú.

Atiku sọ síwájú pé ó pọn dandan pé kí agbára àti àwọn nǹkan àmúṣọrọ̀ Nàìjíríà kúrò lọ́wọ́ ìjọba àpapọ̀ nìkan tí ìdàgbàsókè tó fojúhàn bá máa wáyé ní o’rilẹ̀ èdè yìí.

Ó fi kun pé àyípadà gbọ́dọ̀ bá ìwé òfin Nàìjíríà kó le fi àyè gba dọ́gba-n-dọ́gba, ètò ìdájọ́ tó fẹsẹ̀ rínlẹ̀, kí tẹrútọmọ le jẹ mùkúndùn ìjọba àwaarawa.

Ó tẹ̀síwájú pé ohun tó dára ni kí Nàìjíríà wà ní ìṣọ̀kan títí ayérayé àmọ́ kí àyípadà ló lòòrìn bá ètò ìṣèjọba rẹ̀.

“Ohun tó fojú hàn gbangba ni pé Nàìjíríà ń kojú ìpèníjà gidi pàápàá lórí ìṣọ̀kan rẹ̀ báyìí èyí tó ń wáyé látara ìjà ẹlẹ́yàmẹ̀yà káàkiri gbogbo igun mẹ́rẹ̀ẹ̀rin Nàìjíríà.”

“A gbọ́dọ̀ tètè dìde sí ìjà ẹlẹ́yàmẹ̀yà, kí gbogbo wa gba àláfíà láàyè tí á bá fẹ́ rí orílẹ̀ èdè Nàìjíríà èyí tó wu gbogbo wa.”

Atiku ṣàlàyé pé ètò ìdìbò ọdún 2023 tó ń bọ̀ jẹ́ àsìkò mìíràn tí àwọn ènìyàn máa tún ní àǹfàní láti tẹ Nàìjíríà síwájú nípa yíyan olórí tó ni àfojúsùn àti ohun àmúyẹ láti gbé Nàìjíríà dé èbútè ògo.

Bákan náà ló ní ètò ẹ̀kọ́ ṣe kókó, tó sì ṣe pàtàkì sí ìdàgbàsókè àwùjọ nítorí láìsí ètò ẹ̀kọ́ tó dúró ire, òkùnkùn ni gbogbo ayé máa wà.

Ó wá kóminú lórí bí àwọn akẹ́kọ̀ọ́ ṣe ti wà nílé fún ọ̀pọ̀lọpọ̀ oṣù nítorí ìyanṣẹ́lódì tó ń wáyé láàárín ASUU àti ìjọba àpapọ̀.

Ó ní yàtọ̀ sí wí pé ó ń ba sáà ètò ẹ̀kọ́ jẹ́, ọjọ́ ọ̀la àwọn akẹ́kọ̀ọ́ náà ni ìyanṣẹ́lódí ọ̀hún ń ṣe àkóbá fún.