Ọwọ Ọlọ́pàá tẹ Oníṣègùn tó fipá bá òníbárà rẹ́ sún

Aworan dokita kan

Oríṣun àwòrán, other

Ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Ogun tí fi ofin mu oníṣegun kan ti orukọ rẹ jẹ, Samson Ogundele, ẹni tí o gbe ni agbegbe referefu ni adugbo Oja Ọdan fun bi o ṣe fi tipatipa ba onibara rẹ, ọdomọbinrin kan sun.

Alukoro fun Ileeṣẹ ọlọpaa Abimbola Oyeyemi lo fidi iṣẹlẹ naa mule ninu atesita kan to fi sita niluu Abeokuta lọjọ aiku.

Oyeyemi ni ọwọ tẹ afurasi sì naa lọjọ kẹtadinlọgbọn oṣu keje.

"Ọwọ tẹ afurasi naa lẹyin arabinrin to sagbako naa gbe sì etí ọlọpaa Oja Odan pe, nibi ti oun ti kọ isẹ onidiri ni owo toto ẹgbẹrun kan tí sọnu tí awọn sì pinu pe awọn yoo lọ ọdọ babalawo lati mọ ẹni to mu owo naa lara awọn.

“O ni nigba ti a de si ọdọ babalawo, wọn pe wa wọ ninu yara lẹyin ti wọn ti gba ọgọrun un meje lọwọ wa.

“Arabinrin naa ni lẹyin ti ẹni akọkọ ati ẹni kejì wọlé, tí o si kan oun ni Babalawo fẹ fi tipatipa ba sun.

“Lẹyin ti ọmọbìnrin naa fi ọrọ yí to etí ileeṣẹ ọlọpaa leti, Ọga agba fun awọn ọlọpaa ni agbegbe Oja Odan, CPS Gabriel Ikechukwu, ni kí awọn ọlọpaa lọ mu babalawo naa.

aworan afurasi naa

Oríṣun àwòrán, ogun state police command

“Nigba ti a bẹrẹ iforowero ni ọkan lara awọn ọmọbìnrin to jẹ ọmọ ọdun mẹtadinlogun jẹwọ pe babalawo naa ti ba oun sun nigba ti awọn lọ ṣe iwadi lori ẹgbẹrun kan to sọnu.

“O ni Babalawo sọ fun oun pe tí oun ko gbọdọ sọ ọrọ naa fun ẹnikẹni ati pe ti oun ba sọ ọrọ naa, iku ni fun oun.

“Ní kia la gbe ọmọbìnrin naa lọ sí ile iwosan General Oja Odan níbi awọn dokita ti fi idi rẹ mulẹ pe otitọ ni pe babalawo fi tipatipa ba sun.

“Babalawo fun ara rẹ ti jẹwọ pe otitọ ni pe oun fi tipatipa ba awọn ọmọbìnrin naa sun.