Ìdí tí mo fi wá sí Tẹ́mpìlì Ifá, Osun Osogbo, Fásitì Ibadan láti NewYork – Òyìnbó tó ń kọ́ èdè Yorùbá

Àkọlé fídíò, Americans studying Yoruba: Ṣé ẹ ní Òyìnbó tó ń sọ Yorùbá lágbègbè yín?
Ìdí tí mo fi wá sí Tẹ́mpìlì Ifá, Osun Osogbo, Fásitì Ibadan láti NewYork – Òyìnbó tó ń kọ́ èdè Yorùbá

"Ẹ ma pe wa lalejo mọ, awa yin la nilu..."

Awọn ọmọ ilẹ Amẹrika kan to n kẹkọọ lọwọ ninu imọ ẹkọ ede Yoruba ati Aṣa ni Fasiti United States wa si Naijiria lati wa ṣe pasiparọ saa ẹkọ kan ni ẹka imọ ẹkọ ede Yoruba ti ile ẹkọ giga Fasiti Ibadan.

Awọn ọmọ Amẹrika to n kọ ede Yoruba

Fasiti Ibadan ni yoo jẹ Fasiti akọkọ ni gbogbo orilẹede Naijiria ti iru pasiparọ saa eto ẹkan kan yii ṣi oju awọn ara Amẹrika si iṣe aṣa ati ede awọn ẹya Yoruba.

BBC Yoruba ba lara awọn akẹkọọ naa sọrọ ti wọn si ṣafihan didantọ wọn ninu imọ ẹkọ ede Yoruba nipa kikọ oniruuru orin ati ọrọ nipa aṣa ilẹ Yoruba.

Ọmọ Amẹrika to n kọ ede Yoruba

Wọn tun mẹnu ba ipa ti wọn fi ẹkọ ede Yoruba ko ninu idagbasoke orilẹede Naijiria ati agbaye.