'Láti ojú orun, ohùn kan máa ń tọ́ka ewé àti ègbòogi sí mi, báyìí la ṣe ń ṣe agbo fún ǹkan ọmọ ọkùnrin'
Sisi Alagbo Abuja tẹẹ n ri yii, gbajumọ ni, akọṣẹmọṣẹ si ni ninu iṣẹ ti o yan laayo. Ọmọ bibi ipinlẹ Oyo ni Eniola Fagbemi to sọ fun BBC pe oun ba iṣẹ agbo yii laye ni tori wọn bi oun sinu rẹ ni.
"Lati kekere, mo jẹ ẹni to fẹran ewe ati egbo ati iṣẹṣe, wọn sọ fun mi pe nigba ti mo maa fi gbọnju mọọ, iya baba mi to n ṣee ti jade laye".
Olu ilu orilẹede yii, Abuja lo fi ṣe ibugbe.


"Ọdun meji ni mei kọ iṣ agbo, iya to kọ mi si kọ mi ni gbogbo tinu tode iṣẹ agbo kiki".
Eniola Alagbo tun mẹnu ba bi o ṣe dagba, awọn ipenija to doju kọ ati bo ṣe bori rẹ to jajabọ lọwọ iporuru ọkan to n baa finra nigba naa lẹyin igba to padanu ẹbi rẹ.
Bakan naa lo ṣalaye bi wọn ṣe maa n gbe awọn agbo to ba fẹ fi ranṣẹ si oke okun lọ si laabu ayẹwo ki wọn to lee fi ran awọn ọlọkọ ofurufu.
"A maa n ki agbo ti a maa pakeeji rẹ ranṣẹ lọ si Australia, Amẹrika ati kaakiri orilẹede agbaye bo til jẹ pe mi o tii ni ṣọọbu, ile mi ni mo ṣi n lo".

Asiko yii lo yan iṣẹ agbo laayo to si n ṣe aṣeyọri ninu rẹ titi to fi di gbajumọ de oke okun ninu iṣẹ agbo kiki.





